FIBAN LAGOS

FIBAN LAGOS FREELANCE AND INDEPENDENT BROADCASTERS' ASSOCIATION OF NIGERIA
(4)

Ọ̀RỌ̀ LẸYẸ Ń GBỌ́...
18/12/2021

Ọ̀RỌ̀ LẸYẸ Ń GBỌ́...

18/12/2021

Ìròyìn Àwòko
Ọjọ́ Àbámẹ́ta,ọjọ́ kejìdínlógún,Oṣù Kejìlá ọdún 2021.

Buhari: "Bí mo bá kúrò ní ipò Ààrẹ, ibi ìṣẹ́ ọ̀gbìn mi ni máa padà sí."

Ààrẹ Buhari ṣe ayẹyẹ ọdún ìbí rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Turkey.

Tinubu bá Ààrẹ Buhari yọ lọ́jọ́ ìbí rẹ̀.

Lawan, Gbàjàbíàmílà àti àwọn Gómìnà ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà bá Ààrẹ Buhari yọ lọ́jọ́ àyájọ́ ìkádún rẹ̀.

Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Ọ̀yọ́ dunú bí Gómìnà Mákindé ṣe tètè san owó oṣù ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Kejìlá.

Olú ìlú Warri rọ àwọn olórí ìpínlẹ̀ Delta kí wọ́n fọwọ́sowópọ̀ nítorí ìdàgbàsókè Delta.

Igbákejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó rọ àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ kí wọ́n tẹnpẹlẹ mọ́ ètò ìdàgbàsókè ìṣègùn ìbílẹ̀.

Ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin rọ ìjọba àpapọ̀ kí wọ́n wá ojútùú sí ètò ààbò kí ó lè dẹkùn ìyàn nílùú.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Sokoto Tambuwal pàṣẹ kí wọ́n mú olórin tí ó ń ki ọ̀gá àwọn apanilẹ́kún-jayé.

Orji Kalu kọ lẹ́tà sí Ààrẹ Buhari pé ẹgbẹ́ APC lè dàrú kí ọdún 2023 tó dé.

Ẹgbẹ́ Arẹwa sọ pé Ètò ìdìbò abẹ́lé gbangba-làṣá-ń-ta yóò fá rògbòdìyàn.

Ilé iṣẹ́ Radio Lagos na ọwọ́ ìfẹ́ sí orílẹ̀ èdè Netherlands láti ṣètò ìdàgbàsókè àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀.

Obìnrin tí ọkọ rẹ kó sínú omi ṣe àlàyé wàhálà tí ọkọ rẹ kojú kí ó tó kó sínú omi.

Obìnrin kan gbá ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ létí nítorí kò fẹ́ gbé e ní ìyàwó lẹ́hìn ọdún mẹ́fà tí wọn tí ń ṣe wọléwọ̀de.

Àjọ ìgbòkègbodò ọkọ̀ ojú omi ní Ìpínlẹ̀ Èkó pín èwù adóòlà-ẹ̀mí ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ní ẹkùn èbútékọ̀ márùn-ún ní Ìpínlẹ̀ Èkó.

Àjọ Àmọ̀tẹ́kùn mú ọkùnrin tí ó ń díbọ́n bí obìnrin fi jí ènìyàn gbé.

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá mú ọmọ ilé ìwé tí ó fi májèlé sí inú oúnjẹ ìyá-ìyá rẹ̀.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbé ètò tí yóò ṣe ìgbélárugẹ aṣọ òfì jáde ní agbègbè Ìsẹ́hìn.

Orílẹ̀ èdè Canada yànda orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nínú àwọn tí wọ́n fi òfin dè.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn di olóògbé níbi ìjàmbá iná ni orílẹ̀ èdè Japan.

Ọdẹ́gbàmí sọ pé Eguavoen kii ṣe ẹni tí yóò gbé ikọ̀ Super Eagles dé ilẹ̀ ìlérí.

Ayé wa kò ní ta Àmín.

Àyìnlá Omi.

17/12/2021

Ìròyìn Àwòko
Ọjọ́ Ẹtì,ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Ọpẹ́,ọdún 2021.

Ètò ààbò tí ó mẹ́hẹ ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lè gbégidínà ètò ìbò ní ọdún 2023-jega.

Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yóò gba owó ìrìn-àjò ni ojúnà Èkó sí Ìbàdàn, Afárá Niger kejì àti àwọn ojúnà ìmíràn.

Gómìnà Sanwóolú kí Ààrẹ Buhari kú oríire àyájọ́ ọjọ́ ìbí ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin rẹ̀.

Ìpànìyàn ní Kaduna/Katsina: Àwọn àjọ sọ fún ìjọba àpapọ̀ kí ó kéde ǹkan kò fararọ lẹ́nu ètò ààbò.

Masari rọ àwọn ènìyàn kì wọn dẹ́kun àríyànjiyàn ṣùgbọ́n kí wọ́n gbógun ti ètò ààbò tí ó mẹ́hẹ.

Àjọ adájọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbégidínà ìgbéga àwọn adájọ́ àgbà márùn-ún nítorí ẹjọ́ èké.

Àwọn orílẹ̀ èdè àti àjọ ilẹ̀ òkèèrè rọ Buhari kí ó máa dójúti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà

Ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin fajúro sí bí àwọn ènìyàn ṣe ń ta afẹ́fẹ́ ìdáná lọ́nà tí kò bá òfin mu.

Oyinlọlá sọ pé ìyàlẹ́nu ni bí Àkàndé ṣe ń bẹnu àtẹ́ sí Ọbásanjọ́.

Ìpínlẹ̀ Kogi níílò ọgbọ́n bílíọ́ọ̀ọ̀nù náírà láti san owó owó àjẹmọ́nú- Gómìnà Bello.

Gómìnà Bayelsa àti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ànọ́ ṣí iṣẹ́ àkànṣe àtúnṣe ojúnà Ọ̀yọ́ sí Ìsẹ́yìn.

Àjọ tí ó ń mójútó ètò ìgbòkègbodò Mọ́tò lọ alùpùpù àádọ́jọ ni Olú Ìlú Abuja.

Owó àkànṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ mílíọ̀nù ẹ̀ẹ́dẹ́ gbẹ̀ta àti méjìdínlógójì dọ́là AFDB yóò dín ìṣẹ́ àti ọ̀wọ́n gógó owó ilẹ̀ òkèèrè kù ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àwọn ará ọjà Balógun faraya bí ọjà Balógun ṣe jóná.

Wọn bá òkú àrẹ̀mọ àti obìnrin kan ní ìhòòhò nínú Mọ́tò.

Orílẹ̀ èdè UK bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ètò fífún ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ìwé ìwọ̀lú padà.

Àjọ NPFL, Eyimba àti Rangers rí onígbọ̀wọ́

Arsenal fi ìyà jẹ West Ham.

Ndidi, Iheanacho gbé ọ̀ṣùbà káre sí Aguero tí ó fẹ̀hìntì lójijì.

Christian Eriksen dágbére fún àwọn agbábọ́ọ̀lù Inter Milan.

Ọlọ́run kò ní tìwá jábọ́.

Àyìnlá Omi.

16/12/2021

Ìròyìn Àwòko

Ìjọba Àpapọ̀ bọwọ́lu àlékún owó oṣù àwọn ọlọ́pàá.

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nìkan ló lè gba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà là - Obaseki

Ìgbìmọ̀ aṣọ̀fin bọwọ́lu kí Ààrẹ Buhari yá owó bílíọ̀nù mẹ́fà dín díẹ́ dọ́là láti ilẹ̀ òkèèrè.

Ilé ìgbìmọ̀ aṣojú aṣọ̀fin fajúro bí ìjọba àpapọ̀ ṣe gbé iṣẹ́ àgbàṣe oní mílíọ̀nù mẹ́tàléláàdọ́rin dín díẹ̀ dọ́là fún ilé iṣẹ́ òkèèrè.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ró àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀hìntì ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lágbára.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Edo ṣe kìlọ̀kìlọ̀ fún àwọn abánikọ́lé kí wọ́n má ra ilẹ̀ ayédèrú tàbí ta ilẹ̀ ìjọba.

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tí wọ́n yìnbọn pa ènìyàn ní Akwa.

Ìjọba àpapọ̀ lè sún ètò ìforúkọsílẹ̀ síímùù síwájú.

Sheikh Gumi ṣe àlàyé ìdí tí àwọn òní-sùnmọ̀mí ṣe ń pa ènìyàn.

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fi àwọn tí wọ́n já wọ ilé adájọ́ Mary Odili lọ́nà àìtọ́ sí àtìmọ́lé.

Àjọ EFCC mú àwọn tí wọ́n ń ṣe owó ayédèrú.

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá mú onílé tí ó da ògùn olóró sniper sí yààrá ayálégbé rẹ̀.

Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Fani Kayọde sí ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Kejìlá.

Kòkòrò omicron ń tàn bí iná pápá ní orílẹ̀ èdè mẹ́tàdínlọ́gọ́rin- Àjọ àgbáyé.

Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n dá Jacob Zuma padà sí ẹ̀wọ̀n.

Ọba Sàtánì tí ó ní ìyàwó ọgọ́ta àti ọmọ ọ̀ọ́dúnrún tí fi àyè sílẹ̀.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ́ọ̀lù Real Madrid Modric àti Macelo ti lùgbàdí kòkòrò covid 19.

Ire ọwọ́ wa kò ní jábọ́. Ááṣẹ.

Àyìnlá Omi.

Gómìnà Sanwoolu, Lọ́jọ́ọ Mánigbàgbé Nínú Ètò Ẹ̀kọ́! Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejìlá ọdún 2021 nínú ètò ẹ̀kọ́  nìpínlẹ̀ Èkó jẹ́...
15/12/2021

Gómìnà Sanwoolu, Lọ́jọ́ọ Mánigbàgbé Nínú Ètò Ẹ̀kọ́!

Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejìlá ọdún 2021 nínú ètò ẹ̀kọ́ nìpínlẹ̀ Èkó jẹ́ ọjọ́ ńlá.

Gómìnà Babajídé Sanwóolú ṣí ilé ìwé ìgbàlódé Ẹlẹ́mọrọ̀ Community school ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìbẹ̀jù Lẹ́kí.

Ilé ìwé ìgbàlódé yìí yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ìwé ìjọba nítorí wọn kọ àwọn ǹkan wọ̀nyí kún ilé ìwé yìí:
Ilé ìwòsàn
Ilé ìkàwé
Ilé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀
Ilé ìmọ̀ orin
Pápá ìṣeré ìgbàlódé.

Gómìnà Babajídé Sanwóolú sọ pé kíkọ irú ilé ìwé ìgbàlódé yìí wà nínú àfojúsùn THEMES Agenda.

Ẹ Gbọ́, ṣe owó gọbọi tí gómìnà ná lórí ilé Ẹ̀kọ́ yìí kò pọ̀jú fún idagbasoke eto ẹ̀kọ́?

Kí ni èrò yín?

15/12/2021

Ìròyìn Àwòko

Ipò Ààrẹ: Tinubu sọ pé òun kò ní kọ ìpè àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ààrẹ Buhari yan àwọn Mínísítà tuntun, ó ń dúró de ìbuwọ́lù ìgbìmọ̀ aṣòfin.

Ilé iṣẹ ológun fi ojú àwọn tí wọ́n ń ṣe agbátẹrù àwọn apanijayé lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà hàn.

Ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ sọ pé Kanu ń gbádùn bí èèrà inú ṣúgà ni àkàtà wọn.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó gbé ìgbésẹ̀ láti dẹkùn ìjàmbá àwọn Mọ́tò agbépo ni ìpínlẹ̀ Èkó.

Gómìnà Wike sọ pé ẹni tí yóò rọ́pò òun yóò ní ìfẹ́ àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ Rivers.

Sanwóolú ṣí ilé ìwé yára ìkàwé méjìdínlógún àti ibí ìṣeré ìgbàlódé ní Ìbẹ̀jú Lẹ́kí.

Ìjọba Àpapọ̀ sọ pé àwọn ìgbéyàwó tí wọ́n ṣe ni Ìkòyí Registry bá òfin mu.

Ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ buwọ́ lu àbá ìṣúná owó bílíọ̀nù igba-lé mẹ́rìn-lé-làádọ́rùn- ún tí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọdún 2022.

Àwọn onímótò èrò fún ìjọba Èkó ní gbèdéke kí wọ́n dá àwọn ẹgbẹ́ onimọto lọ́wọ́ kọ lórí gbígba owó lọ́wọ́ àwọn awakọ̀.

Àwọn Gómìnà ìlà Òòrùn Àríwá ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ ní Ìpínlẹ̀ Yobe.

LAWMA ṣe ayẹyẹ orin Kérésìmesì ìparí ọdún 2021.

Sanwóolú yóò kọ àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ẹgbẹ̀rún kan níṣẹ́.

Ajọ́ ilẹ̀ Àgbáyé sọ pé kòkòrò omicron ń tàn bí iná pápá.

Ìjọba UK gbé òté kúrò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ilé iṣẹ́ NNPC ṣé ètò bí owó afẹ́fẹ́ ìdáná yóò ṣe wálẹ̀.

Ọmọ Ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà kọ̀ọ̀kan ń gba mílíọ̀nù méjìléláàdọ́ta, ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin kọ̀ọ̀kan ń gba mílíọ̀nù méjì lélọ́gbọ̀n-Lawan.

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́ọ̀lù Arsenal gba ipò Balógun kúrò lọ́wọ́ Aubameyang.

Ayé wa kò ní dojú rú.

Àyìnlá Omi.

Kílódé Tí Ilé-Ẹjọ́ Wọ́gilé Ìgbéyàwó Ìkòyí? Ẹ̀yìn Ìyàwó Ò Mà Gbọdọ̀ Mẹníì🙄👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡
14/12/2021

Kílódé Tí Ilé-Ẹjọ́ Wọ́gilé Ìgbéyàwó Ìkòyí?
Ẹ̀yìn Ìyàwó Ò Mà Gbọdọ̀ Mẹníì🙄

👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡

Méjì náà ni!..... 👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡
14/12/2021

Méjì náà ni!.....

👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡

Ará Òwu Kìí Rán'ró, Àwíì-Mẹ́nu-Kúrò Ni T'Òwu...........👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡
14/12/2021

Ará Òwu Kìí Rán'ró, Àwíì-Mẹ́nu-Kúrò Ni T'Òwu...........

👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡

Ẹ Jẹ́ Ká Jọọ Gbé Òńkà Yìí Yẹ̀wò🤗👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡
14/12/2021

Ẹ Jẹ́ Ká Jọọ Gbé Òńkà Yìí Yẹ̀wò🤗

👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡

14/12/2021

Ìròyìn Àwòko.

Mínísítà ètò ìṣúná sọ pé ètò owó orí ìmíràn ń bọ̀ ni ọdún 2022.

Ilé iṣẹ́ Ààrẹ sọ pé ìwà ìfẹ̀míṣòfò kìí ṣe ìwà Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Gómìnà Sanwọ́olú ṣí àwọn ojúnà tí ìjọba rẹ̀ túnṣe ní Victoria Island.

Gómìnà Umahi sọ pé àwọn Ẹgbẹ́ IPOB kò lè dí àbẹ̀wò Ààrẹ lọ́wọ́.

Gómìnà Mákindé ṣe ìfilọ́lẹ̀ iná ọba òní bílíọ̀nù mẹ́jọ náírà.

Ilé iṣẹ́ ológun rọ àwọn ológun kí wọ́n má a fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ wọ́n.

Ààrẹ Buhari, Makinde, Obasanjo àti àwọn ìmíràn ṣe ìdárò Sọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ̀

Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ìlera sọ ìdí tí àwọn dókítà òyìnbó ṣe ń fi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sílẹ̀.

Agbẹjọ́rò Falana rọ àwọn ọlọ́pàá kí wọ́n mú Kẹ́mi Olúnlọ́yọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ikú Sylvesta ilé ìwé Dowen.

Bílíọ́nù méje owó ẹ̀yáwó àyáàsan kóbá ètò ọ̀gbín ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ Èkó mílíọ̀nù méjì-dín-díẹ̀ ni wọ́n ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára ìdènà covid 19 ní Ìpínlẹ̀ Èkó.

Ilè iṣẹ́ ìforúkọsílẹ̀ fi orúkọ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà mílíọ̀nù ọgbọ́n sílẹ̀ ni ọdún kan, bí gbogbo ètò ìforúkọsílẹ̀ ṣe wọ mílíọ̀nù àádọ́rin mílíọ̀nù ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ètò ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìgbàlódé yóò pèsè ìṣẹ́ ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù kan ní ọdún 2025.

Èyàn ogún pàdánù ẹ̀mí nínú ìjàmbá Mọ́tò ní Ìpínlẹ̀ Bauchi.

Àwọn ènìyàn mẹ́rìnlá jàjàbọ́ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní Ìpínlẹ̀ Sokoto.

Ìjàmbá iná jó ọjà Computer Village ní Ìpínlẹ̀ Èkó.

Ọmọdé kan dánọ́ sun ara rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Russia.

Pinnick sọ ìdí tí wọ́n fi yọwọ́ Gernot Rohl láwo.

Àjàṣẹ́gun ni a máa jà lónìí lágbára Ọlọ́run. (Ááṣẹ)

Àyìnlá Omi.

👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡

13/12/2021

Ìròyìn Àwòko Fiban Èkó News

(1) Ààrẹ Buhari, Jonathan péjú ní ìpàdé Ecowas.

(2) Ayu sọ pé Ẹgbẹ́ PDP yóò jáwé olúborí ní Ìpínlẹ̀ márùndínlọ́gbọ̀n ní ọdún 2023.

(3) Ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́ wàjà.

(4) Obásanjọ́ ṣe ìdárò Ṣọ̀ún

(5) Ajọ Serap rọ lawan àti Gbàjàbíàmílà kí wọ́n wádìí bílíọ̀nù mẹ́wàá owó ìgbìmọ̀ aṣòfin.

(6) FRSC ṣe kìlọ̀kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ NURTW kí wọ́n bẹ̀rù òfin ìrìnà.

(7) Àwọn jàǹdùkú ń béèrè mílíọ̀nú kan owó orí ní Ìpínlẹ̀ Zamfara.

(8) Ilé iṣẹ́ ológun sọ pé àwọn jàǹdùkú kò jí àwọn ènìyàn gbé ní ojúnà Maiduguri sí Damaturu.

(9) Wọn ti rí Janet ọmọbìnrin tí wọn jí gbé ní ìlú Èkó.

(10) Wọ́n jí ẹ̀gbọ́n Sheikh Gumi gbé

(11) Ikú akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé Dowen: ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá mú akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún àti òbí mẹ́ta.

(12) Wọ́n ká ìdí àádọ́rin òògùn olóró kookéènì mọ arìnrìn-àjò Italy lọ́wọ́.

(13) Orílẹ̀ èdè UAE bẹ ìjọba Nàìjíríà kí wọ́n fi ààyè gba Emirate ni Nàìjíríà.

(14) Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fi òfin de Canada, Saudi Arabia àti àwọn orílẹ̀ èdè ìmíràn.

(15) Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Totheham, Man United nífẹ̀ẹ́ sí adẹ̀hìnmú Chelsea Christensen.

(16) NFF júwe ilé fún Rohr, wọ́n gba Eguavon gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá fìdíhẹ́.

À rí Ajé Jẹun lónìí (Àṣẹ)

Àyìnlá Omi

Ẹ kú ojúmọ́ o
13/12/2021

Ẹ kú ojúmọ́ o

Address

Lagos

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when FIBAN LAGOS posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to FIBAN LAGOS:

Videos

Share


Other Media/News Companies in Lagos

Show All