ÌTÈDÓ FM 44.4,Nítèdó.

ÌTÈDÓ FM 44.4,Nítèdó. Enjoying Ìtèdó Radio/Tv station 44.4 always, for your good programs.
..pls stay tuned always...

05/04/2024

ÌRÒNÚ AKÉWÌ
Ọ̀RỌ̀ ṢÙNÙNKÙN

MO ṢE BÍ Ọ̀RỌ̀ ṢÙNÙNKÙN
OJÚ ṢÙNÙNKÙN L'WỌN ÀGBÀ
FI N WÒÓ LÁYÉ IJÓHUN ÀNÁ RÍ?
ÈYÍ TÍ ÀWỌN ÀGBÀÀGBÀ MÁ N PÉ
BÍRÍ-KÓTÓ PÉ BÌRÌ-KÒTÒ LÉ LÓRÍ.

Ó WÁ DÀ BÌ ẸNI PÉ LÓDE TÒNÍ
Ọ̀RỌ̀ ṢÙNÙNKÙN OJÚ GÀN-ÌN-GÀN-ÌN
LA FI N WÒÓ LÓ FI JẸ́ KÍ ÀWỌN
ABẸ́RANJẸ̀ MÁA MÚ WA GÙN LỌ́DẸ̀DẸ̀.

ÀWỌN ABẸ́RANJẸ̀ TÍ N JÍ WA GBÉ
ÀWỌN ABẸ́RANJẸ̀ TÍ N PA WÁ
ÀWỌN ABẸ́RANJẸ̀ TÍ WỌN N MÚ
DÚKÌÁ TI WỌN BA DÚKÌÁ T'ÀGBẸ̀ JẸ́.

ÀWỌN AGBÈFỌ̀BA WÁ TI ÀWỌN
ODẸ ABẸ́RANJẸ̀ SÍWÁJÚ WÍ PÉ
KI WỌN O MÁA MÚ ÀGBẸ̀ TẸ́ KA Ẹ̀SÙN
AWÚRÚJU SÍ L'Ẹ́SẸ̀ LÁÀLÀ.

ÀWỌN AGBÈFỌ́BA WÁ MÚ ÌRÙ ẸKÙN
WỌ́N FI L'ÁJÁ LỌ́WỌ́ NÍNÚ OKO,
ÀWỌN AGBÈFỌ́BA WÁ N RÁN INÁ
N'ÍSẸ́ LỌ WÒÓ WÁ SÍ Ẹ̀TÙ L'Ọ̀SÁN GANGAN,
ṢÉ OHUN TÓ DÁA NI?

BẸ́Ẹ̀ Ẹ Ẹ̀ SÌ ṢALÁÌ MỌ LÀKÁÁDÍ
TÍ N BẸ NÍLẸ̀ TÍ N GBÓNÁ YORUKU LALA
Ọ̀RẸ́ ARÁ ÌLÚ L'ÈMI GBỌ́ PÉ WỌN N PÈ YÍN,
A MỌ́ ṢÁ ÈMI MỌ̀ PÉ ẸNU TI JẸ DODO PỌ̀JÙ
L'Ọ́DỌ̀Ọ ÀWỌN ABẸ́RANJẸ̀ N NI ÒDODO
FI D'OHUN ÀÌ LEÈ SỌ FUN WON MỌ́

HUMMM.. ṢÉ NÍTORÍ OHUN TẸ́NU ŃJẸ
HÀÁÀ! ṢÉ NÍTORÍ PÉ O FẸ́ JẸ́ ÈNÌYÀN
NÍTORÍ KÒO LE R'ÓWÓ GBŌ BÙKÀTÀ
N'IWỌ AGBÈFỌ́BA ṢE N DORÍ ÒFIN K'ODÒ
BẸ́Ẹ̀ NI ÀTÚNBỌ̀TÁN TI PARẸ́ LÓÓKAN ÀYÀ WỌN PÁTÁ PÁTÁ PORONGODO.

ÌYÁ N JẸ WÀ LÓDE Ẹ̀KẸ́Ẹ̀, Ọ̀RỌ̀ ṢÙNÙNKÙN!
ÀBÙKÙN TÍ N KÀN WÀ PỌ̀
NÍ ÌLÚ ÀSÁLÀ YII, Ọ̀RỌ̀ ṢÙNÙNKÙN
Ó TI N KỌJÁ OHUN ÀFẸNUSỌ,
OHUN TÀWỌN AGBÈFỌ́BA Ó JẸ LO JẸ WỌ́N LÓGÚN KÌÍ ṢE WÀHÁLÀ TÁ N KOJÚ NÍLẸ̀ YÌÍ.

Ẹ̀YIN ÀGBÀÀGBÀ TI N BẸ
LÓDE Ẹ̀KẸ́Ẹ̀ YÌÍ {IWERE ILE} NI KO FI OJÚ
ṢÙNÙNKÙN WO Ọ̀RỌ̀ ṢÙNÙNKÙN
TÍ N JÀ RÀN-ÌN-RÀN-ÌN NÍLẸ̀ YÌÍ,
LÁÌ NÍ ỌWỌ́ AGBÈFỌ́BA KAN NÍNÚ.

TẸ BÁ SI FẸ KÍ A FI ÌLÚ WÁ SILẸ FUN
ÀWỌN ABẸ́RANJẸ̀ NI, KẸẸ F'Ọ̀RỌ̀ YÍ SILẸ
LÁÌ MÓJÚ TÓ, KI KÓÓWÀ O KÚKÚ
GBA IBI TÓ BÁ RÍ LỌ.

KÁ KÚKÚ FÍ ÌLÚ SILẸ
FÚN ÀWỌN ABẸ́RANJẸ̀ ÀTI
ÀWỌN AGBÈFỌ́BA
Ọ̀RỌ̀ ṢÙNÙNKÙN NÁÀ RÈÉ O, ẸNI TÓ BÁ YÉ
Ẹ JẸ́ KÍ GBOGBO WA Ó TIIRI SI
NI ÌMỌ̀RÀN TI N BẸ LẸ́NU SIMÁDÉRÓ AKÉWÌ.

28/01/2024

Happy Sunday to you Fans, from Itedo FM 44.4. Nitedo.

07/12/2023

Famous Nigerian child actor Enorense Victory popularly known as Kiriku has 2 million followers on Instagram, 5 million followers on Tiktok, 2.7 million followers on Facebook and 290k YouTube subscribers . With couple of awards , cars and mansions to his name at just 9 years old .

Kiriku is a blessing to his parents . As you celebrate him today others will celebrate you tomorrow.

Congratulations to him , for his great achievements at tender age 👏 🙌.

Please follow my back up page
Its Ode Officiall 👈🏿🙏🇨🇲🇳🇬🇱🇷🇬🇭🇿🇦💚

30/11/2023
03/11/2023

ẸYÌN ỌMỌ TITUN TÓ N BỌ̀ WÁYÉ,
ETÍ YÍN MÉLÒÓ?
Ẹ JẸ́ MỌ ORÍLẸ̀-ÈDÈ TO GBÀ LỌ.
MÁ WÀ RÍYÀ NÍ NÀÌJÍRÍA.
WÒÓ OJÚ Ẹ Á RÍ TÓ!!!

02/11/2023

☹️ÌRÒNÚ AKÉWÌ ☹️
Ọ̀RỌ̀ WỌN TI LỌ́DÍÌ-ÌGBÍN

KÒ LÓJÚÙTÚ, KÒ LÓJÚÙTÚ.
WỌN SO Ó PỌ̀ TÁN KÖ LÓJÚ MỌ́
WỌN TA Á NÍ KÓKÓ TÁN
Ọ̀RỌ̀ WỌN TI WÁ LỌ́DÌÍ ÌGBÍN
OHUN GBOGBO TI WÁ DOJÚRÚ
MỌ́ WỌN LỌ́WỌ́ PO.

WỌN FOJÚ SO OKÙN TÁN
KÒ ṢE É TÚ MỌ́, Ó ṢE FÚN WỌN
OHUN TÍ WỌN Ó SÌ KÚKÚ JẸ
TẸ́LẸ̀ NÁÀ NI WỌ́N WÁ
LÓ MÚ WỌN DI AṢÁÁJÚ PÁNDA.

Ọ̀JẸ̀LÚ LÈRÒ TÍ WỌ́N KÚKÚ BÁ DÉ
ORÍ IPÒ NÁÀ LỌ́JỌ̀SÍ A MỌ̀ BẸ Ẹ
AWÚRÚJU OLÓṢÈLÚ NIWỌ́N JẸ́
OJÚLÓWÓ ỌLỌ́JẸ̀LÚ NIWỌ́N ṢE.

GBANIGBANI ỌBA TÓ DÁ AYÉ,
ELÉTÍ GBÁRÒYÉ ỌLỌ́RUN ÌGBÀLÀ
ALÁGBÁRA TÍ KÖ LẸGBẸ ỌBA AJÍGBỌ́TẸNI
WÁ GBA IPÒ NÁÀ LỌ́WỌ́ WỌN LÓJIÌJÌ
ÀWỌN ÌKÀ OLÓRÍ LÉMI N BÁÁWÍ.

WÁ GBÀJỌBA LỌWỌ ÀWỌN ÌKÀ YÌÍ
WÁ GBÀJỌBA LỌWỌ AWỌN Ọ̀DÁJÚ
WÁ! AṢẸ̀DÁ, KO WÁ GBÈWÁ NÍJÀ.
NÀÌJÁ YÌÍ TÍ N RÍYÁ PÚPỌ̀ JÙ
GBOGBO NKAN PÁTÁ NI KÒ ṢE É RÀ MỌ́
FÚN MẸ̀KÙNÙ, ÀFOLÓWÓ NIKAN.

BÓYÁ WỌN Ò SÌ FẸ́ RÍ MẸ̀KÚNÙ LÁYÉ MỌ
ÀBÍ Ò WÁ ṢE É ṢE NI LÁÌPÉ ỌJỌ́
KÁ GBỌ̀NÀ Ọ̀RUN LỌ FUN WỌN NI?
ÌLÙ BÁMÚBÁMÚ LA YÓ
N NI WỌN N LÙ LÓRÍ ÌJỌBA TÍ WỌN ṢE.

TA BÁ WÁ FI ÀWÒDÌ JẸ AṢÍWÁJÚ ẸYẸ
TÍ KÒ WÁ LE DÁ ÒRÒMỌDÌRẸ GBÉ
TÍ OJÚ BÁ WÁ TI ÀWÒDÌ BẸẸ
TÓ TOKÙN BỌRÙN GBỌ̀NÀ ÒRUN LỌ
KÒ DÁMILÓJÚ PÉ O JẸBI 'KU..

OLÓRÍ TA BÁ WÁ FI SÍPÒ
TÍ KÒ RÍ ÌLÚ TÒ, TÓ SÍ LÓJÚ TÌ
O YẸ KÍ ÌRÒNÚ LE DORÍ IRÚ OLÓRÍ BẸ́ Ẹ̀ KODÒ
N JẸ́ Ó YẸ KÍ IRÚ OLÓRÍ BẸ́ Ẹ̀
LE SÙN TÀBÍ WO?
ABI KÍ NI LÁÁRÍYÀ IRÚ AṢÍWÁJÚ BẸ̀ È?

ÀBÍ KÍNI AGBÁDÁ ÌYÁ ÒUN ÌSẸ́
TẸ N KÓ SÓRÙN KÁ?
ÌBÀNÚJẸ́ TI WA N LAYỌ̀ TI YÍN
Ẹ MA PÀ ÌYÁ MỌ́ D'ỌJỌ́ ÌDÁJỌ́
ÀWỌN APỌ̀DÀ Ọ̀JẸ̀LÚ,
TÓ JẸ́ PÉ IKÚ NÍ Ó PADÀ
ṢÍ WỌN LỌ́WỌ́ IṢẸ́ DÀ SÍ KÒTÒ
NÍGBÀ ÀÌ RÒ TẸ́LẸ̀.

ÀWỌN TÓ JẸ́ PÉ ASÁN
NÍ WỌN N KÓ JỌ LÓRÍ ASÁN,
LẸYÌN TÓ JẸ́ PÉ
ÒFO LẸ̀ N TÒ JỌ SÓRÍ ÒFO
GBOGBO RẸ̀ ÒFO NÁÀ NI.

NÍTORÍ ÒFO LO MÚ WÁYÉ
DANDAN SÌ NI ÒFO NÁÀ
LẸYÌN Ọ̀JẸ̀LÚ WỌ̀NYÍ YÓÒ MÚ LỌ
IKÚ NÌKAN LẸ LE GBÀ FÚN LÁÌ JIYÀN
Ó SÌ TI KÙ SÍ DẸ̀DẸ̀, ÌDÁJỌ́ LÓ KÚ

LẸ́YIN TÓ YẸ KẸ́ Ẹ MÁ LO IPÒ
BÍ ẸNI TÍ KÒ NÍ DỌ̀LA
LẸ WA N GB'ÁYÉ BÍ ẸNI
TÍ KÒ NI KÚ LÁYÉ LÁYÉ.
HÀÁÀ! Ó ṢE FÚN UN YÍN GAN AN NI.

Simádéró Akéwì.

19/10/2023
ÌRÒNÚN AKÉWÌ (lórí ìlú mi)Ẹ̀YIN ÀGBÀÀGBÀ INÚ ÌLÚ YI OOẸ̀YIN ABIYAMO ÌLETÒ YI OOOẸ̀YIN Ọ̀DỌ́ TÍÍ ṢE ỌJỌ Ọ̀LA ÌLÚ YIIẸ BỌ́...
19/10/2023

ÌRÒNÚN AKÉWÌ (lórí ìlú mi)

Ẹ̀YIN ÀGBÀÀGBÀ INÚ ÌLÚ YI OO
Ẹ̀YIN ABIYAMO ÌLETÒ YI OOO
Ẹ̀YIN Ọ̀DỌ́ TÍÍ ṢE ỌJỌ Ọ̀LA ÌLÚ YII
Ẹ BỌ́ SÍ GBÀGEDE LÓJÚ TÁYÉ
MO FẸ BÁ A YÍN NÍ GBÓLÓHÙN

ṢÉ ÀWỌN ÀGBÀ SÌ WÀ L'ỌJA YI ṢÁ?
ÀBÍ Ẹ Ẹ̀ RI BI ORÍ AWỌN ỌMỌDÉ
ṢE N WỌ́ TÍ WỌN FI Ń D'ẸNI
ÀGBÉGBÌN BÍ ÈBÙ NI.

BÓYÁ OGUN L'AWỌN ÀGBÀ
PẸ̀LÚ ÀWỌN OLÓRÍ WỌNYÍ SÌ N SÁ FÚN?
TO MÚ WỌN DA BÍI ỌDÀLẸ̀ LÓJÚ WA
ṢÙGBỌ́N ÀWỌN BABA TIYIN JAGUN FÚLÀNÍ Ọ̀HÚN RÍ, OGUN ÌDÀHỌ̀MÌ NKỌ ṢEBÍ WỌN JÀÁ WỌ́N ṢẸ́GUN.

LÁÌ SÍ ÌRÓ OWÚ ALÁGBẸ̀DẸ
ÒṢÌṢẸ́ KAN KÒ LE RỌ IFE RERE KAN
LÁÌ SÍ ÀGBÉLÈBÚ ÀTI ÌYỌNU ÈMI KÒ LE HUN ADÉ MI T'ÒRUN, Ọ̀RỌ̀ JÉSÙ TẸ LẸ N TẸ̀LÉ NÌYÍ LÁÌ WÀ SÍ OGUN, KÒ SÍ ÌṢẸ́GUN,
LẸ́YÌN ÌṢẸGUN NI ÒMÌNIRA.

JÉSÙ JAGUN ṢẸGUN L'ÓFI DAṢẸ́GUN
DẸNI TÍ TẸRÚ TỌMỌ N KÓKÌKÍ Ẹ̀
ṢÉ ÀNÁBÌ O JAGUN NI? KÓ TÓ DẸNI ÀPÉSIN.

NÍNÚ ÌWÉ ÌTÀN, ÌLÚ WO LÓ GA LÁÌ JAGUN
Ẹ WÁ SỌ FÚN MI, BÓ TILẸ JẸ PÉ OGUN OHUN KÒ DÀ BÍIYÁN ṢÙGBỌ́N LÁÌ JÀÁ
KÒ LÈ SÍ IFỌKANBALẸ FÚN TOLORI TẸLẸ́MÙ.

ÀWỌN WO LÓ N T'ỌWỌ́ WA BỌ ṢỌ̀Ọ̀LỌ̀ GAN?
ÀBÍ ÀGBÀ AJÁ NÍ B'AWỌ JẸ́ NI?
ÀBÍ ÀWỌN TÁA GBÓJÚ OKÙN LE
WA LE MA J'ẸNI AGBA NI?

BÓYÁ OHUN T'Ọ́MỌDÉ SÌ GU IGI TI KO RI
NI N MU ÀWỌN ÀGBÀÀGBÀ WỌ̀NYÍ
ṢE BÍ ENIPÉ WỌN N SÁ F'ÓGUN NI?
ṢEBÍ KÌÍ SÁ A ṢE WÍPÉ NÍTORÍPÉ OHUN
ÀÁ MÚ LỌ S'ENU NI WỌ́N ṢE F'ỌWỌ́ L'Ẹ́RÁN
BÍ ẸNI WÍ PÉ IFÁ TI WỌ́N DÁ, KÒ L'ÉTÙTÙ?

ÀWỌN ỌJỌ́ Ọ̀LA TÍ N KÚ LÓJÚ YÍN WỌNYÍ
LÁÌ JÉ WÍ PÉ Ẹ Ò MỌ IBÍ TÍ IKÚ TÍ N P'AWỌ́N
TÍ N WỌ́ WÁ, BẸ́Ẹ̀ NI WỌN KÒ SÌ Ṣ'ÀTÓWỌ́FÀ
KÍ LÓ WÁ DÉ TẸ́Ẹ FÍ WỌ́N SÍLẸ̀ LÁÌ GBÈJÀ?

ÀBÍ ÀWỌN KAN NÍNÚ AWỌN TÁA GBÓJÚ OKÙN LÉ TÍ O J'ẸNI AGBA
NÍNÚ AWỌN ÀGBÀ TI GBÀ GBÀBẸ̀TẸ́LẸ̀
FI ÀWỌN Ọ̀DỌ́ WỌ̀NYÍ D'ÍGUN.
LẸ TÚN N FI ÀÌGBÈJÀ L'ÉWON L'ÓLÙ GBÈJÀ
FÀWỌ́N L'ÉKÚ L'Ọ́WỌ́ L'Ọ̀SÍN GANGAN.

BÍ BABA BÁ GBÀBỌ̀DÈ F'ỌMỌ
ÌYÁ O SÁÀ RÁNTÍ ỌJỌ́ ÌKÚNLẸ̀
Ẹ̀YIN ABIYAMO ÌLÚ YI OOO
Ẹ̀YIN OBÌNRIN ÌLETÒ YI OO

Ẹ JẸ́ SÁN TÒBÍ ÌKỌ̀YÀ L'Ẹ́YẸ Ọ̀SỌKÀ
KẸ́ Ẹ TÚ U LÓJÚ ÀWON OLÓRÍ ÌKÀ
KẸ Ẹ Ṣ'ÍBI WỌ́N GBÀ WÁYÉ HÀN WỌN
BÓYÁ WÓN A JẸ́ JÁWỌ́ NÍNÚ IṢẸ́ IBI.

BÓYÁ NÍTORÍ DÒDÒ TI WỌN TI JẸ
NÍGBÀ KAN RI LÓ N MÚ ẸNU WỌN
KÒDODO LÓJÓ GBOGBO
BÓ SÌ JÉ DODO T'ÒNÍ LÓ N MÚ UN YÌN
GBÀGBÉ WI PÉ ALẸ́ LÓJÙ, È MÚRA SÍI.

GBOGBO Ọ̀NÀ TÍ
AWỌN Ọ̀BÀLÚJÚ Ọ̀DỌ́ KAN N RÌN
ÀTI Ẹ́BÙRÚ TÍ ÀWỌN ÀGBÀ KAN N TỌ̀
MÚ OMI T'Ẹ̀YÌN WỌ ÌGBÍN ÌLÚ ASÁLÀ YI LẸNU
TÍKÚ ÀWỌN Ọ̀DỌ̀ WÁ FÍ DI
TỌ́Ọ́RỌ́ N FỌ́N KÁLÉ,

LỌ́LÁ AWỌN Ẹ̀JẸ̀, PẸ̀LÚ Ẹ̀MI TÓ JÁBỌ́ LÓJIÌJÌ
DAN DAN NI KÓ Ṣ'ÈDÁJỌ́ LÓRÍ GBOGBO ÀWỌN Ọ̀DÀLẸ̀ LÓNÍLÉ, LÁLEJÒ NÍNÚ ÌLÚ Ẹ̀KẸ́Ẹ̀ YI L'ỌSAN GANGAN NI O ṢEÉ PẸLÚ,

T'ÓBÁ ṢẸLẸ Ṣ'ÍWỌ ṢE YÓÓ DÙN MỌ Ọ
ÀBÍ NÍTORÍ WÍ PÉ, ỌMỌ TIRẸ KỌ́ NI WỌN PA
LOFI LÉRÒ WÍ ÀSÌKÒ ÀTI KỌ̀YÀ KỌ̀ TÍÌ TO
TÉNÍ TODE LARÍ, T'ẸNI TÍ O KAN LÓLA A KÒ TÍÌ MỌ̀ LÓ FI YẸ KÁ ṢÍGUN
FÁWỌN TI YOO GBÈ WÁ NÍJÀ.

JÉÉSÙ OLÙGBÀLÀ DÁKUN GBỌ́!
ÀNÁBÌ DÁKUN TẸ́TÍ SÍ ÀWA ẸRÚ RE
ALÁLẸ̀ ÌLÚ YII GBÉRA SỌ..
OGUN KÒ JÀ JÀ KÓ KÓ ÌLÚ YII RÍ
ṢUGBỌN AWỌN ONIJEKUJE
TI FẸ FOGUN MU WA.

BABA-ỌJÀ ALÁGBO-YẸ̀TÚ OOO
WÁ FILÈ MÚ WỌN
SÀNGÓ OMÍRÌNDÉ OOOO.
WÁ FÀRÁ GBÈJÀ!
ÒGÚN ONÍRÈ OO YÁNKAN-BÍỌGBẸ́
WÁ FI IRIN Ṣ'ÈDÁJỌ́ F'AWON ẸNI IBI
ỌṢỌ́Ọ̀SÌN WÀ F'IGI ÒRÚYAN FÚNWON LỌ́RÙN PA

ÀWỌN WO NI ??????????
ÀWỌN Ọ̀DÀLẸ̀ ṢEKU-ṢẸYẸ NÍNÚ OLÓRÍ
L'ỌKUNRIN TÀBÍ L'OBINRIN
NÍNÚ ÀWỌN Ọ̀DỌ́, L'ỌKUNRIN TÀBÍ L'OBINRIN
LÓNÍLÉ, TÀBÍ LÁKEJÒ,

KÓṢẸ KÓṢẸ NI TILAKỌ̀ṢẸ BI Ọ̀RỌ̀
AWON OLÓDODO ÀGBÀLAGBÀ
ÒÒJỌ́ N LORÓ INÁ MÚ IGI
ÒÒJỌ́ N LÀṢẸ ÌTỌ̀ MÚLẸ̀
ÌRÀWÉ KÌÍ DÁJỌ́ ILẸ̀ KÓ S'ÙNKÈ
KÓ ṢẸ!!!

ORIN DÁFÍDÌ ORÍ KARÙN-DÍN-LÓGÓJÌ
(PSALM 35)
KÓ WÁ LỌ JÍSẸ́ YÀJÓYAJÓ
FÚN GBOGBO ÀWỌN TÓ J'ATA JẸ'YỌ̀
ÌLÚ ÌWÉRÉ-ILÉ TÓ TÚN WÁ DẸ̀YÌNBỌ̀
F'OGUN JA ÌLÚ ÌWÉRÉ-ILÉ
LÁGBÁRA BABA ÈDÙMÀRÈ ÈÈÈ.

30/08/2023

Simádéró Òrò

27/08/2023

Happy Sunday to you all

25/08/2023

On your special day I pray that the ground you walk upon will forever bring you blessing. The sky above will forever release favor on you. May this day mark a beginning of new happiness and chances for my best friend but and my Adviser, happy birthday to you.

20/08/2023

Happy Sunday to everyone!

14/08/2023

Happy birthday 🎂 to you Kofoworola.

13/08/2023

Happy Sunday from Itedo FM 44.4, Nitedo.

10/08/2023

Evangelist Segun Jade-Ogo, May goodness and mercy accompany youtoday and all the days of your beautiful life. Happy birthday to you Daddy.

08/08/2023

Evening!

08/08/2023

Good evening!!

07/08/2023

Thanks God it's a new day from Itedo FM 44.4.
By Simádéró Òrò (the Talkative of Itedo FM)

26/07/2023

Nothing big and nothing small.
May God bless you as you are doing this, Thanks.
WhatsApp. 08055683490

Ac/No. 016572818
Ac/Na. Aderogba Adekunle Simeon
Bank/Na. Union Bank

Address

Oyo

Telephone

+2348055683490

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when ÌTÈDÓ FM 44.4,Nítèdó. posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to ÌTÈDÓ FM 44.4,Nítèdó.:

Videos

Share


Other Broadcasting & media production in Oyo

Show All