Orin Duru

Orin Duru This is a place where you get the reasons behind many of the church hymns

24/04/2025

1. Mo f’ emi mi sabe
Itoju Re Jesu;
‘Wo ko jo mi l’ ainireti,
‘Wo l’ Olorun Ife.

2. ‘Wo ni mo gbekele
‘Wo ni mo f’ara ti:
Rere at’ Ot**io ni O,
Eyi t’ O se l’ o to.

3. Ohun t’o wu k’o de,
Ife re ni nwon nse:
Mo f’ ori pamo saiya Re,
Nko foiya iji yi.

4. B’ ibi tab’ ire de,
Y’o dara fun mi sa!
Ki nsa ni O l’ ohun gbogbo,
Ohun gbogbo n’nu Re. Amin.

13/10/2024

1. Ojo nla l’ ojo ti mo yan
Olugbala l’ Olorun mi:
O ye ki okan mi ma yo,
K’o sir o ihin na ka ‘le.
Ojo nla l’ ojo na!
Ti Jesu we ese mi nu;
O ko mi ki mma gbadura,
Kim ma sora, ki nsi ma yo.
Ojo nla l’ ojo na!
Ti Jesu we ese mi nu.

2. Ise Igbala pari na,
Mo di t’ Oluwa mi loni;
On l’o pe mi ti mo si je,
Mo f’ ayo jipe mimo na.
Ojo nla, &c.

3. Eje mimo yi ni mo je
F’ Eniti’ o ye lati feran;
Je k’orin didun kun ‘le Re,
Nigba mo ba nlo sin nibe.
Ojo nla, &c.

4. Simi, aiduro okan mi,
Simi le Jesu Oluwa;
Tani je wipe aiye dun
Ju odo awon Angeli?
Ojo nla, &c

5. Enyin orun, gbo eje mi;
Eje mi ni ojojumo
Em’ o ma so dotun t**i
Iku y’o fi mu mi re ‘le.
Ojo nla, &c. Amin.

03/10/2024

Mo f’ iyin ailopin
Fun Olorun Baba,
Fun ore aiye mi,
At’ ireti t’ orun.
O ran Omo Re ayanfe,
Lati ku fun ese aiye

Celebrating my 9th year on Facebook. Thank you for your continuing support. I could never have made it without you. 🙏🤗🎉
01/10/2024

Celebrating my 9th year on Facebook. Thank you for your continuing support. I could never have made it without you. 🙏🤗🎉

A f’ope f’ Olorun, L’ okan ati ohun wa, Eni s’ ohun ’yanu, N’nu Enit’ araiye nyo; Gbat’ a wa l’om’ owo On na l’o ntoju w...
28/09/2024

A f’ope f’ Olorun,
L’ okan ati ohun wa,
Eni s’ ohun ’yanu,
N’nu Enit’ araiye nyo;
Gbat’ a wa l’om’ owo
On na l’o ntoju wa
O si nf’ ebun ife
Se ’toju wa sibe.

23/09/2024

Oluwa, pa wa mo l’ oni,
Fi apa Re so wa;
Kiki awon ti ’wo pamo,
L’ o nyo ninu ewu.

Address

Ayedade, Off Blind Centre, Ogbomoso/Iseyin Road
Ogbomoso

Telephone

+2347063046520

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Orin Duru posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Share

Category