Ewulayetv+ Yoruba

Ewulayetv+ Yoruba Ẹ KABỌ sori ikanni EWULAYETV+ YORUBA pẹlu ìròyìn lede Yorùbá, Ìtàn àwọn akọni nilẹ̀ Adulawọ atbbl. Live Online TV

21/04/2024

IYA ỌKỌ GBÀ ÌYÀWÓ ỌMỌ RẸ LÉTÍ, NÍ ÌYÀWÓ NÀÁ BA GBÀ TI Ẹ PADÀ, Ẹ GBỌ TA LO JẸBI?

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA
fans

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀ÀGBÀ MẸ́TAAPRIL 21, 2024 Àgbà mẹ́ta kì í ṣi ẹ̀kùlù pè:Bí ẹnì èkín ní bá pe ẹkúlú. Ẹni èkejì á pe, ẹkùlu. Àgb...
21/04/2024

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀
ÀGBÀ MẸ́TA
APRIL 21, 2024

Àgbà mẹ́ta kì í ṣi ẹ̀kùlù pè:
Bí ẹnì èkín ní bá pe ẹkúlú. Ẹni èkejì á pe, ẹkùlu. Àgbà kẹta a sì pe ẹ̀kùlù jálẹ̀ Kooroko.

Orí ènìyàn kì í burú, kó má ni nǹkan méjì nílé ayé:
Bí kò bá ní omi nínú àmù yóò ní ikun ni imú.

Ìyá méjì kì í jẹ Òkóbó:
Bí Òkóbó kò bá lè sun oorun ọmọ, yóò le tọ̀.

Ènìyàn méjì kì í pàdánù irọ́:
Bi ẹni tí a n pa irọ́ fún kò bá mọ̀, ẹni tó n pa irọ́ mọ̀ ní ọkàn rẹ̀ pé irọ́ ni òun n pa.

➖➖➖➖➖➖➖➖
Ìwọ tí o n ka àtẹ̀jíṣẹ́ yìí, Ojú rẹ kò ní í fọ́. Eti rẹ kò níí di. Gbogbo àwọn ẹyà ara rẹ, kò ní í da iṣẹ́ silẹ̀, lasẹ Èdùmàrè.

Ileeṣẹ Ewulayetv+ Yoruba ló n kí wa pé a kú ìsinmi òní.

✍️ Wòlíì Fágbọrọ̀ Emmanuel

ÌRÒYÌN: Mohbad kọ lo sọ ọmọ rẹ ni Liam, Victor ni mo fẹ sọ ọ, wọn ko si gbe olubi ọmọ yẹn fun wa n'igba ti wọn bi i - Ba...
20/04/2024

ÌRÒYÌN: Mohbad kọ lo sọ ọmọ rẹ ni Liam, Victor ni mo fẹ sọ ọ, wọn ko si gbe olubi ọmọ yẹn fun wa n'igba ti wọn bi i - Baba Mohbad tun da wahala tuntun silẹ

Mohbad kọ lo sọ ọmọ rẹ l'orukọ Liam, Victor ni mo fẹ sọ ọ, koda, wọn ko gbe olubi ọmọ yẹn fun wa n'igba ti wọn bi i, eyi fi han pe, ọtọ l'ẹni to ni ọmọ - Pasito Joseph Aloba, Baba Mohbad tun da wahala tuntun silẹ

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA
fans

ÌRÒYÌN: A ṣe àṣìṣe, kìí ṣe DJ Switch ni a mú - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàáApril 17, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba Ṣe lootọ ni pe Ileeṣẹ Ọ...
18/04/2024

ÌRÒYÌN: A ṣe àṣìṣe, kìí ṣe DJ Switch ni a mú - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
April 17, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Ṣe lootọ ni pe Ileeṣẹ Ọlọpaa ti mu gbajugbaja oluwọde Endsars, Obianuju Catherine Udeh ti ọpọ mọ si DJ Switch saa ahamọ?

Ibeere yii ni ọpọ n bi arawọn lẹyin ti ọpọlọpọ rogbodiyan bẹ silẹ lori ayelujara.

Saaju ni Ileeṣẹ ọlọpaa kede sita pe ọwọ awọn ti tẹ ọdọbinrin naa fẹsun pe o kọlu Ọlọpaa kan.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin lo ti kọkọ fidi iroyin naa mulẹ sugbọn o pada jade sita tọrọ aforijin lọwọ oniweroyin pe a siṣe ni.

Hundeyin ni DJ Commissioner Wysei ni o wa atimọlẹ ki ṣe Dj Switch.

“Asiṣe ti wa lati ọwọ wa. Ẹni ti ọwọ wa tẹ ni DJ Commissioner Wysel ki ṣe DJ Switch.

“Mo tọrọ aforijin lọwọ awọn Ileeṣẹ iroyin ti mo ti kọkọ fi di rẹ mulẹ fun wọn pe ọwọ ti tẹ DJ Switch .

“Bakan naa ni mo tọrọ aforijinlọwọ DJ Switch naa.”

- EWULAYETV+ YORUBA
fans

ÌRÒYÌN: Irọ́ ni pé mo wà ní àhámọ́ Ọlọ́pàá - DJ SwitchApril 18, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba Saaju ki agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa...
18/04/2024

ÌRÒYÌN: Irọ́ ni pé mo wà ní àhámọ́ Ọlọ́pàá - DJ Switch
April 18, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Saaju ki agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa Benjamin Hundeyin to bọ sita lati tọrọ aforijin ni DJ Switch ti bọ sori ayelujara lati wọgile iroyin to ni o wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa.

O ni owurọ oni lo da bi ọjọbi oun nitori bi oun ṣe gba ipe ati atẹjisẹ kaakiri lati ọdọ awọn to fẹ mọ pe ṣe lootọ ni oun wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa.

“Orisirisi ipe ati atẹjisẹ lo jimi laarọ yii. Mo bẹrẹ si ni ma ro pe ki lo ṣẹlẹ, oni kọ ni ọjọbi mi.

“Ko pẹ lo han si mi pe wọn ni mo wa ni ahamọ Ileeṣẹ ọlọpaa.

“Koda iroyin kan ni mo kọlu Ọlọpaa. Lootọ n ko ni fẹ awọn ọlọpaa yii sugbọn mo lodi si irufẹ iwa pe ki eeyan kọlu ọlọpaa.

“Awọn akọroyin ni lati ma ṣe iwadii saaju ki wọn to gbe iroyin sita nitori o lewu pupọ.”

DJ ti wa sọrọ labẹ ohun ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa gbe sita nibi to ti n tọrọ aforojin pe oun ti forijin fun asiṣe naa.

• Taa ni DJ Switch?

Orukọ abisọ DJ Switch ni Obianuju Catherine Udeh, o jẹ olorin to gbegba oroke ninu idije X Factor akọkọ iru rẹ, ti ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ Glo ṣagbatẹru rẹ lọdun 2013.

O jẹ ọmọ ilu Udi, ni ipinlẹ Enugu, oun si ni abikẹyin iya rẹ.

O kẹkọọ jade ninu imọ Geology ni Fasiti ijọba apapọ to wa ni ilu Port Harcourt, ni ipinlẹ Rivers.

Okiki rẹ bẹrẹ si n kan lẹyin ti oun ati ẹgbẹ rẹ Da Pulse jawe olubori ninu idije orin Star Quest lọdun 2009.

Lẹyin naa lo gbe awo orin kan jade eyii to pe akori rẹ ni "So tey," ti olorin takasufẹ ilẹ Amẹrika, Busta Rhynes kopa ninu rẹ.

Ko pẹ si asiko naa to darapọ ileeṣẹ to n gbe orin jade, Sony Music.

DJ Switch jẹ ọkan gboogi lara awọn to n lọgun iwọde End SARS lori ayelujara.

- EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌRÒYÌN: EFCC kede gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello gẹgẹbi afurasi ti wọn nwaAjọ to n gbogun ti eto ọrọ-aje ati...
18/04/2024

ÌRÒYÌN: EFCC kede gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello gẹgẹbi afurasi ti wọn nwa

Ajọ to n gbogun ti eto ọrọ-aje ati inawo ti kede pe gomina tẹlẹ nipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, ni awọn nwa fun awọn ẹṣẹ to jọmọ awọn iwa ọdaran jiji owo ilu ko.

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA fans

18/04/2024

witi ẹ 🙏🙏🙏

ÌRÒYÌN: Gbajumọ ajafitafita fun iṣẹlẹ Endsars, Dj Switch lagbọ wi pe awọn Ọlọpaa ti mu ni ilu Eko bayii.Ewulayetv+ Yorub...
18/04/2024

ÌRÒYÌN: Gbajumọ ajafitafita fun iṣẹlẹ Endsars, Dj Switch lagbọ wi pe awọn Ọlọpaa ti mu ni ilu Eko bayii.

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌRÒYÌN: Ọ̀rọ̀ epo pupa dá wáhàlá sìlẹ́ láàrin ìyá àti ọmọ rẹ̀ l'Ọsun, ẹ̀mí ìyá bọ́ síiApril 17, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba...
17/04/2024

ÌRÒYÌN: Ọ̀rọ̀ epo pupa dá wáhàlá sìlẹ́ láàrin ìyá àti ọmọ rẹ̀ l'Ọsun, ẹ̀mí ìyá bọ́ síi
April 17, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Niṣe ni ọrọ di ẹfun abi eedi ni ilu Kajọla, Apomu Ikire, ijọba ibilẹ Isọkan, ipinlẹ Ọsun nigba ti iroyin gbode pe ọkunrin kan pa iya rẹ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe ọrọ owo epo pupa lo da awuyewuye silẹ laaarin iya ati ọmọ naa ko to di pe ọmọ naa ti iya rẹ ti iya naa si gba ibẹ jẹ Ọlọrun nipe.

Afurasi naa Luku Odejoju, ẹni ọdun mẹtalelọgọta ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa.

Nigba to fi idi iṣẹlẹ naa fun Bbc, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ọsun, Yẹmisi Ọpalọla ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa aawọ naa.

Opalola ni ọjọ Kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ni nnkan bii aago mẹwaa owurọ ni arakunrin kan ti orúkọ rẹ ń jẹ Rabiu Odejoju ti o gbe ni oko kan ti wọn pe orúkọ rẹ ni Kajola ni Apomu Ikire lọ fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa.

Rabiu Odejoju lo wa si agọ ọlọpaa to wa ni Apomu Ikire to si salaye iṣẹlẹ laabi ọhun wi pe afurasi Luku Odejoju tii iya rẹ ọmọ ọgọ́rùn-ún ọdun lulẹ ti iya naa si gbe ẹmi mi.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa ṣalaye wi pe ohun to fa Isẹlẹ naa ni bi afurasi Luku Odejoju se tii iya rẹ Aminat Yusuf Odejoju lulẹ nitori ọrọ epo pupa.

O tẹsiwaju wi pe afurasi naa nigba ti awọn n gba ọrọ énu rẹ kalẹ ni oun ko ṣa deede ti iya naa ṣubu nitori epo pupa, sugbọn ọrọ awọn ko ye ara awọn bi oun ṣe n ṣalaye fun mọmọ oun bi ọrọ epo pupa naa se jẹ.

“Ṣugbọn lojiji ni ọwọ mi ṣa deede gba mọmọ lẹgbẹ ti iya naa si ṣubu lulẹ lojiji to si gbe ẹmi mi,” afurasi naa sọ fun awọn ọlọpaa.

Opalola ni oku iya naa ti wa ni ipamọ bayii

Bakan naa lo ni iwadi ọrọ naa n tẹsiwaju ati wi pe afurasi naa, Luku Odejoju ti wa ni kolo awọn ọlọpaa bayi fun iwadii to peye.

- EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌRÒYÌN: Ilokulo Naira: Ile-ẹjọ ti gba beeli Cubana pẹlu owo miliọnu mẹwaa (N10m)April 17, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba Ile-ẹ...
17/04/2024

ÌRÒYÌN: Ilokulo Naira: Ile-ẹjọ ti gba beeli Cubana pẹlu owo miliọnu mẹwaa (N10m)
April 17, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Ile-ẹjọ giga ti ijọba apapọ ni ipinlẹ Eko, ni ọjọ Wẹsidee, fun gbajugbaja oniṣowo, Pascal Okechukwu, ti gbogbo eniyan mọ si Cubana Chief Priest, ni beeli N10m pẹlu oniduuro meji.

Saaju akoko yii, okunrin gbajugbaja naa ti sọ pe oun ko jẹbi owo naira nibi igbejo rẹ.

Orisun: Segun Odunayo
- EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌRÒYÌN: Lónìí ní àjọ EFCC n gbé Cubana lọ sílé ẹjọ́ pe òun náà ṣe owo náírà niṣekuṣe bíi tí BobriskyApril 17, 2024 | Ewu...
17/04/2024

ÌRÒYÌN: Lónìí ní àjọ EFCC n gbé Cubana lọ sílé ẹjọ́ pe òun náà ṣe owo náírà niṣekuṣe bíi tí Bobrisky
April 17, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ti sọ pe awọn yoo fi oju gbajugbaja oniṣowo nni, Pascal Okechukwu ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Cubana Chief Priest ba ile-ẹjọ.

Ẹsun ti ajọ EFCC fi kan Cubana Chief Priest ni pe o wa lara awọn to n ṣe owo naira niṣekuṣe, gẹgẹ bi eyi ti wọn fi kan ọdọmọkunrin to n ṣebi obinrin nni, Idris Ọlanrewaju Okuneye ti ọpọ mọ si Bobrisky.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni ile-ẹjọ giga apapọ ju Bobrisky sẹwọn oṣu mẹfa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lai fi aye silẹ fun owo itanran rara.

Oni tii ṣe Ọjọru ni ajọ EFCC sọ pe Cubana Chief Priest yoo fi oju ba ile-ẹjọ giga apapọ to wa niluu Eko lori bo ṣe n fọn owo ka nita gbangba, eyi ti wọn lo tapa si ofin banki agba orileede yii, iyẹn Central Bank Act of 2007.

Nigba to n fidi iroyin mulẹ, Dele Oyewale to jẹ agbẹnusọ ajọ EFCC sọ pe ọwọ awọn ti tẹ Cubana Chief Priest, ti awọn yoo si fi oju rẹ ile-ẹjọ.

“Bẹẹni, Cubana Chief Priest ti wa ni ahamọ wa, a si maa fi oju ba ile-ẹjọ l’Ọjọru, ọsẹ yii.”

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun 2024 ti a wa yii ni agbẹjọro EFCC, Rotimi Oyedepo ati awọn agbẹjọro meje miran ti wọn ṣoju alaga EFCC, Ọla Olukayọde fi ẹsun kan Pascal Okechukwu wi pe o na owo naira loju agbo, ti wọn si tun n tẹ ẹ mọlẹ.

Ọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 2024 ni wọn sọ pe Pascal ṣe owo naira niṣekuṣe ni otẹẹli Eko (Eko Hotel), eyi ti wọn lo tako ofin banki apapọ lori nina owo naira, to si ni ijiya ninu ni abala kọkanlelogun akọkọ.

- EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀INÁ ỌMỌAPRIL 17, 2024Ohun tí a bá ní, ohun la fi n kẹ́ ọmọ ẹni.Ṣùgbọ́n, a kò lè torí kí ọmọ má bàa kú, kí ìy...
17/04/2024

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀
INÁ ỌMỌ
APRIL 17, 2024

Ohun tí a bá ní, ohun la fi n kẹ́ ọmọ ẹni.

Ṣùgbọ́n, a kò lè torí kí ọmọ má bàa kú, kí ìyá rẹ̀ o ni kí ó sọ ẹpọ̀n bàbá rẹ̀ di gba woroworo ko máa fí ṣeré.

A kò le sọ wí pé, torí k’ọ́mọ má baà kú ki ìyá rẹ o fi ìgbọ̀nsẹ rẹ̀ fọ́ ẹ̀kọ mu.

Ikú tó fẹ pa ọmọ yí ni ko pa mi, ìyá ọmọ yóò lọ́ra tìkọ̀, ko to sọ bẹ́ẹ̀ fún ọmọ tí kò tíì pé oṣù kan tí wọ́n bí i.

Ọmọ tó bá dára, dídùn inú bàbá rẹ ni, ṣùgbọ̀n ọmọ burúkú ni ìbànújẹ ìyá.

➖➖➖➖➖➖➖➖
Ìwọ tí o n ka àtẹ̀jíṣẹ́ yìí, Iná ọmọ kò ní jó ọ, wọn ko ni fi ọmọ pa ọ l'ẹ́kún, l’áṣẹ Èdùmàrè. 🙏🙏🙏

Ileeṣẹ Ewulayetv+ Yoruba ló n kí wa kú ojúmọ́.

✍️ Wòlíì Fágbọrọ̀ Emmanuel
EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌRÒYÌN: A o kábamọ̀ ìgbésẹ̀ wá rárá - Afurasí ajìjàgbara Oodua NationApril 16, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba Ileeṣẹ ọlọpaa ip...
16/04/2024

ÌRÒYÌN: A o kábamọ̀ ìgbésẹ̀ wá rárá - Afurasí ajìjàgbara Oodua Nation
April 16, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti safihan eeyan mọkanlelogun to jẹ ajijagbara olominira Oodua Nation to yawọ ọfisi Gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo.

Ninu ifọrọwerọ wọn pẹlu awọn akọroyin, pupọ awọn afurasi yii ni awọn ko fi igba kankan kabamọ igbesẹ ti awọn gbe rara nitori o ba ofin mu.

Awọn afurasi ni awọn ko fi ọbẹ ẹyin jẹ ẹnikẹni ni isu, ti gbogbo igbesẹ ti wọn gbe lo jẹ eyi to ni atilẹyin ofin lọwọ.

Alabi Ogundeji, ẹni ọdun marundinlọgọta to jẹ olukọ ile ẹkọ gbogbo nise College of Education ti ijọba apapọ to wa niluu Oyo sọ fun awọn akọroyin pe ọkan oun balẹ pupọ nitori oun wa lori ẹtọ oun, to si tun jẹ ko di mimọ pe nnkan ti oun gunle jẹ nnkan to ba ofin Naijiria ati agbaye mu.

“Mo wa lara awọn ajijagbara, mi o le sọ pe mi o ki n ṣe arawọn. Yoruba gẹgẹ bii ilu nla ti di orilẹede bayii.

“A ni ọpọlọpọ orilẹede labẹ Naijiria, ti Yoruba si jẹ ọkan lara wọn.

“Awọn olori Oodua ti gbe gbogbo igbesẹ to yẹ ki wọn gbe, a ti gunle ayipada ti ọọdẹgbẹta awọn ọmọ Yoruba buwọlu pe ka tẹsiwaju.

“Awọn olori wa lọ si gbogbo ipinlẹ Yoruba lati fun awọn alaṣẹ ni iwe ti awọn olori wa kọ, ti awọn naa si ni ẹda ti wa lọwọ.

“Lẹyin eyi ni akede fun gbogbo agbaye pe Yoruba ti di orilẹede agbaye.

“A wa si ọgba ọfisi Gomina ipinlẹ Oyo lati wa se ajọyọ nitori a ti ni orilẹede ti wa.

“Ko jẹ tuntun pe ilẹ Yoruba ti di orilẹede nitori pe a fẹ da duro fun ara wa. A ti wa pẹlu Naijiria fun ogun ọdun.”

• A gbagbọ ninu awọn olori wa - Afurasi
Ademola Adeniyi, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ti oun naa wa lara awọn afurasi naa ni oun ko kabamọ igbesẹ oun lati darapọ mọ awọn ajijagbara ominira ilẹ Yoruba

“A mọ pe ko si nkankan to n sisẹ mọ ni Naijiria, nkan le fun gbogbo araalu ayafi awọn to wa ni ijọba, a wa ni ọgba ọfisi Gomina, ti a n duro fun awọn olori wa lati wa ba wa sọrọ.

“A gbagbọ pe awọn olori wa mọ nipa ofin, fun idi eyi ẹru ko ba wa lati darapọ mọ wọn nigba ti wọn pe wa.

“Awọn olori wa sọ gbogbo ipenija ti n Ilẹ Yoruba n koju ati bi wọn yoo ṣe pese ọna abayọ.”

• Ki ni Ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Ẹwẹ nigba to sọrọ, Kọmisana ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adebola Hamzat ni iwa ọdaran ni awọn ajijbara na wu eyi to ni ijiya nla labẹ ofin.

O ni ṣeeṣe koko ki orilẹede Naijiria wa ni iṣokan nitori gbogbo igbiyanju awọn eeyan nla ko gbọdọ ja si ofo.

Hamzat ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ko ni fi igba kankan ju wọ didẹkun iwa ibajé lawujọ paapa lọwọ awọn ajijagbara.

- EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌRÒYÌN: Ile-ẹjọ giga to fi kalẹ si ilu Osogbo ti fun, Oyeyẹmi Ọlalekan ẹniti ọpọ eeyan mọsi Emir Ajagungbade ni beeli.Ap...
16/04/2024

ÌRÒYÌN: Ile-ẹjọ giga to fi kalẹ si ilu Osogbo ti fun, Oyeyẹmi Ọlalekan ẹniti ọpọ eeyan mọsi Emir Ajagungbade ni beeli.
April 16, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Emir ẹniti o ti n dojukọ awọn ẹsun ipaniyan, jijinigbe lati bi aimọye oṣu sẹyin ni adajọ ti gba beeli rẹ bayi loni ọjọ iṣẹgun tuuside, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹrin ọdun 2024.

Ninu oṣu kẹta ni Ewulaye Agba ṣe abẹwo si Emir ni ọgba correctional center to wa ni Ile-Ifẹ fun ifọrọwerọ papọ pẹlu ọkan pataki lara awọn oluranlọwọ fun ikọ Ewulayetv+ iyẹn Ọgbẹni Fẹmi Ọlaobaju Sanjọ Obj.

- EWULAYETV+ YORUBA fans
Ajagungbade Emir Emir

ÌRÒYÌN: Ẹgbẹ Afẹnifẹre pé fún ìfìyàjẹ àwọn Afurasí Oodua Nation tó yá wọ ọgbà ọ́físì Gómìnà ỌyọApril 16, 2024 | Ewulayet...
16/04/2024

ÌRÒYÌN: Ẹgbẹ Afẹnifẹre pé fún ìfìyàjẹ àwọn Afurasí Oodua Nation tó yá wọ ọgbà ọ́físì Gómìnà Ọyọ
April 16, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Ẹgbẹ Afenifere ile Yoruba ti bu ẹnu atẹlu bi awọn ikọ ajijagbara Oodua Nation ṣe ya wọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ lọsẹ to kọja.

Afenifere, ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ naa, Comrade Jare Ajayi fi lede fun awọn akọroyin, salaye pe awọn to lọwọ ninu ikọlu gbe igbesẹ naa ni ọna ti ọpọ ọmọ Yoruba ti wọn ni awọn n soju lodi si.

O ni ijọba ni lati ṣe iwadi, ko si fiya jẹ wọn ni ilana ti ofin gbekalẹ lati le jẹ ẹkọ fun awọn eeyan mii to ni erongba irufẹ bẹẹ

Bẹ ba gbagbe, ọjọ Satide ọsẹ to kọja ni awọn eeyan kan to pe ara wọn ajijagbara Yoruba Nation yawọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ni Agodi, ti wọn sapejuwe gẹgẹ bii olu ilu fun Ilẹ Yoruba.

Sugbọn Afenifere ni ko si nnkan to jọ mọ orilẹede Ilẹ Yoruba ni bi kibi.

“Ile Yoruba jẹ ilu kan gboogi to wa labẹ orilẹede Naijiria. Gẹgẹ bii a se mọ, ko si nnkan to n jẹ ominira”

Lọwọ lọwọ bayii, awọn eeyan Yoruba wa ni ipinlẹ Ekiti, Eko, Ogun, Ondo, Osun ati Oyo.

Bakan naa ni wọn ni awọn apa ibi kan ni Kwara, Kogi, Delta ati Edo.

Ajayi ni ọpọ iwa ibajẹ lo wa ni ọna ti awọn oloselu fi n da ri orilẹede Naijiria.

“Ọna abayọ si awọn iṣoro yii ki ṣe jagidijagan. Ohun to yẹ ka ma ja fun ni pe ka wa bi a ṣe wa ọna abayọ si iṣoro orilẹede yii.

“Afenifere si ni igbagbọ ninu iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu to n sapa fun Naijiria ati awọn olugbe rẹ lati ma gbe papọ ni alafia laipẹ.”

Afenifere ni ilana ti awọn ikọ ajijagbara yii gunle ni ko mu ọpọlọ dani rara.

“Bawo ni eeyan kan tabi ẹgbẹ kan ma ro pe ti awọn ba ya wọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ tumọ si pe awọn ti da idasilẹ orilẹede mii.

“Yoruba ma ronu ki wọn to gbe igbesẹ papa irufẹ igbesẹ bayii. Yoruba ko ki n gbe igbesẹ ni ilana yii.

“Wọn yoo ro ori wọn ki wọn to ni awọn gunle nnkan bayii.”

Agbẹnusọ Afenifere wa pe fun iwadi, to si rọ ijọba lati fiya jẹ awọn afurasi naa ni ilana ti ofin gbe kalẹ, eyi to ni yoo jẹ ẹkọ nla fun awọn eeyan mii to ni irufẹ erongba kanaa.”

- EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌRÒYÌN: Yoruba Nation yàtọ̀ sí ẹgbẹ́ tí Dupẹ Onitiri dá sílẹ̀ - Banji AkintoyeApril 16, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba Adari I...
16/04/2024

ÌRÒYÌN: Yoruba Nation yàtọ̀ sí ẹgbẹ́ tí Dupẹ Onitiri dá sílẹ̀ - Banji Akintoye
April 16, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Adari Ilana Omo Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye ni ọrọ ko ri bi ọpọ awọn oni iweroyin ṣe n gbe kiri pe ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua lo wa ni di ikọlu ti awọn ikọ ajijagbara Yoruba Nation kan ṣe si ọgba ọfisi Gomina ipinlẹ Oyo.

Akintoye, ninu atẹjade kan to buwọlu fun akọroyin, salaye pe awọn ikọ ti wọn ṣe ikọlu yii lo wa labẹ idari Dupe Onitiri- Abiola, iyawo gbajugbaja oloṣelu to ti di oloogbe, M.K.O Abiola.

“Awọn ajijagbara yii darukọ wọn, DEMOCRATIC REPUBLIC OF THE YORUBA, ikọ ajijagbara to wa labẹ Arabinrin Dupe Onitiri-Abiola.

“A ni lati tan imọlẹ si ọrọ yii pe, ilana YORUBA NATION ko ni nnkan ṣe pẹlu Arabinrin Dupe Onitiri-Abiola ati ikọ ajijagbara rẹ.”

Bẹẹ ba gbagbe, ni ọsẹ to kọja ni awọn ajijagbara ti wọn pe ara wọn DEMOCRATIC REPUBLIC OF THE YORUBA ya wọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo pẹlu awọn ọmọ ologun wọn.

Awọn ikọ yii tun parọ aṣia orilẹede Naijiria pẹlu ti Yoruba Nation.

• 'Ijọba ni lati kede sita pe awọn n wa Onitiri-Abiola'

Akintoyin ni o ṣeeṣe koko ki ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ gbe igbesẹ ni kiakia, ki wọn si kede sita pe awọn n wa Arabinrin Dupe Onitiri-Abiola lati sọ idi ti ikọlu naa fi waye.

O tẹsiwaju pe bi awọn oni iwe iroyin kan ṣe n gbe kiri pe awọn Ilana ọmọ oodua lo wa ni ikọlu to waye niluu Ibadan ni ko bojumu, to si yẹ ki wọn ṣe iwadii wọn ki wọn to gbe iroyin sita.

“Awọn eeyan to wa labẹ Yoruba Nation jẹ oni suuru eeyan to n gbe igbesẹ ni ilana to ba ofin mu sugbọn awọn ikọ ajijagbara to wa labẹ Dupe Onitiri-Abiola ni wọn jẹ oni jadijagan eeyan ti ko fẹran alaafia ilu.

“A ri fọnran kan nibi ti Arabinrin Dupe Onitiri- Abiola bọ sori afẹfẹ lati fidi rẹ mulẹ pe awọn ni wọn wa nidi ikọlu.

“A n rọ ijọba apapọ lati kede sita pe wọn n wa Arabinrin Dupe Onitiri-Abiola lati wa ṣalaye idi ti ikọlu naa fi waye.”

- EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌRÒYÌN: A n kilọ fun yin pe ki ẹ tu awọn ọmọ ogun wa silẹ bibẹkọ ẹ ma ri ogun – Awọn Ajijangbara Yoruba ranṣẹ si Makinde...
16/04/2024

ÌRÒYÌN: A n kilọ fun yin pe ki ẹ tu awọn ọmọ ogun wa silẹ bibẹkọ ẹ ma ri ogun – Awọn Ajijangbara Yoruba ranṣẹ si Makinde ati Tinubu.
April 16, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Awọn ti wọn n pe ara wọn ni ijọba adele lorilẹ-ede Yoruba ti sọ pe Aare Bola Tinubu ati Gomina ipinle Oyo, Seyi Makinde, yoo koju ija ogun ti wọn ba kuna lati tu awọn ajafitafita ti wọn mu nitori gbigbe asia orilẹede Yoruba soke ni ijọba Ipinlẹ Ọyọ. .

Igbakeji alamojuto fun awọn ajafitafita lorilẹ-ede Yoruba, Victor Mobolaji Adewale, tojẹ igbakeji aarẹ adele lo fi ikilọ naa lede.

Adewale, ti oun gbe ni Sweden ti o si n ṣiṣẹ gẹgẹbi Alakoso European ti Oodua Progressive Union (OPU), ti wọn yan gẹgẹbi Akingbayi Aarẹ Ọna Kakanfo ti ilẹ Yoruba ni 2020 nipasẹ Gani Adams.

O ni wọn yoo yọ Tinubu kuro nipo Aarẹ ti Makinde ba tesiwaju lati ti awọn eeyan wọn mọ igbekun.

Adewale ni, “Ti Seyi Makinde ko ba da awọn eeyan wa ti wọn mu silẹ, ti wọn si je ki wọn sun ninu sẹẹli pẹ, o ti pe ogun, yoo si kan Bọla Tinubu naa pupọ. Ọna ti a o gba gbẹsan, ko le ye yin in.

“Wọn pami lasẹ lati kilọ fun yin fun igba ikẹhin, Seyi Makinde gbọdọ tu awọn jagunjagun wa ti o mu ni ile-iṣẹ ijọba ni Ibadan. Kíákíá ló gbọ́dọ̀ tú wọn sílẹ̀, kó si dá wọn padà sí ilé-iṣẹ́ ijọba, kí wọ́n máa ṣe tiwọn níbẹ̀, ká sì máa ṣe tiwa.

“Ti o ba tesiwaju lati mu wọn, nibikibi ti o ba wa…, Tinubu, maa gbe ijọba silẹ. Ẹ lọ bèèrè lọ́wọ́ àwọn baba yín, àwọn lẹ́tà ìkéde wa tí wà lọ́dọ̀ wọn. Tinubu, Tunji Disu, Makinde ati gbogbo Amọtẹkun ni ilẹ Yoruba ati ẹyin olopaa, ẹ gbọdọ tu awọn eeyan yẹn silẹ lẹsẹkẹsẹ. Ogun n bọ atipe mo fẹ ki awọn ọmọ Yoruba jade lapapo lati ṣe ifẹhonu han. Sibẹsibẹ, boya ẹ fẹ tabi ẹ ko fẹ, a ti ni ijọba adele ni bayi fun Orilẹ-ede Yoruba.”

EWULAYETV+ YORUBA
fans

ÌRÒYÌN: A kò ní fi ààyè gba àwọn tó bá fẹ́ dá wàhálà Yoruba Nation sílẹ̀ l'Ọ́ṣun - AdelekeApril 15, 2024 | Ewulayetv+ Yo...
15/04/2024

ÌRÒYÌN: A kò ní fi ààyè gba àwọn tó bá fẹ́ dá wàhálà Yoruba Nation sílẹ̀ l'Ọ́ṣun - Adeleke
April 15, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun ti gbe awọn ẹṣọ aabo dide lati tako awọn ajijangbara fun idasilẹ ominira ilẹ Yoruba, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni ‘Yoruba Nation Agigators’.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn ajijangbara yawọ ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ninu aṣọ ologun, nibi ti wọn ti lọ da wahala nla silẹ, ṣugbọn ti ọwọ ọlọpaa pada tẹ awọn ti ko dini ni ogun.

Ṣugbọn lati le dẹkun iru iṣẹlẹ yii nipinlẹ Ọṣun, Gomina Adeleke ti paṣẹ fun oludamọran pataki lori ọrọ eto aabọ, Samuel Ojo lati dide si ọrọ naa.

Adeleke ni oun ko laju silẹ lati jẹ ki ohun to ṣẹlẹ nipinlẹ Ọyọ tun ṣẹlẹ nibi toun ti jẹ gomina, fun idi eyi, o ni awọn eleto aabo duro digbi ni igbaradi si ileeṣẹ ijọba ipinlẹ naa.

Bakan naa lo tun ni ki awọn eleto lọ daabo bo ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ tipinlẹ naa, iyẹn Osun State Broadcasting Corporation (OSBC), eyi to ni o ṣee ṣe ki awọn ajijangbara naa kọlu.

A gbọ pe lati ọjọ Abamẹta, ọsẹ to kọja yii lawọn eleto aabo ti lọ duro si awọn ileeṣẹ ijọba ati gbogbo ibi ti ijọba ni dukia to jọju si niluu Oṣogbo fun eto aabo to pe ye.

Adeleke ti wa gba awọn eeyan lamọran lati lo ifẹ, iṣọkan ati lati jẹ ki alaafia jọba lasiko yii.

O ni dipo ki awọn ajijangbara maa pe fun idasilẹ orileede Yoruba, ki wọn gbajumọ bi atunṣe yoo ṣe tubọ deba iwe ofin orileede yii, eyi ti yoo ro awọn ipinlẹ lagbara nipa ojuṣe wọn.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe wahala ko le yanju iṣoro orileede yii, bi ko ṣe ijiroro ati apero to lọ ni ibamu pẹlu iwe ofin, to si loun nigbagbọ pe atunṣe to n lọ lọwọ lori iwe ofin Naijiria yoo tan iṣoro naa.

EWULAYETV+ YORUBA | fans

ÌRÒYÌN: Atiku to jẹ olólùfẹ́ Arsenal, fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn lẹ́yìn tí àwọn Gunners jìyà lọ́wọ́ Aston Villa ní pápá ìṣeré...
15/04/2024

ÌRÒYÌN: Atiku to jẹ olólùfẹ́ Arsenal, fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn lẹ́yìn tí àwọn Gunners jìyà lọ́wọ́ Aston Villa ní pápá ìṣeré Emirates lana

Bi Arsenal ṣe pẹlu aami ayo odo si meji (0-2) sọwọ Aston Villa yatọ si esi ti mo nireti – Atiku

Igbakeji Aarẹ nigbakanri ati oludije fun ipo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ninu idibo gbogboogbo ọdun 2023, Atiku Abubakar, ti sọ pe ijakulẹ Arsenal 0-2 kii ṣe abajade ti oun ati awọn ololufẹ Arsenal miiran reti lati ọdọ ẹgbẹ naa.

Atiku, olólùfẹ́ Arsenal kan tí ó le koko, fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn lẹ́yìn tí àwọn Gunners jìyà lọ́wọ́ Aston Villa ní pápá ìṣeré Emirates.

O fi si oju ọwọ X rẹ ni ọjọ Sundee lati pin awọn ero rẹ lori ibaamu naa, ni sisọ pe o jẹ abajade idiwọ fun ẹgbẹ naa.

Laibikita pipadanu naa, Atiku jẹ alatilẹyin oloootọ ti ẹgbẹ naa ati pe o ni igboya ninu agbara wọn lati yi awọn nkan pada.

Atiku sọpe, "Kii se esi ti a n reti lati ọdọ Arsenal. Ṣugbọn ko tan sibẹ ireti siwa t**i yoo fi pari."

Aston Villa gba awọn wọle lẹẹmeji ni awọn ipele ipari lati ṣe alekun ipese oke-mẹrin wọn pẹlu iṣẹgun 2-0 iyalẹnu ni papa iṣere Emirates ni ọjọ Sundee.

Leon Bailey ati Ollie Watkins lo gba ayo wọle ni Emirates lati doju ifojusọna akọle Premier League ti Arsenal bolẹ.

Orisun: X | atiku

----
Tẹle wa fun awọn iroyin ati awọn fidio lorisirisi | Ewulayetv+ Yoruba | EWULAYETV+ YORUBA | fans

ÌRÒYÌN: Mi ò mọ nǹkankan nípa àwọn ajìjàgbara Oodua Nation tó kọlu ilé aṣòfin n’Ibadan – Sunday IgbohoApril 15, 2024 | E...
15/04/2024

ÌRÒYÌN: Mi ò mọ nǹkankan nípa àwọn ajìjàgbara Oodua Nation tó kọlu ilé aṣòfin n’Ibadan – Sunday Igboho
April 15, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Ajigbara fun ominira ilẹ Yoruba, iyẹn Yoruba Nation, Oloye Sunday ‘Igboho’ Adeyemo ti sọ pe oun ko mọwọmẹsẹ ninu rogbodiyan ti awọn ajiagbara kan fa niluu Ibadan laarọ ọjọ Abamẹta.

Igboho lo sọ ọrọ naa ninu atẹjada kan to fi lede loju opo Instagram rẹ.

O ni oun ko lọwọ ninu ikọlu naa, bẹẹ lawọn ajijagbara ẹgbẹ oun ko ni da irufẹ nnkan bẹẹ laṣa lailai.

“Mo rọ ijọba lati ṣewadii finifini lori ọrọ naa ko si fi oju awọn aṣebi ati abanilorukọjẹ naa lede.”

Ṣaaju laarọ ọjọ Abamẹta ni awọn eeyan kan ti kọkọ kọlu ile igbimọ aṣofin naa, ti wọn si gbiyanju lati gba ibẹ ki awọn agbofinro to ṣi wọn lọwọ iṣẹ.

A gbọ pe awọn eeyan naa yọ asia orilẹede Naijiria to wa nile igbimọ aṣofin naa kuro ti wọn si fi asia Oodua Nation sibẹ.

Wayi o, ọwọ awọn agbofinro ti tẹ diẹ lara awọn eeyan ti wọn funra si pe wọn da rugudu naa silẹ.

fans EWULAYETV+ YORUBA

ÌRÒYÌN: Ijọba ipinlẹ Ọyọ ẹ mọ f'iya jẹ awọn alaisẹ mọ awọn ẹlẹsẹ - Mọlẹbi awọn ẹsọ alaabo abẹle kan pariwo sitaIwadi jẹ ...
15/04/2024

ÌRÒYÌN: Ijọba ipinlẹ Ọyọ ẹ mọ f'iya jẹ awọn alaisẹ mọ awọn ẹlẹsẹ - Mọlẹbi awọn ẹsọ alaabo abẹle kan pariwo sita

Iwadi jẹ ka mọ pe àwòrán tí àwọn òṣìṣẹ́ alaabo gbé síta jẹ ti àwọn ikọ̀ alaabo abẹle kan tiwọn kiise tí ìjọba àmọ́ lásìkò tí àwọn ọmọ Dúpẹ́ Onitiri lọ kọlu ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọ̀yọ́ na ni àwọn tí ẹ ń wo àwòrán wọn yí ń lọ jẹ pe awọn osiṣẹ Civil Defense tí wọn mú lára wọn lórí ọ̀rọ̀ aṣọ wọn tó jọ ti Civil Defense.

Èyí ni àwọn òṣìṣẹ́ alaabo fi dá ọkọ wọn dúró lẹhin ti rogbodiyan yí tí lọlẹ tán ti wọn n kọjá tí wọn lọ.

Aṣọ àwọn wọ̀nyí yàtọ̀ sí ti àwọn tó wà daluru pẹlu ẹri jẹ ka mọ pe awọn osiṣẹ alaabo tán ara ilu jẹ ní pelu gbogbo àwọn ohun tí wọn ko síwájú àwọn alaiṣẹ yìí leyi ti kiise tiwọn.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbọ́dọ̀ ṣe adayanri àwọn tó wà kọlu Sẹkiteriati àti àwọn komọwọ kọmẹsẹ yii.

Oriyọmi Hamzat f'idi ọrọ yii mulẹ lori ẹrọ ayelujara lakoko ti awọn mọlẹbi awọn tiwọn komọ idaluru yii lọsi ileeṣẹ rẹ, o si rọ ijọba lati gbe igbeṣẹ tootọ lori iṣẹlẹ yii koto pẹ.

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA
fans

15/04/2024

ASIRI IBI TÍ DUPẸ ONITIRI KO ASỌ OGUN SÌ TU.

Kí àwọn ìjọba Ìpínlẹ̀ tó kù na tètè bẹ̀rẹ̀ iwadi lori ọ̀rọ̀ yìí.

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA
fans

14/04/2024

Ẹfura ooo, njẹ ẹyin ti gbọ nipa iṣẹ ti wọn npe ni Gbe'na wọle?

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA
fans

14/04/2024

Ẹ wo adele tiwọn yan fun Orilẹede Yoruba, Ṣugbọn Sunday Igboho ati Ọjọgbọn Banji Akintoye lawọn ko mọ si.

Kini ero ti yin ẹyin Baba ati Mọmọ wa nilẹ Yoruba?

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA
fans

14/04/2024

ÌRÒYÌN: Dupẹ Onitiri kede pe awọn ti yọn adele Aarẹ fun orilẹede Yoruba

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA
fans

ÌRÒYÌN: Iléesẹ́ ọlọ́pàá ni pé àwọn bá ìbọn, ọ̀pọ̀ ọtá ìbọn, ọ̀pọ̀ àdá àtàwọn ohun ìjà míì lọ́wọ́ àwọn afurasí ajìjàgbara...
14/04/2024

ÌRÒYÌN: Iléesẹ́ ọlọ́pàá ni pé àwọn bá ìbọn, ọ̀pọ̀ ọtá ìbọn, ọ̀pọ̀ àdá àtàwọn ohun ìjà míì lọ́wọ́ àwọn afurasí ajìjàgbara Oodua Nation náà.

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA
fans

ÌRÒYÌN: Iléesẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ ti ṣàfihàn àwọn afurasí ajìjàgbara Oodua Nation tó kọlu ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ n'Iba...
14/04/2024

ÌRÒYÌN: Iléesẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ ti ṣàfihàn àwọn afurasí ajìjàgbara Oodua Nation tó kọlu ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ n'Ibadan.

Nínú àtẹ̀jáde tí alukoro àjọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Olawale Osifeso fi síta, ó ní ogún èèyàn ni ọwọ́ ti tẹ̀ báyìí tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà.

Osifeso tún sọ pé àwọn bá ìbọn, ọ̀pọ̀ ọtá ìbọn, ọ̀pọ̀ àdá àtàwọn ohun ìjà míì lọ́wọ́ àwọn afurasí náà.

📸: Oyo State Police command
Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌRÒYÌN: Awọn ajijangbara f'ominira Yoruba ya wọ ile awọn osiṣẹ ijọba n'Ibadan, ṣugbọn Sunday Igboho ni awọn ko mọ nipa r...
13/04/2024

ÌRÒYÌN: Awọn ajijangbara f'ominira Yoruba ya wọ ile awọn osiṣẹ ijọba n'Ibadan, ṣugbọn Sunday Igboho ni awọn ko mọ nipa rẹ.

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌRÒYÌN: Ọkunrin ni mi, mi o ki i ṣe obinrin o - Idris Okuneye t'ọpọ eeyan mọ si Bobrisky fesi si ibeere Adajọ n'ile-ẹjọE...
12/04/2024

ÌRÒYÌN: Ọkunrin ni mi, mi o ki i ṣe obinrin o - Idris Okuneye t'ọpọ eeyan mọ si Bobrisky fesi si ibeere Adajọ n'ile-ẹjọ

Ewulayetv+ Yoruba
EWULAYETV+ YORUBA fans

ÌRÒYÌN: Ile-ẹjọ ju Idris Okuneye ẹniti ọpọ eeyan mọ si Bobrisky sẹwọn oṣu mẹfa lai f'aaye gba sisan owo itanranApril 12,...
12/04/2024

ÌRÒYÌN: Ile-ẹjọ ju Idris Okuneye ẹniti ọpọ eeyan mọ si Bobrisky sẹwọn oṣu mẹfa lai f'aaye gba sisan owo itanran
April 12, 2024 | Ewulayetv+ Yoruba

Adajọ Abimbola Awogboro ti ile-ẹjọ giga ni ilu Eko ti ṣe idajọ Idris Okuneye, ti gbogbo eniyan mọ si Bobrisky, pẹlu ẹwọn oṣu mẹfa lai ni itanran.

Idajọ naa waye ni owurọ ọjọ Jimọ, oṣu kẹrin ọjọ kẹrin.

Ọjọ karun oṣu kẹrin, ni EFCC gbe Bobrisky lọ si ile-ẹjọ lori ẹsun mẹfa ati ilokulo owo Naira.

Ile-ẹjọ naa, da awọn ẹsun kiko owo pamọ nu ṣugbọn wọn da a lẹbi fun ilokulo Naira lẹhin ti o jẹwọ ẹṣẹ naa.

Ile-ẹjọ tun paṣẹ pe ki wọn fi i sinu atimọle EFCC ni Ilu Eko Adajọ naa sun igbejọ si ọjọ kẹsan oṣu kẹrin. ṣugbọn, ile-ẹjọ ko le joko nitori ọjọ kẹsan ati ọjọ kọkanla oṣu kẹrin jẹ isinmi ọdun itunu awẹ (Eid-Fitri).

Ile-ẹjọ ti niki o lọ si ẹwọn oṣu mẹfa lai f'aaye gba sisan owo itanran.

Address

15 Bishop Street Igbona Area
Osogbo

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Ewulayetv+ Yoruba posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to Ewulayetv+ Yoruba:

Videos

Share