28/05/2024
Different "ITEMS" ti o jọ ara wọn....
Eyan ỌBA ♔ ni ̣nna_Oodua!
....
Asoro ba d'owo pọ o, asoro ba d'owo pọ l'Ọkọ Rọpo mi ko sọ fẹ, Ọkọ Toyọsi mi o se rẹ jẹ, ki s'ọọdalẹ atel'eni ma ya ni, Igboho Sunday Baba Ayọmide mi, Eegun to ba tẹẹle lo n l'ero rẹpẹtẹ.
......
Atunf'Igboho Sunday mi, atunf'Igboho Sunday Baba Dammy mi, ti n ba wa ti ri ẹẹlẹ mejeji, Igboho Osha ti n se Ẹgbọn Ifa, iku k'iku ti n paa aarun jẹ, Alujannu eyan ti mo n sọ ko sọ fẹẹ o o.
......
Aapata paara o o, apata para Ọkunrin Ogun, Iku aye ti n pa'Gun jẹ Sunday mi, okuta pataki t'imọle sọ pe ko daa, to wa papa wapada d'igun ile, Igboho Osha owo Baba Dammy mi, o f'ẹpọn d'isa Eejo pinpinpin, o di fami n fa'ẹ l'ọwọ ẹni l'ẹpọn lo ja mọ.
......
Se bo mọ Maja Sunday mi, Majasọla s'ebi o mọ Igboho tan ma n sọ Sunday yẹn, Baba Dammy onisiri eelewele, awifunni ko to b'ani jaa masaa lọ o, against pe boya oni Sigidi kan, ma lo egun ori to ba sa tir'Igboho, ko ma f'ọjọ ọl'ọj̇ọ lọ o k'ore Esu o.
......
Wa n bi so mọ Majashọla iku Baba ẹẹruku, Igboho Osha mi Majashọla iku Baba ẹẹruku, eeleyi tunl'Ọmọ Ogun oni Saabe iku Baba ẹẹruku, Aakọni eniyan ni Majashọla iku Baba ẹẹruku, to ba ma ti mọ Anobi Maja o ma ti mọ'yan, Igboho Osha to ba ri se Tualaa🙌🙌🙌 fun, Irunmọlẹ to n jẹ owo yaa paper fun, Igboho o le gba wipe kan wa ma rẹ'yan jẹ, af'abiku eyan t'iku batiwu to fẹ ku, t'abi were to ba fẹ s'ọnu kan ma ri.
......
L'oogun ọfẹ Majasọla owo Baba Damilọla, Akọni Eniyan l'owo Ọkọ Rọpo mi, b'eyan o l'ogun n'Ibadan rara o debi Isẹyin o, ko ma l'ohun l'ogun l'Eko n'isoju Igboho.
.....
Majasọla mi Sunday mi Igbohoo, Majasọla Sunday t'awọn aye ti mọ s'Igboho, agbadaNla to n yan Guguru waalah ni, ko r'awin ko t'awin Maja ko sin'Wo n'le Aana, or'Iku s'aya di n di Ọkunrin Oogun, ton'Iyawo kukuru l'oojo ijo, Ọmọ buruku wulo funwa n'jọ ti ijangbọn baade.
......
Majasọla Sunday o, Majasọla Sunday Ọka o'ri ebe to n le furukọkọ furukọkọ, Erikina aapa kan Ẹfun aapa kan Oosun lẹ ri yẹn, koto d'Esu tobatiri o salu'gbo, t'ori koto bẹrẹ koto sa wọ Buka o, t'ọwọ Baba Dammy ba to aatijan n popo.
......
Sẹkẹrẹ o se f'Ọpa lu o o, sẹkẹrẹ o se f'ọpa lu yee ma fọn p'olemu , n'ibi t'Ọka n dana debi t'Ọmọ Eere n fọ awo, ̣la o kọ n'isẹju kan k'Ọsan o d'Orun, gbogbo ẹl'ẹnu ko t'ọwọ ọmọ'ẹ bọ Asọ ni, to r'Esu Ọdara n wa ohun tio jẹ o l'orita, eeruku ata ni mawulẹ f'oju kọ.
......
Igboho Maja Sunday mi, wọn ni Maja o ja mọ o rẹkẹ de wọn, Baba Damilọla d'ẹgẹrẹ min-ti, bo wo s'ile bo wo s'ita wahala ni, b'aja l'ogun ọdun l'aye o ogun aaj'aja, tor'ẹbiti ap'eku o t'iye-t'iye ni.....
........
Emi l'eyan Maja Sunday mi Igbooho, tan ba sọ pe Igboho de Ikoko o aj'Egun j'Ẹran Aakọni Ọmọ, Ọmọ abẹẹrẹ mẹtta o de aye, to n gun wọn l'Oju gun wọn l'Ẹnu pẹlu ọna Ọfun, t'ori were ita la se n ni t'ile jare, pakirakita ẹni ori yọ o od'ile, Ọkọ awọn were ajinigbe lo n bọ yẹn, Sanpọnna Oodua to yọ lokere tan m'eere🏃🏃🏃......
Osupa s'ebi emi naani, emi l'eyan Maja Sunday mi Igbooho, tan ba sọ pe Igboho de Ikoko o aj'Egun j'Ẹran Aakọni Ọmọ, Ọmọ abẹẹrẹ mẹtta o de aye, to n gun wọn l'Oju gun wọn l'Ẹnu pẹlu ọna Ọfun, t'ori were ita la se n ni t'ile jare, pakirakita ẹni ori yọ o od'ile, Ọkọ awọn were ajinigbe lo n bọ yẹn, Sanpọnna Oodua to yọ lokere tan m'eere🏃🏃🏃🏃.......
........
MAJASỌLA SUNDAY o o, MAJASỌLA SUNDAY ọkunrin laakọ, ọkunrin laada, ọmọ gbelura ọmọ ọjọ gbogbo Oogun n jẹ o, gbogbo Modakẹkẹ mo gbelura de Ifẹ o, Baba Sunday to mọ ewe mọ egbo to pọ gannnn, Adisa j'ogun oogun o dẹ tun n bẹ pẹlu Ọlọhun.....
MAJASỌLA SUNDAY o o, AADISA, MAJASỌLA SUNDAY ọkunrin laakọ, ọkunrin laada, ọmọ gbelura ọmọ ọjọ gbogbo Oogun n jẹ o, gbogbo Modakẹkẹ mo gbelura de Ifẹ o, Baba Sunday to mọ ewe mọ egbo to pọ gannnn, Adisa j'ogun oogun o dẹ tun n bẹ pẹlu Ọlọhun.
Still !