Eko News.Com

Eko News.Com It Is An Independent Media Platform, Crashing Information Barrier, Rooted In Lagos State, Nigeria.
(1)

"ÌNIRA YÓÒ DÓPIN LÁÌPẸ́" - ÌJỌBA ÀPAPỌ̀[Fábùnmi] Mínísítà fétò ìròyìn àti ìtanijí, Mohammed Idris ló sọ èyí lọ́jọ́bọ̀, ọ...
01/03/2024

"ÌNIRA YÓÒ DÓPIN LÁÌPẸ́" - ÌJỌBA ÀPAPỌ̀

[Fábùnmi]

Mínísítà fétò ìròyìn àti ìtanijí, Mohammed Idris ló sọ èyí lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì pé ebi tí ń pa ará ìlú yóò di ohun ìgbàgbé kó tó di ọdún tó ń bọ̀.

Idris ni ó sọ èyí nígbà tó ń kópa níbi ayẹyẹ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àádọ́ta ọdún tí ìwé ìròyìn ojojojúmọ́ Punch Nàìjíríà ṣe ní Civic Centre, Victoria Island, Ìpínlẹ̀ Èkó.

Mínísítà ni ó ṣojú Ààrẹ Tinubu níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Soyinka ṣe, níbẹ̀ ni ó ti fi dá àwọn ọmọ ilẹ̀ yìí lójú pé Tinubu yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣe, tí ó sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n ṣe sùúrù.

ẸGBẸ́ ÒṢÌṢẸ́ ṢE ÌWỌ́DE NÍ ÌLÚ ÈKÓ LÓNÌÍ ỌJỌ́ ÌṢẸ́GUN🙏🏽
27/02/2024

ẸGBẸ́ ÒṢÌṢẸ́ ṢE ÌWỌ́DE NÍ ÌLÚ ÈKÓ LÓNÌÍ ỌJỌ́ ÌṢẸ́GUN🙏🏽

26/02/2024

ÌRÒYÌN ÀWÒKO 🇳🇬🕊️ ỌJỌ́ KẸRINDINLỌGBỌN, OṢÙ ÌKEJÌ, ỌDÚN 2024.

Ìpínlẹ̀ Ondo sin òkú Gómìnà Rótìmí Akérédolú pẹ̀lú ọlá ìkẹyìn ní ìlú Ọ̀wọ̀.

Ààrẹ Tinubu àti àwọn Aláṣẹ ìlú dágbére ìkẹyìn fún Olóògbé Gómìnà Rotimi Akérédolú tí Ìpínlẹ̀ Òǹdó.

Ìpínlẹ̀ Gombe fọwọ́ sí Bílíọ́nu márùn lé díẹ̀ náìrà fún sísan owó àwọn òṣìṣẹ̀ fẹ̀yìntì.

Ààrẹ Tínubu yan Arábìnrin Kẹ́mi Nanna Nandap gẹ́gẹ́ bí Alákóso àgbà fún Ilé-iṣẹ́ ìwé ìrìn-àjò Nàìjíríà.

Ààrẹ Tinubu pé fún fífòpin sí àwọn ìjìyà tí wọ́n fi de orílẹ̀-èdè Guinea, Mali, Niger àti orílẹ̀-èdè Burkina Faso.

Ààrẹ Tínubu ṣe ìlérí láti tẹ̀ síwájú nínú àwọn ètò àtúntò ìlú láìwo àwọn Ìpèníjà tí wọ́n ń kojú.

Ìjọba Àpapọ̀ kìlọ̀ fún Amòfin Fálànà àti ẹgbẹ́ Ayédáadé òṣìṣẹ̀ lórí ìwọ́de gbogboogbò tí wọ́n fẹ́ ṣe.

Gómìnà Sanwo-Olu ṣe ìlérí pé, ọkọ̀ ojú-irin Red Line yóò bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́ ní Ọjọ́Bọ ọ̀sẹ̀ yìí.

Ààrẹ Ẹgbẹ́ Amòfin Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NBA jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bí oludije Gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ní Ìpínlẹ̀ Edo.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìjọba fọwọ́ ṣìnkún òfin mú Alága ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Abure.

Ilé Ìfowópamọ́ àgbà yóò ṣe àtúnṣe sí owó náìrà tí kò níye lórí mọ́ ní ọjà pàṣípààrọ̀ owó lágbàáyé - Cardoso.

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dá iná mọ̀nàmọ̀nà padà sí orílẹ̀-èdè Niger.

Ilé-iṣẹ́ Ẹ̀ṣọ́ Aṣọ́bodè àti ilé-iṣẹ́ ológun orí omi yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ láti gbógun ti ìwà fàyàwọ́.

Gómìnà Oyèbánjí sọ fún àwọn olórí ìjọba ìbílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì pé, wíwà sí ìpàdé Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ Ààbò ìlú ṣe pàtàkì.

Olórí Àjọ EFCC rọ àwọn Olùdarí Ilé ìfowópamọ́ láti máa tẹ̀lé ìlànà òfin nínú ìṣẹ́ wọn.

Àwọn ọlọ́pàá fọwọ́ ṣìnkún òfin àwọn ayédèrú ọmọ Ogun mẹ́rin ní Ìpínlẹ̀ Èkó, tí wọ́n sì gba àwọn nǹkan ìjà ogun lọ́wọ́ wọn.

Ìgbákejì Ààrẹ, kashim Shettima yóò ṣí ẹ̀rọ amúnáwá Apá Ìlà Òòrùn Gúúsù fún ìpèsè ìná mọ̀nàmọ̀nà fún àwọn ilé-iṣẹ́ déédéé lónìí Ọjọ́ Ajé.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Abia gba ìṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n gbà àwọn ohun ìní ilé-iṣẹ́ Aṣọ híhun tí Ìpínlẹ̀ náà.

Àrùn onígbá méjì pa ọ̀pọ̀ ènìyàn ní orílẹ̀-èdè Zambia

Ajé á wá wa wá

ÀWỌN OLÓGUN ṢE IKÚ PA BODERI, ÒGBÓǸTARÌGÌ AJÍNIGBÉ TÓ Ń DA AGBÈGBÈ KADUNA LÁÀMÚ|Àlàbí Ẹ̀ṣọ́|Tìdùnnú-tìdùnnú ni ìjọba ìpí...
24/02/2024

ÀWỌN OLÓGUN ṢE IKÚ PA BODERI, ÒGBÓǸTARÌGÌ AJÍNIGBÉ TÓ Ń DA AGBÈGBÈ KADUNA LÁÀMÚ
|Àlàbí Ẹ̀ṣọ́|

Tìdùnnú-tìdùnnú ni ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna fi kéde ikú ìgárá ajínigbé, tó ń yọ Kaduna lẹnu àti gbogbo àgbègbè ẹ.

Olobo táwọn èèyàn ta ìjọba ni eto ti gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀hún Sinetọ Uba Sanni ṣagbekalẹ rẹ láti gbógun ti àwọn apanilẹkun jaye yìí ṣe ṣe aṣeyege.

Lọ́jọ́ Ọjọ́rú tó kọjá ní ọ̀daràn yìí, Boderi Isyaku àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ lo koju àwọn ọmọ ogún orílẹ̀ èdè yìí tí wọn wá láti agbegbe Bada/Riyawa ti àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Chikun àti Igabi.

Ìjà ìbọn àti nnkan oloro mìíràn yìí ló ṣekú pa Boderi àtàwọn ẹmẹ̀wà mi tó bógún rìn.

Ọgagun V.U. Okoro to jẹ adarí Division 1, tí ọmọ ogun orílẹ̀ èdè yìí (àti Force Commander, operation Whirl Punch) lo ṣigun àjàyè yìí látàrí ipalemọ to péye àti ifimufinlẹ.

Lára àwọn idaluru tí Boderi ti ṣe niwọnyi: jiji àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ile-iwe Federal College of Forestry Mechansation mọkanginlogoji gbe lọ́jọ́ kọkànlá oṣù kẹta, lọ́dúnun 2021.

Àwọn ohun ìjà oloro, ìbọn AK47, rédíò ikansiraẹni, alupupu bíi marun-un ni wọ́n ko ni ibùba àwọn akúmádijú yìí.

Lọ́jọ́ kẹrinlelogun, oṣù kẹjọ ọdún 2021 bákan-náà lotun ya lu Nigerian Defence Academy ti Afaka ni Igabi ti wọn si pá ji ọmọ ologun meji ti wọn jì àwọn kan gbe lọ.

OSIMHEN GBA ÀMÌ Ẹ̀YẸ AGBÁBỌ́Ọ̀LÙ TÓ DÁRA JÙ  NÍGBA TÍ NAPOLI KOJÚ BARCELONA NI UCL| Napoli 1-1 Barcelona |
22/02/2024

OSIMHEN GBA ÀMÌ Ẹ̀YẸ AGBÁBỌ́Ọ̀LÙ TÓ DÁRA JÙ NÍGBA TÍ NAPOLI KOJÚ BARCELONA NI UCL
| Napoli 1-1 Barcelona |

ỌBA FI OYÈ TUNTUN DÁ NWABALI LỌ́LÁ. Ọba ìlú tí aṣọle ikọ̀ Super Eagles Stanley Nwabali fi òye tuntun dáa lọla.Ọba Nzeobi...
22/02/2024

ỌBA FI OYÈ TUNTUN DÁ NWABALI LỌ́LÁ.

Ọba ìlú tí aṣọle ikọ̀ Super Eagles Stanley Nwabali fi òye tuntun dáa lọla.

Ọba Nzeobi Amida tí agbegbe Egbema ni ìpínlẹ̀ Rivers fi Nwabali jẹ òye Ugo Egbema tí ó tunmọ si ògo ìlú Egbema, ọba náà sọpe bí agbaboolu náà ṣe ṣe dáadáa mú ògo bá agbegbe Egbema, ìpínlẹ̀ Rivers àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lapapọ.

"KÌNÌÚN PA OLÓWÓ RẸ NÍGBÀ TÓ FẸ́ DÓÒLÀ Ẹ̀MÍ OBÌNRIN KAN LỌ́WỌ́ RẸ̀" - ALÁGA ẸGBẸ́ NASU[Fábùnmi]Àwọn alákòóso ilé ìwé Gí...
21/02/2024

"KÌNÌÚN PA OLÓWÓ RẸ NÍGBÀ TÓ FẸ́ DÓÒLÀ Ẹ̀MÍ OBÌNRIN KAN LỌ́WỌ́ RẸ̀" - ALÁGA ẸGBẸ́ NASU

[Fábùnmi]

Àwọn alákòóso ilé ìwé Gíga Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ifẹ̀, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tí gbé àgádágodo sí ẹnu ìloro ibi tí wọ́n ṣe àwọn ẹranko lọ́jọ̀ sí fún àwọn ènìyàn láti wá máa wò, lórí ikú tó pa òṣìṣẹ́ ibẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Olabode Olawuyi, láti ọwọ́ Kìnìún tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju ọdún mẹ́sàn-án lọ ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kejì, ọdún 2024.

Nígbà tí Alága àwọn Òṣìṣẹ́ tí kìí ṣe ti Àwọn Olùkọ́ ti Ilé-ìwé gíga ẹ̀ka ti OAU, Ọ̀gbẹ́ni Wọlé Odewumi, bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ àìkú, ogúnjọ́, oṣù kejì, ọdún 2024 pé àwọn alákòóso Ilé-ìwé náà ti gbé ọgbà àwọn ẹranko náà tì pa.

Tó sì tún tẹ̀síwájú nínú àlàyé rẹ̀ pé Kìnìún ni ó gba ẹ̀mí ọkùnrin tó ń rí sí ètò ìlera àwọn ẹranko ọ̀hún nígbà tí ọkùnrin náà fẹ́ dóòlà obìnrin tí ó kọ́kọ́ bọ́ há sí ọwọ́ Kìnìún náà.

ỌWỌ́ ỌLỌ́PÀÁ TI TẸ ṢẸ́Ẹ̀FÙ TÓ JÍ ỌMỌ Ọ̀GÁ RẸ̀ GBÉ SÁLỌ[Fábùnmi]Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìlú Abuja ti fi páńpẹ́ òfin gbé ọkùnrin ...
19/02/2024

ỌWỌ́ ỌLỌ́PÀÁ TI TẸ ṢẸ́Ẹ̀FÙ TÓ JÍ ỌMỌ Ọ̀GÁ RẸ̀ GBÉ SÁLỌ

[Fábùnmi]

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìlú Abuja ti fi páńpẹ́ òfin gbé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ulagu Chukwuma fún jíjí ọmọ ọ̀gá rẹ̀ ọkùnrin ẹni ọdún méjìlá gbé ní ọjọ́ kejìláá, oṣù kejì, ọdún 2024 ní Jabi, ìlú Abuja.

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti Olú ìlú wa Abuja ti kéde fífi páńpẹ́ òfin gbé ọ̀kan lára àwọn adarí ajínigbé tí wọ́n sì fi wọ́n hàn ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kejì, ọdún 2024, tí orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Saidu Abdulkadir, tí gbogbo ayé mọ̀ sí Dahiru Ádámù pẹ̀lú afunrasí mìíràn tí ọwọ́ tún tẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ tí Alukoro fún ilé ìṣe ọlọ́pàá ti Olú ìlú wa Abuja SP Josephine Adeh fi síta lọ́jọ́ àìkú, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kejì, ọdún 2024, pé afunrasí ọ̀hún ni ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé kan tí ó ń dáná fún ìdílé Nwakwo tí ọwọ́ sì tẹ̀ ẹ́ láti ọ̀dọ̀ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ẹkùn ti Utako.

15/02/2024

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ TÍ ÀÀRẸ BỌ́LÁ AHMED TINUBU BÁ ÀWỌN GÓMÌNÀ SỌ NÍBI ÌPÀDÉ LÓNÌÍ. ỌJỌ́ KẸẸDOGUN OṢÙ KEJÌ ỌDÚN 2024.

💥ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ YÓÒ GBA ÀWỌN ÈNÌYÀN SẸ́NU IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ SII.

💥ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ YÓÒ RAN ÀWỌN GÓMÌNÀ LỌ́WỌ́, LÓRÍ ÌDÁSÍLẸ̀ ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀.

💥KÍ ÀWỌN GÓMÌNÀ ṢE ÈTÒ ÀÀBÒ ÀWỌN IGBÓ ÌPÍNLẸ̀ WỌN.

💥ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ÀTI ÌPÍNLẸ̀ YÓÒ FỌWỌ́SOWỌ́PỌ̀ LÁTI PÈSÈ OÚNJẸ LỌ́PỌ̀ YANTURU.

💥ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ KÒNÍ KÓ OÚNJẸ WỌLÉ LÁTI ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ.

💥KÍ ÀWỌN GÓMÌNÀ GBÓGUN TÍ ÀWỌN ỌLỌ́JÀ TÍ WỌ́N Ń KÓ ỌJÀ PAMỌ́.

💥ÀÀRẸ RỌ ÀWỌN GÓMÌNÀ KÍ WỌN MÓJÚTÓ ÈTÒ Ọ̀SÌN ADÌYẸ ÀTI ẸJA.

💥ÀÀRẸ BẸ ÀWỌN GÓMÌNÀ KÍ WỌN TÈTÈ SAN OWÓ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ ÀTI ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ FẸ̀HÌNTÌ.

💥ÀÀRẸ BẸ ÀWỌN GÓMÌNÀ KÍ WỌN PÈSÈ IṢẸ́ FÚN ÀWỌN Ọ̀DỌ́ NÍ ÌPÍNLẸ̀ WỌN.

"Ó SÀN KÍ N BÍMỌ SÓJÚ KAN, NI MO ṢE PADÀ SỌ́DỌ̀ ỌKỌ MI", WUNMI TORIỌLA|Ogidiolu|Òṣèré, gbajúmọ̀ orí ìtàgé àti fíìmù àgbé...
14/02/2024

"Ó SÀN KÍ N BÍMỌ SÓJÚ KAN, NI MO ṢE PADÀ SỌ́DỌ̀ ỌKỌ MI", WUNMI TORIỌLA
|Ogidiolu|

Òṣèré, gbajúmọ̀ orí ìtàgé àti fíìmù àgbéléwò Wunmi Toriọla tó ṣe ìgbéyàwó lọ́dún un 2018, sọ ọ́ di mímọ̀ pé ìgbéyàwó òun tó túká lórí ìjà pé ọkọ òun ń fi ojú òkìkí òun gbolẹ̀.

Wunmi sọ pé àwọn méjéèjì náà ni wọn jìjọ́ ń tọ́ ọmọ kan ṣoṣo tí wọ́n bí, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Zion, tí àwọn méjéèjì sì ń ṣe ojúṣe náà dáadáa.

Ó tún sọ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà pé òun ó sàn àti pé ó wu òun láti tún wọ ọkọ̀ ìfẹ́ pẹ̀lú ẹlòmìíràn torí òun ní ìgbàgbọ́ nínú irú èrò báyìí.

Àmọ́ òun dá irú èrò yìí dúró pátápátá ni pé, ó wu òun kí ọkọ òun àtijọ́ kí ó jẹ́ bàbá àwọn ọmọ tí òun máa bí ní ọjọ́ iwájú.

ẸJỌ́ ti kú s'Áké. Ẹyin olólùfẹ́ wa, ẹ máa yáṣẹ́.
Ẹ̀yin ìyàwó ó ní mọ ẹni o.
Torí bàbá kan náà ni ó bí àwọn ọmọ rẹ̀, yóò lè rọrùn fún àwọn òbí méjéèjì láti lè jìjọ tọ́ àwọn ọmọ náà láì ṣe ìgbéyàwó ìbílẹ̀.

13/02/2024

ÀÀRẸ BỌ́LÁ AHMED TINUBU FI ÀMÌ Ẹ̀YẸ MON DÁ ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ AGBÁBỌ́Ọ́LÙ SUPER EAGLES LỌ́LÁ NÍLÙÚ ABUJA.

ÀWỌN ÀKÙDÉ TÓ JÁ ẸYẸ NÀÌJÍRÍÀ BỌ́|Ògídíolú|Wọn ò ta ìwé àmì ìwọlé tíkẹ́ẹ̀tì fún àwọn ọmọ Nàìjíríà. Àwọn ọmọ Nàìjíríà kan...
13/02/2024

ÀWỌN ÀKÙDÉ TÓ JÁ ẸYẸ NÀÌJÍRÍÀ BỌ́
|Ògídíolú|

Wọn ò ta ìwé àmì ìwọlé tíkẹ́ẹ̀tì fún àwọn ọmọ Nàìjíríà. Àwọn ọmọ Nàìjíríà kan tilẹ̀ ra ìwé ìwọlé, tíkẹ́ẹ̀tì wọn ní ọgọ́rùn-ún Dọ́là (Dollar), tí kò tó Dọ́là márùn-ún

Cote D'Ivoire kó gbogbo tíkẹ́ẹ̀tì náà pamọ́ sábẹ́, tí àjọ NFF ò sì gbìyànjú láti ṣe ètò bí yóò ṣe wà fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Kódà ìta pápá náà ni àwọn ẹgbẹ́ alátìlẹ́yìn Super Eagles wà pẹ̀lú ìlù àti àwọn fèèrè wọn.
Àìmọye àwọn olólùfẹ́ tí wọ́n wà ní ìta, tí wọn ò ráyè wọlé sinú pápá náà.

Nnkan bíi 57,904 ni ènìyàn ló wà nínú pápá ìgbá bọ́ọ̀lù náà, tí àwọn alátìlẹ́yìn fún ikọ̀ ti Nàìjíríà tó wà níbẹ̀ kò tayọ 94.

Ọ̀nà kan náà nìyẹn láti mú ìpòrúùrù bá ọkàn àwọn agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Super Eagles.
Ọ̀bẹ ti gé ọmọ lọ́wọ́ a sọ ọ̀bẹ nù. Mo lérò wí pé a ti kọ́ ẹ̀kọ́ látara èyí.

"SỌ FÚN ỌKỌ RẸ PÉ ÌYÁ Ń JẸ ÀWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ", -EMIR ÌLÚ KANO|Ògídíolú|Lánàá ọjọ́ Kejìlá, oṣù kejì ọdún 2024 ni Emir ti ...
13/02/2024

"SỌ FÚN ỌKỌ RẸ PÉ ÌYÁ Ń JẸ ÀWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ", -EMIR ÌLÚ KANO
|Ògídíolú|

Lánàá ọjọ́ Kejìlá, oṣù kejì ọdún 2024 ni Emir ti ìlú Kano, ìyẹn Aminu Ado Bayero rọ obìnrin àkọ́kọ́ ìyẹn Sẹ́nétọ̀ Olúrẹ̀mí Tinubu pé kí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ ìyẹn Ààrẹ Bọ́lá Tinubu pé ìyà ń jẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà látara bí ètò ọrọ̀ ajé orílè-èdè Nàìjíríà ṣe dórí kodò.
Ìgbà tí orí adé náà gba Sẹ́nétọ̀ náà ní àlejò ní ààfin rẹ̀ nígbà tí ó fẹ́ lọ ṣe ìfilọ́lẹ̀ ilé kan tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ kọ́, tí wọ́n sì tún fi sọrí rẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Òfinn.

Nínú ilé ìwé gíga ti Maryam Abacha, American University ti Nàìjíríà (MAAUN), ni orí adé NÁÀ ti fi ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sì Tinubu.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjogún bá ni àwọn ìṣòro náà jẹ́, àmọ́ Báyẹ́ró rọ ààrẹ Tinubu pé kí wọ́n tún bọ̀ sa gbogbo agbára wọn láti lè jẹ́ kí ìrọ̀rùn dé bá ètò ọrọ̀ ajé àti láti lè kojú ọ̀rọ̀ àìtó ètò àbò tí ó wà ní orílè èdè náà.

ÀÀRẸ TINUBU FÚN ÀWỌN AGBÁBỌ́Ọ̀LÙ SUPER EAGLES NI ÀMÌ Ẹ̀YẸ, ILẸ́ ÀTI ILÉ
13/02/2024

ÀÀRẸ TINUBU FÚN ÀWỌN AGBÁBỌ́Ọ̀LÙ SUPER EAGLES NI ÀMÌ Ẹ̀YẸ, ILẸ́ ÀTI ILÉ

13/02/2024

"SỌ FÚN ỌKỌ RẸ PÉ ÌYÀ Ń JẸ ÀWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ" - ADO BAYERO

[Fábùnmi]

Emir ìlú Kano, Aminu Ado Bayero ni ó sọ èyí ní àná ọjọ́ kejìlá, oṣù kejì, ọdún 2024, fún aya Ààrẹ, Sínétọ̀ Oluremi and Tinubu pé kí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ Ààrẹ Bọ́lá Tinubu pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ń jẹ̀yà nítorí ọrọ̀-ajé tó di agẹgẹ ní orílẹ̀ èdè yìí.

Ọba alayé yìí ni ó fi ọ̀rọ̀ yìí síta nígbà tó ń tẹ́wọ́ gba Sínétọ̀ Tinubu sí ààfin rẹ̀ ní ìlú Kano ní àná òde yìí.

Bayero ni ó sọ báyìí pé: "Lóòótọ́, a ní àwọn ọ̀nà mìíràn tí a le gbà bá ìjọba sọ̀rọ̀ lórí ohun tí à ń wá, ṣùgbọ́n ìwọ ni ó tọ́ sí jùlọ láti bá wa sọ fún Ààrẹ nípa ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè yìí.

À ń gbọ́ ìròyìn lójoojúmọ́ bí gbogbo nǹkan ṣe wọ́n tí ìyà sì ń jẹ àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti orí ìjọba tó wà lóde yìí. A mọ̀ wí pé ìjọba ń gbìyànjú ṣùgbọ́n kí ó túbọ̀ kára mọ́ ìgbìyànjú rẹ̀ láti lè mú ìdẹ̀rùn dé bá ìyà tí àwọn ènìyàn ń dojú kọ... "

ÀWỌN AGBÉBỌN JÍ ÀWỌN  ÈRÒ ỌKỌ̀ GBÉ NÍ OǸDÓ[Fábùnmi]Àwọn agbébọn yìnbọn pa awakọ̀ èrò bọ́ọ̀sì tí wọ́n sì jí àwọn èrò inú ...
12/02/2024

ÀWỌN AGBÉBỌN JÍ ÀWỌN ÈRÒ ỌKỌ̀ GBÉ NÍ OǸDÓ

[Fábùnmi]

Àwọn agbébọn yìnbọn pa awakọ̀ èrò bọ́ọ̀sì tí wọ́n sì jí àwọn èrò inú ọkọ̀ náà gbé sá lọ ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí tí ń ṣe ọjọ́ ẹtì, ní ìlú Akunu, ní ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Àkúrẹ́ ìpínlẹ̀ Oǹdó.

Ìròyìn tí a gbọ́ ni wí pé àwọn agbébọn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ibi ní ọjọ́ àìkú ni wọ́n fi ọmọdé bìnrin léńjeléńje kan sílẹ̀ lọ.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ṣe ojú rẹ̀ ni wọ́n ṣe àlàyé pé àwọn ajínigbé ọ̀hún ni wọ́n dáná ìbọn yá awakọ̀ bọ́ọ̀sì náà nígbà tí ó fẹ́ bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́, tí ọkọ̀ bọ́ọ̀sì náà sì fi tipátipá dúró.

Báyìí ni wọ́n ṣe kó ikọ̀ aláàbò Amotekun, Àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́dẹ àti àwọn agbófinró sí inú igbó láti dóòlà ẹ̀mí àwọn tí wọ́n jí gbé náà.

11/02/2024

ẸYẸ NÀÌJÍRÍÀ KÒ GBÉRA😢 INÁ DILẸ̀ LẸ́YÌN ASUNṢUJẸ🤔
COTE D'VOIR TI GBÉFE LỌ🏆

ÌRÒYÌN ÀWÒKO ỌJỌ́ ÀBÁMẸ́TA, ỌJỌ́ KẸWÀÁ OṢÙ KEJÌ ỌDÚN 2024 Ààrẹ Tinubu ṣe ìfilọ́lẹ̀ kíkọ́ ilé gbígbé olójúlé ẹgbẹ̀rún mẹ́...
10/02/2024

ÌRÒYÌN ÀWÒKO ỌJỌ́ ÀBÁMẸ́TA, ỌJỌ́ KẸWÀÁ OṢÙ KEJÌ ỌDÚN 2024

Ààrẹ Tinubu ṣe ìfilọ́lẹ̀ kíkọ́ ilé gbígbé olójúlé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta lé ọgọ́rùn-ún kan àti díẹ̀ ní ìlú Abuja.

Ààrẹ Tinubu pàṣẹ kíkó àwọn oúnjẹ yẹ̀fun òní metric tọ́ọ̀nù ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún jáde fún jíjẹ àwọn ará ìlú.

Ààrẹ Tínubu ṣe ìlérí fífi òpin sí Ìpèníjà ọ̀rọ̀ ààbò ní orílẹ̀-èdè yìí, bí ilé-iṣẹ́ ológun òfuurufú ṣé ṣí àwọn ọkọ̀ òfuurufú agbérapá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rà

Ilé-ẹjọ́ pàsẹ fún Ìjọba Àpapọ̀ láti ṣàtúnṣe sí owó ọjà láàrin ọ̀sẹ̀ kan.

Àwọn àgbà ẹgbẹ́ òṣèlú APC kìlọ̀ fún Ààrẹ Tinubu láti má ṣe kọtí ikún sí ọ̀rọ̀ ìwọ́de Àpapọ̀, pé ó léwu.

Àjọ EFCC gbé Ikọ̀ àkànṣe kan kalẹ̀ nítorí níná owó dọ́là láàárín ìlú àti ṣíṣe owó náìrà oníṣekúṣe.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Anambra kọlu ibi tí wọ́n ti ń bímọ nítorí òwò, wọ́n gba àwọn ọ̀dọ́ langba mẹ́fà tó wà nínú oyún sílẹ̀.

Ṣe àtúnṣe sí ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ kí ìyà ará ìlú lè dínkù - Ọba Alayé rọ Ìjọba Àpapọ̀

Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní Ìpínlẹ̀ Ògùn dárò Olóògbé Ọ̀gbẹ́ni Sabitu, àgbà ẹgbẹ́ òṣèlú náà tó jáde láyé.

Wọ́n fi ojú Ọ̀gbẹ́ni Ladi Adétubú ba Ilé-ẹjọ́ látàrí ẹ̀sùn gbígbé owó rìn lọ́nà àìtọ́.

Dẹ́rẹ́bà ọkọ̀ kan ṣubú sínú mọto ní ìlú Ìbàdàn, ó sì kú.

Ọwọ́ Ọlọ́pàá ba arákùnrin kan tí ó gé orí Ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Bauchi.

Àwọn adigunjalè ṣe àwọn ọmọ Ogun apẹ̀tùsááwọ̀ ni ṣuta.

Ìjàmbá ìbúgbàmù àgbá afẹ́fẹ́ gáàsì pa ènìyàn kan, àwọn mẹ́ta mìíràn fara pa ní Ìpínlẹ̀ Èkó.

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà pàṣẹ fún Ọ̀gbẹ́ni Ẹdun láti ṣàlàyé láàrin ọjọ́ méje bí wọ́n ṣe ná ọgọ́rùn-ún Bílíọ́nu náìrà tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ àkànṣe ìpèsè afẹ́fẹ́ gáàsì.

Iṣẹ́ àtúnṣe afárá 'Third main land' ní ìlú Èkó yóò parí nínú oṣù kẹrin ọdún - Ìjọba Àpapọ̀.

Àwọn ilé-iṣẹ́ tó ń pèsè ọtí líle inú ọ̀rá kéékèèké pinnu láti pe ìjọba lẹ́jọ́ lórí bí wọ́n ṣe fòfin dé títa àwọn ọtí náà.

Ètò Ìkànìyàn yóò wáyé nínú ọdún 2024 gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣètò rẹ̀ - Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ṣe ìlérí fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún Arábìnrin kan tó pa aṣaralóge kan ní Ìpínlẹ̀ Ẹnugu.

Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC ṣe kìlọ̀ kìlọ̀ bí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Kano ṣe gba ìwé láti tú Ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba Ìpínlẹ̀ náà ká.

Jìbìtì Bílíọ́nu lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin lé mẹ́rìnléláàdọ́ta náìrà: Ilé-ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Alákóso àgbà Àjọ NIMASA tẹ́lẹ̀ sí ọjọ́ kẹtadínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún yìí.

Àjọ EFCC fọwọ́ ṣìnkún òfin mú àwọn afurasí mọ́kànlélógójì pẹ̀lú ọkọ̀ ńlá méjìlá nítorí iṣẹ́ ìwakùsà lọ́nà àìtọ́

**ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá gbégi dína ìkọlù ìmúninígbèkùn àwọn adigunjalè ní ìlú Abuja.

Ìnilára àtúbọ̀tán yíyọ owó Ìrànwọ́ epo rọ̀bì: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ̀ NLC àti TUC kéde bíbẹ̀rẹ̀ ìyànṣẹ́lódì lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rìnlá.

Àwọn ènìyàn mẹ́fà kú níbi ìjà àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn.

Ààrẹ Tinubu páṣẹ kíka ìlérí orílẹ̀-èdè ní kété tí wọ́n bá parí orin ìdámọ̀ orílẹ̀ - èdè Nàìjíríà

Wọ́n sọ eré àgbéléwò 'Ti Olúwa nílẹ̀' di eré orí ìtàgé.

Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles yóò wàákò pẹ̀lú Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Ivory Coast ní ipile tó gbẹ̀yìn nínú ìdíje Ife ẹ̀yẹ ilẹ́ Áfíríkà, AFCON lọ́jọ́ Àìkú.

ALÀGBÀ OLOWOFẸLA, ẸNI ỌGỌ́RIN ỌDÚN TÓ JẸ́ BÀBÁ ÌSÀLẸ̀ ÀWỌN AJÍNIGBÉ LÉKÌTÌ ÀTI ÀYÍKÁ Ẹ̀
07/02/2024

ALÀGBÀ OLOWOFẸLA, ẸNI ỌGỌ́RIN ỌDÚN TÓ JẸ́ BÀBÁ ÌSÀLẸ̀ ÀWỌN AJÍNIGBÉ LÉKÌTÌ ÀTI ÀYÍKÁ Ẹ̀

SUPER EAGLES WỌ ÌPELE ÀṢEKÁGBÁ AFCON 2023 | PẸNÁRITÌ NI WỌ́N FI PA SOUTH AFRICA
07/02/2024

SUPER EAGLES WỌ ÌPELE ÀṢEKÁGBÁ AFCON 2023 | PẸNÁRITÌ NI WỌ́N FI PA SOUTH AFRICA

ÀWỌN AJÍNIGBÉ BÈÈRÈ ÌRẸSÌ ÀTI OWÓ GỌBỌI. [Fábùnmi]Àwọn òbí àti àwọn tó ni ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ Apostolic Group of School...
05/02/2024

ÀWỌN AJÍNIGBÉ BÈÈRÈ ÌRẸSÌ ÀTI OWÓ GỌBỌI.

[Fábùnmi]

Àwọn òbí àti àwọn tó ni ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ Apostolic Group of Schools, Emure Èkìtì, ṣàlàyé bí orí ṣe kó àwọn ọmọ Ilé-ìwé yọ nínú ìgbèkùn ìjínigbé.

Àwọn òbí ọmọ Ilé-ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé Apostolic Faith, Ilú Emure Èkìtì márùn-ún tí wọ́n jí gbé ṣàlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn ní ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kẹrin, oṣù kejì, ọdún 2024, pé wọ́n fẹ́rẹ̀ la ewu iná kọjá kó tó di wí pé wọ́n tú àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn àwọn ajínigbé.

Wọ́n tú àwọn ọmọ kéékèèké márùn-ún ọ̀hún sílẹ̀ ní ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kẹrin, oṣù kejì ọdún 2024 lẹ́yìn tí wọ́n ti gba N15m owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ wọn.

Lẹ́yìn owó tí wọ́n gbà, àwọn ajínigbé náà tún dúró lórí gbígba ìrẹsì díndín, àwọn ohun mímu afúnnilókun àti àwọn sìgá lọ́wọ́ wọn.

Olùdásílẹ̀ ilé ìwé ọ̀hún, Gabriel Adesanya, sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé wọ́n gbẹ̀mí awakọ̀ bọ́ọ̀sì Ilé-ìwé tí wọ́n jí gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀hún, tó sì tún ní wọn kòì tíì rí òkú awakọ̀ ọ̀hún gbé wálé.

Nígbà tí wọ́n pe ọkàn lára àwọn òbí àwọn ọmọ ọ̀hún tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adebisi Jegede, ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n san owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé náà.

03/02/2024

PETER OBI ṢE ÀTÌLẸ́YÌN FÚN IKỌ̀ SUPER EAGLES NÍ ORÍLẸ̀ ÈDÈ COTE D VOIRE.

03/02/2024

IJÓ AYỌ̀ LẸ́SẸ̀ IKỌ̀ AGBÁBỌ́Ọ́LÙ SUPER EAGLES

SUPER EAGLES WỌ SẸMI FAINÀ! ÌPELE TÓ SÚNMỌ́ ÀṢEKÁGBÁ😜❤️
02/02/2024

SUPER EAGLES WỌ SẸMI FAINÀ! ÌPELE TÓ SÚNMỌ́ ÀṢEKÁGBÁ😜❤️

NÀÌJÍRÍÀ Ẹ FURA O! ILẸ̀ Ń YỌ̀ NÍ AFCON|Ogidiolu|      Gbogbo ẹni tó gbá bọ́ọ̀lù fún orílẹ̀-èdè Angola ni ilé iṣẹ́ ìbára-...
01/02/2024

NÀÌJÍRÍÀ Ẹ FURA O! ILẸ̀ Ń YỌ̀ NÍ AFCON
|Ogidiolu|



Gbogbo ẹni tó gbá bọ́ọ̀lù fún orílẹ̀-èdè Angola ni ilé iṣẹ́ ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ UNITEL fún ní Iphone 15, nígbà tí wọ́n da àgbo ikọ̀ ẹgbẹ́ agbá bọ́ọ̀lù Nàmíbíà sígbó.

Láfikún, orí kànkan ni ó gba ẹgbẹ̀rún mẹ́fà dollar láti ọwọ́ ilé ìfowópamọ́ ti ilẹ̀ Angola nígbà tí wọ́n fi àmì mẹ́ta sí òdo ṣẹ́gun ẹgbẹ́ agbá bọ́ọ̀lù Nàmíbíà ní ìpele ti mẹ́rìndínlógún nínú ìdíje bọ́ọ̀lù ti ilẹ̀ adúláwọ̀ (AFCON).

Ilé ìfowópamọ́ ilẹ̀ Angola kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Benco Keve ti ṣe ìlérí PÉ àwọn yóò fún àwọn agbá bọ́ọ̀lù náà ni ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn lé ní ẹgbẹ̀ta dollar tí wọ́n bá fi lè fi ẹ̀yin aáyán ẹgbẹ́ agbá bọ́ọ̀lù Nàìjíríà lélẹ̀.

Nígbà tí ilé iṣẹ́ tó ń ṣe òkúta iyebíye tí Angola, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Social EP ti ṣe ìlérí láti fún ikọ̀ agbá bọ́ọ̀lù náà ni Ẹgbẹ̀rún Àádọta -lé-lúgba dollar tí wọ́n bá lè tọwọ́ ikọ̀ agbá bọ́ọ̀lù Nàìjíríà bọ aṣọ.

ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ ṢE ÌLÉRÍ ÌDÁJỌ́ ÒDODO FÚN AKẸ́KỌ̀Ọ́ TÍ OLÙKỌ́ FI ẸGBA GBA Ẹ̀MÍ RẸ̀.[Fábùnmi]Àwọn ìgbìmọ̀ kan ní ìjọba ...
30/01/2024

ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ ṢE ÌLÉRÍ ÌDÁJỌ́ ÒDODO FÚN AKẸ́KỌ̀Ọ́ TÍ OLÙKỌ́ FI ẸGBA GBA Ẹ̀MÍ RẸ̀.

[Fábùnmi]

Àwọn ìgbìmọ̀ kan ní ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti ṣe àbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí mọ̀lẹ́bí olóògbé akẹ́kọ̀ọ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún ní ilé ìwé Girama àgbà Aromi-Ilogbogbo, Oko-Afo ní ìlú Badagry, ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù kínní, ọdún 2024, tí olùkọ́ Ilé-ìwé kan nà dójú ikú.

Àwọn ìgbìmọ̀ ọ̀hún ni Kọmíṣánnà fọ́rọ̀ Ẹ̀kọ́ Jamiu Alli-Balogun darí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Oludari ètò ẹ̀kọ́ Ganiyu Lawal fi síta pé àwọn fi dá àwọn màlẹ́bí olóògbé náà lójú pé àwọn yóò rí kúlẹ̀kúlẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó gbẹ̀mí ọmọkùnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ David Babadipo, tó wà ní girama àgbà onípele kínní (SS 1).

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí a gbọ́ ni wí pé, olùkọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oluwale, ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ẹgba gbẹ̀mí lẹ́nu ọmọkùnrin ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù kínní ọdún 2024.ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI ṢE ÌLÉRÍ ÌDÁJỌ́ ÒDODO FÚN AKẸ́KỌ̀Ọ́ TÍ OLÙKỌ́ FI ẸGBA GBA Ẹ̀MÍ RẸ̀.

[Fábùnmi]

Àwọn ìgbìmọ̀ kan ní ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti ṣe àbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí mọ̀lẹ́bí olóògbé akẹ́kọ̀ọ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún ní ilé ìwé Girama àgbà Aromi-Ilogbogbo, Oko-Afo ní ìlú Badagry, ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù kínní, ọdún 2024, tí olùkọ́ Ilé-ìwé kan nà dójú ikú.

Àwọn ìgbìmọ̀ ọ̀hún ni Kọmíṣánnà fọ́rọ̀ Ẹ̀kọ́ Jamiu Alli-Balogun darí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Oludari ètò ẹ̀kọ́ Ganiyu Lawal fi síta pé àwọn fi dá àwọn màlẹ́bí olóògbé náà lójú pé àwọn yóò rí kúlẹ̀kúlẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó gbẹ̀mí ọmọkùnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ David Babadipo, tó wà ní girama àgbà onípele kínní (SS 1).

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí a gbọ́ ni wí pé, olùkọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oluwale, ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ẹgba gbẹ̀mí lẹ́nu ọmọkùnrin ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù kínní ọdún 2024.

ÈBÚTÉKỌ̀ LEKKI DEEP SEA GBA ÀLEJÒ ỌKỌ̀ OJÚ OMI ŃLÁ NÍ ÌWỌ̀ OÒRÙN ÁFÍRÍKÀ.Àyìnlá Omi. Èbútékọ̀ tuntun ni ìpínlẹ̀ Èkó lekk...
29/01/2024

ÈBÚTÉKỌ̀ LEKKI DEEP SEA GBA ÀLEJÒ ỌKỌ̀ OJÚ OMI ŃLÁ NÍ ÌWỌ̀ OÒRÙN ÁFÍRÍKÀ.

Àyìnlá Omi.

Èbútékọ̀ tuntun ni ìpínlẹ̀ Èkó lekki deep seaport gba àlejò ọkàn nínú ọkọ ojú omi tó gun lagbaye.

Ọkọ̀ ojú omi CMA CGM SCANDOLA gùn ni ìwọ̀n bàtà ọọdunrun lè mẹ́rin lè laadọrin. Ó fẹ ni ìwọ̀n bàtà marundinlọgọta.

Ọkọ̀ yìí ni ọkọ àkọ́kọ́ to ń ṣe àmúlò afẹ́fẹ́ ìdáná fi ṣe agbára tí yóò kọ́kọ́ wọ ìwọ oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà.

Ìròyìn fi tó wa létí pé ebutekọ lekki seaport tí bẹ̀rẹ̀ síni ri eto ọ̀rọ̀ ajé èyí tí yóò ṣe orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní àǹfààní púpọ̀.

ỌWỌ́ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI TẸ AJÍNIGBÉ TÓ JÍ TẸ̀GBỌ́N TÀBÚRÒ OBÌNRIN GBÉ NÍ ABUJA[Fábùnmi]Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti fi páńpẹ́ òfin g...
29/01/2024

ỌWỌ́ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI TẸ AJÍNIGBÉ TÓ JÍ TẸ̀GBỌ́N TÀBÚRÒ OBÌNRIN GBÉ NÍ ABUJA

[Fábùnmi]

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti fi páńpẹ́ òfin gbé ajínigbé, Bello Mohammed, afunrasí tó ṣekú pa Nabeeha Al-kadriyar.

Olóògbé Nabeeha ni ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìyá mẹ́fà láti ìdílé Al-kadriyar tí wọ́n jí gbé pẹ̀lú àwọn mẹ́tàdínlógún mìíràn ní agbègbè Bwari ní olú ìlú ìjọba Àpapọ̀ Abuja ní ọjọ́ kejì, oṣù kínní, ọdún 2024.

Nínú ọ̀rọ̀ tí Alukoro ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá, Olumuyiwa Adejobi fi síta ní àná ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù kínní, ọdún 2024, pé ọwọ́ tẹ Mohammed ní ilé ìtura kan tó wà ní Kaduna ní ogúnjọ́, oṣù kínní, ọdún 2024.

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti ẹkùn Tafa tó ṣe ìtọpinpin ni wọ́n ya bo ilé ìtura kan tó wà ní agbègbè Tafa ní Kaduna, níbi tí wọ́n ti fi páńpẹ́ òfin gbé Bello pẹ̀lú N2.25m tí wọ́n bá lọ́wọ́ rẹ̀. Afunrasí ọ̀hún ni ó fẹ́ tẹ̀síwájú nípa gbígba owó tí yóò fi tú àwọn tó jí gbé sílẹ̀ ní àárín agbègbè ọ̀hún.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe fún afunrasí náà ni ó ti jẹ́wọ́ pé òun pẹ̀lú àwọn tó jí àwọn ìdílé Agbẹjọ́rò kan tí orúkọ ń jẹ́ Ariyo ní Bwari, Ilú Abuja gbé ní ọjọ́ kejì oṣù kínní, ọdún 2024, tí òun sì gbẹ̀mí àwọn kan tí wọ́n jí gbé.

28/01/2024

ÀWỌN ỌMỌ IKỌ̀ AGBÁBỌ́Ọ́LÙ SUPER EAGLES Ń JÓ IJÓ AYỌ̀ LẸ́HÌN TÍ WỌ́N SỌ KÌNÌÚN CAMEROON DI AJÁ INÚ ÌWÉ.

28/01/2024

TÓBI AMUṢAN DI ỌBA ELÉRÉ SÍSÁ NILẸ ÁFÍRÍKÀ, Ó SA ERE LÁÀRIN ÌṢẸ́JÚ MÉJE ÀÁYÁ ÀTI DÍẸ̀ NÍBI ÌDIJE ERÉ SÍSÁ LÁBẸ́ ILÉ NÍ ÌLÚ ASTANA LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ KAZAKHSTAN.

Address

Ikeja
Lagos

Telephone

+2348033132123

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Eko News.Com posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Videos

Share


Other Broadcasting & media production in Lagos

Show All