Alaroye tuntun

Alaroye tuntun IWEEROYIN TO N ṢOJU ỌMỌ YORUBA NIBI GBOGBO

25/04/2024

Ọlawale Ajao, Ibadan Lẹyin ti wọn ti rọ Onifiditi tilu Fiditi loye, ija ṣẹṣẹ bẹrẹ lori ọrọ oba ilu naa gan-an ni bayii pẹlu bi ori ade ọhun, Ọba Oyelẹyẹ Sakirudeen, ṣe faake kọri, o ni

25/04/2024

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ Awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meje ni wọn ti wa nikaawọ ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo, lẹyin ti wọn fipa ba ọmọbinrin kan lo pọ, ti wọn si tun digun ja a lole niluu

25/04/2024

Adewale Adeoye Ẹsẹ ko gbero nile ẹjọ to n ri si lilo ọmọde ni ilokulo atawọn iwa ọdaran mi-in ‘Special Offences Court’, to wa ni Ikẹja, nipinlẹ Eko, nibi ti igbẹjọ ti waye lori Ọgbẹni Samsondeen Awoniyi tawọn tawọn agbefọba ipinlẹ Eko fẹsun

25/04/2024

Adewale Adeoye Bẹẹ ba ri awọn wọda kan ti wọn n lọ kaakiri igberiko nilu Eko, paapaa ju lọ, ti wọn ba n wo ọtun, ti won n wo osi ninu ọja Sabo, niluu Ikorodu, nijọba ibilẹ Ikorodu, nipinlẹ Eko, afurasi ọdaran kan, Ọgbẹni Abubarkar Isiaq, ẹni ọdun mẹtalelọgbọ...

25/04/2024

Adewale Adeoye Ni bayii, awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Bavarian, lorileede Germany, ti fi kele ofin gbe awọn ọmọ Naijiria mọkanla kan ti wọn n huwa ọdaran niluu naa. Ohun ti wọn ṣẹ ni pe wọn maa n lo ọrọ ifẹ lori ero ayelujara lati fi ṣe

25/04/2024

Adewale Adeoye Iwaju Onidaajọ Abilekọ Olagbẹgi tile-ẹjọ Majisireeti kan to wa lagbegbe Ita-Ẹlẹwa, niluu Ikorodu, nijọba ibilẹ Ikorodu, nipinlẹ Eko, ni wọn foju awọn marun-un kan ba. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe lọdun to kọja ni wọn lẹdi apo pọ laarin ara wọn...

24/04/2024

Florence Babaṣọla, Oṣogbo Awọn mọlẹbi Pasitọ Morris Ọlagbaju Fadehan, to jẹ oluṣọ ni ijọ Celestial Church of Christ, Grace of Comfort Parish, Omitótó, ni Ilode, niluu Ileefẹ, ẹni ti igbakeji rẹ, Lekan Ogundipẹ, gun pa, ti

24/04/2024

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin Abilekọ kan, Mariam Sọdaq, ti sọ fun Onidaajọ Yunusa Abdullahi, ti kootu ibilẹ kan to wa lagbegbe Akérébíata, niluu Ilọrin, pe ko tu oun ati ọkọ oun, Abdulmujeeb, ti oun bimọ mẹta fun

24/04/2024

Monisọla Saka Ijọba apapọ ti paṣẹ pe wọn ko gbọdọ gba akẹkọọ yoowu ti ko ba ti i pe ọdun mejidinlogun sileewe giga. Lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Tahir Mamman, ti i

24/04/2024

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti fi panpẹ ofin gbe afurasi kan, Abubakar Mahmud, ẹni ọdun marundinlogoji (35), to n gbe ni agbegbe Ọlọ́runsògo, niluu Ilọrin, fẹsun pe ṣe lo fọ ọlọpaa obinrin kan,

24/04/2024

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo eyan ilu Ijẹlu-Ekiti, nijọba ìbílẹ̀ Ọyẹ, nipinlẹ Ekiti, pẹlu bi ojo nla kan ṣe ṣi ile to to bii ọgbọn niluu naa. Bakan naa ni ilu odi keji, Omu-Ekiti, ko

24/04/2024

Ọlawale Ajao, Ibadan Ẹni a ni ko waa wo gọ̀bì, tó ní kí rèé gọ́bigọ̀bi. Eeyan bomi lámù, o loun ri eégun, ki waa ni ki ẹni to pọnmi sibẹ o ri. Owe wọnyi lo lọ

24/04/2024

Monisọla Saka Ajọ to n gbogun ti ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku lorilẹ-ede wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ti nawọ gan Hadi Sirika, ti i ṣe minisita feto irinna oju ofurufu labẹ iṣejọba

24/04/2024

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin Lẹyin ti baale ile kan, Shuaibu Ọba, tu gbogbo aṣiri iwa buruku ọwọ iyawo ẹ, Afusat Garuba, niwaju ọkẹ aimọye eeyan ni kootu ibilẹ kan to wa laduugbo Akérébíata, niluu Ilọrin, nitori ki

24/04/2024

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin Akolo ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ni ọkunrin kan, Sunday Gbemis, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, to n gbe ni agbegbe Amọ́yọ̀, niluu Ilọrin, to n ṣiṣẹ fọniṣọ, ṣugbọn tọwọ tẹ pe o n pe ara

23/04/2024

Florence Babaṣọla, Oṣogbo Aya aarẹ orileede yii, Arabinrin Olurẹmi Tinubu, ti sọ pe itara ti oun ni si ọrọ awọn obinrin ati ọrọ ẹkọ to peye fun awọn ọdọbinrin lo fa a ti oun fi ṣedasilẹ

23/04/2024

Florence Babaṣọla, Oṣogbo Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti ṣapejuwe aya aarẹ orileede yii, Sẹnetọ Rẹmi Tinubu, gẹgẹ bii ẹni to ko gbogbo eeyan mọra, ti ki i si i ṣe ẹlẹyamẹya. Lasiko ti Rẹmi Tinubu

23/04/2024

Florence Babaṣọla, Oṣogbo Pẹlu bi ọpọ awọn ọdọ orileede yii ṣe n fi ẹmi ara wọn wewu lojoojumọ latari owo ojiji ti wọn n wa, agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe, Traditional Religion Worshipers Association (TRWASO) ti sọ

23/04/2024

Monisọla Saka Asiko yii ki i ṣe eyi to dara rara fun ọkan ni awọn gbajumọ arẹwa oṣerebinrin ilẹ wa nni, Fathia Balogun. Eyi ko ṣẹyin bi ọmọbinrin naa ṣe padanu baba to bi i lọmọ

23/04/2024

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti tẹ ọkunrin ẹni aadọta ọdun kan, Ọgbẹni Jamiyu Adewọle, pẹlu ẹsun pe omi inu kanga kan to wa ninu ọgba ibi to ti n ṣe piọ wọta

23/04/2024

Monisọla Saka Ijọba ipinlẹ Eko ti ni gbogbo arufin ojupopo ti ọwọ ba ti tẹ lati isinyii lọ, paapaa ju lọ, awọn to n wa ọkọ ni opopo ti ki i ṣe ti wọn, ti wọn

23/04/2024

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin Wọn ni ohun ti a o ba fẹ ko bajẹ, oju ni a a mu to o. Eyi lo fa a ti ijọba ipinlẹ Kwara, ṣe lọọ ko gbogbo awọn ẹran maaluu ti

23/04/2024

Faith Adebọla Minisita fun eto iṣuna-owo nilẹ wa, Ọgbẹni Wale Ẹdun, ni gbogbo eto ti pari, ajọsọ ati adehun si ti fori mẹyin laarin orileede Naijiria ati Banki Agbaye, lati ya owo ti iye rẹ jẹ

23/04/2024

Faith Adebọla Bi ilẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ṣe n mọ, Olori orileede wa, Bọla Ahmed Tinubu, yoo ti palẹ ẹru rẹ mọ, ti yoo si tẹkọ leti lọ sorileede

23/04/2024

Faith Adebọla Ọrọ kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara bayii ni bi gbajugbaja ọkunrin alafẹ to n mura bii obinrin nni, Idris Ọlanrewaju Okunẹyẹ, tawọn eeyan mọ si Bobrisky, ṣe fi awọn aga onike

22/04/2024

Faith Adebọla Ọkọ akẹru gbọgbọrọ kan ti ko mọlẹbi baale ile kan to doloogbe sinu ọfọ ati ibanujẹ laaarọ kutu ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, latari bi ọkọ ọhun ṣe lọọ

22/04/2024

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin Ṣe ni ibẹrubojo gbilẹ niluu Ilọrin ati gbogbo agbegbe rẹ lati ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, latari bi iroyin ṣe gba igboro pe awọn alapata kan n ta

22/04/2024

Adewale Adeoye Baba agbalagba kan, Oloogbe Mallam Danjuma, ẹni ọgọta ọdun tawọn eeyan mọ si Black nigba aye rẹ, ọmọ rẹ, Oloogbe Ibrahim, ẹni ọdun marundinlogoji, ati ọrẹ ọmọ rẹ, Oloogbe Aminu, ẹni ọdun marundinlogoji, ni

22/04/2024

Adewale Adeoye Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ bi Insipẹkitọ Taofeek, to jẹ ọlọpaa lagbegbe Ajah, nipinlẹ Eko, ṣe fọbẹ gun araalu kan, Oloogbe Anosikwe Patrick, pa lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii. ALAROYE g...

Address

15, LOVE-ALL Street, IKOSI/KETU
Lagos

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Alaroye tuntun posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to Alaroye tuntun:

Share


Other Lagos media companies

Show All