Eya Yoruba

Eya Yoruba Ẹ káàbọ̀ sí Ìkànnì Ẹ̀yà Yorùbá fún ìgbélárugẹ àwùjọ Yorùbá. E ó ní àǹfààní láti mọ́ nípa àṣà Yorùbá.
(3)

Káàárọ̀-Oòjiíire-Ọmọ Yorùbá Foundation (KOOF) tako portable lórí ọ̀rọ̀ OLORÌ ALÁÀFIN. #ẹ̀yàyorùbá
16/12/2024

Káàárọ̀-Oòjiíire-Ọmọ Yorùbá Foundation (KOOF) tako portable lórí ọ̀rọ̀ OLORÌ ALÁÀFIN.
#ẹ̀yàyorùbá

Àrúgbó ṣoge rí, àkísà pàápàá lògbà ri!!! Kín ni àwòràán yìí mú u yín rántí? #ẹ̀yàyorùbá  ̣
16/12/2024

Àrúgbó ṣoge rí, àkísà pàápàá lògbà ri!!! Kín ni àwòràán yìí mú u yín rántí?
#ẹ̀yàyorùbá ̣

Ìwúre Ọ̀sẹ̀Àná lọjọ́ ọsẹ̀ tuntun, ọjọ́ ìsinmi niAdúpẹ́ tá ò sinmi lékú lọ́wọ́Àwa ò sinmi sínú sàréèỌjọ́ Ajé lòní, àwa yó...
16/12/2024

Ìwúre Ọ̀sẹ̀
Àná lọjọ́ ọsẹ̀ tuntun, ọjọ́ ìsinmi ni
Adúpẹ́ tá ò sinmi lékú lọ́wọ́
Àwa ò sinmi sínú sàréè
Ọjọ́ Ajé lòní, àwa yóò rájé jẹun
Ajé yóò filé wa ṣebùgbé
Ọ̀la l'ọjọ́ ìṣégun, ogun rírí àt'ogun àìrí yóò ṣé fún
Ogun k'ógun kì yóò borí àwa, àwa yóò di àṣégun
Ọ̀túnla lọjọ́ Rú, àwa ò ní rùkú wọlé, a ò ní rùkú jáde
Ọjọ́ kẹrin ọ̀sẹ̀ ni ọjọ́ bọ̀,
Owó, Ọmọ, Ọlá, Àgbéga, Àlàáfíà yóò bọ̀ fún tọkọ taya wa. Ìṣe ọmọ wa yóò ṣojú wa
Ọjọ́ Ẹtì ni ìkarùn ún nínú ọ̀sẹ̀, Ẹtì kò ní bá ọrọ̀ ayé wa
Àwa kì yóò ṣàṣetì lọ́lá Àláwùràbí
Ọjọ Àbámẹ́ta ló kẹ́yìn nínú ọ̀sẹ̀, àbá wa láti pẹ́ bí mọ́mọ́ ṣe n pẹ́ láyè, yóò ṣẹ
Àbá wa láti má ṣiṣẹ́ f'óníṣé láyé yóò ṣẹ
Àbá wa láti jẹ́ẹ̀yàn yóò ṣẹ
Àbá wá láti jèrè àwọn ọmọ wa , yóò ṣẹ
Nítorí àbá t'álágẹmọ bá dá, n l'òrìṣà òké ó gbè🙏🙏🙏🙏🙏
̣sẹ̀

EWU INÁ KÌ Í PÀWÒDÌ
16/12/2024

EWU INÁ KÌ Í PÀWÒDÌ

LÁGBO ÒṢÈRÉÒní ni ìrántí olóògbé Síkírù Ọlọ́ládé Barrister. Gbajúgbajà àti olúdásílẹ̀ Fújì nígbà ayé wọn. Wọn ti ṣiṣẹ́ o...
15/12/2024

LÁGBO ÒṢÈRÉ
Òní ni ìrántí olóògbé Síkírù Ọlọ́ládé Barrister. Gbajúgbajà àti olúdásílẹ̀ Fújì nígbà ayé wọn. Wọn ti ṣiṣẹ́ ológun ilẹ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ kí wọn tó di olórin. Ọba kó dẹlẹ̀ f'ẹ́ni ire🙏🙏🙏🙏. Ẹ KỌ DÍẸ̀ FÚN WA NÍNÚ ORIN WỌN

Àwòrán níbi ayẹyẹ ìsìnkú Ọba Ọwá Obòkún Tilẹ̀ Ìjèsà Olóògbé Gabriel Adekunle Arómọ́láàrán.
14/12/2024

Àwòrán níbi ayẹyẹ ìsìnkú Ọba Ọwá Obòkún Tilẹ̀ Ìjèsà Olóògbé Gabriel Adekunle Arómọ́láàrán.

Iṣu ata yánanyànan láàrín Olorì Aláàfin Ọ̀yọ́ àti gbajúgbajà olórin Zazuu, Habeeb Olálọmi. Àmọ́ kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ látị dọ́rè...
14/12/2024

Iṣu ata yánanyànan láàrín Olorì Aláàfin Ọ̀yọ́ àti gbajúgbajà olórin Zazuu, Habeeb Olálọmi. Àmọ́ kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ látị dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn lẹ́yìn ikú ọkọ ẹni, Ó kàn jẹ́ wèrè ni ká yẹra fún ooo.

Bèbè ìdí rèé!!! Iṣẹ́ kí ló n ṣe?
14/12/2024

Bèbè ìdí rèé!!! Iṣẹ́ kí ló n ṣe?

ÌDÁMỌ̀ ẸRANKOẸ kàárọ̀ o.Ǹjẹ́ kínni ẹ̀ ńpe kòkòrò yìí lọ́dọ̀ tiyín, àti wípé kínni à lè ṣe sí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí?        ...
14/12/2024

ÌDÁMỌ̀ ẸRANKO

Ẹ kàárọ̀ o.

Ǹjẹ́ kínni ẹ̀ ńpe kòkòrò yìí lọ́dọ̀ tiyín, àti wípé kínni à lè ṣe sí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí?

Ọ̀RỌ̀ TÓ N LỌAdájọ́ ti ni kí arákùnrin yìí máa gba ilé wá jẹ́jọ́ lẹ́yìn to tí yọ díẹ̀ nínú owó tó jí bù pamọ́ fún ilé ẹj...
14/12/2024

Ọ̀RỌ̀ TÓ N LỌ

Adájọ́ ti ni kí arákùnrin yìí máa gba ilé wá jẹ́jọ́ lẹ́yìn to tí yọ díẹ̀ nínú owó tó jí bù pamọ́ fún ilé ẹjọ́, owó gbà, mábínú, túmisílẹ̀. Ẹ Mágbàgbé pé lára owó tó jí bù pamọ́ ló sán owó iléèwé ọmọọmọ̀ rẹ̀ títì di ọdún 2030.
Ayé níkà!!!
#ọ̀rọ̀tónlọ

Kín ni àwòrán yìí mú u yín rántí???
14/12/2024

Kín ni àwòrán yìí mú u yín rántí???

Agbẹnusọ fún ọ̀gá àgbà ilé ìfowópamọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Hakama Sidi ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àhesọ ọ̀rọ̀ ni pé a ó kó ...
14/12/2024

Agbẹnusọ fún ọ̀gá àgbà ilé ìfowópamọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Hakama Sidi ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àhesọ ọ̀rọ̀ ni pé a ó kó àwọn owó àtijọ́ nílẹ̀ nínú ọdún yìí, Irọ́ ni ooooo, Wọ́n ni ká máa nà mọ́ ara wọn yálà tuntun tàbí tàtijọ́. Èyíkéyí tó bá ká mọ́wa lọ́wọ́, níná ni kí a máa fi ṣe.
A ò ní wówó tì láṣẹ Èdùmàrè🙏

13/12/2024

Ẹ̀yín ọmọ Ìbàdàn àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀, WÈRÈ OLÓRIN ni kò sí ilé tó ní POP ní ìlú yín😝😝😝😝. Ṣé bẹ́ẹ̀ ni?
̣jímọ̀

13/12/2024

Ṣé ẹ̀yín kò tí ì fi ojú àṣà Yorùbá gbolẹ̀ nínú ilé yín? Ṣé àwọn ògo wẹẹrẹ tiyín n sọ èdè abínibí báyìí? Ẹ rántí pé ọ̀pọ̀ Ifáfitì lo ti ṣe èdè Yorùbá ni kàn án pá fún gbogbo Akẹ́kọ̀ọ́ báyìí, pàápàá LASU, LASUSTECH abbl? Ẹ kò gbodọ̀ jẹ́ kí èdè Yorùbá ti ọwọ́ yín yí mẹ́rẹ̀ oooo. Á JÚWA Á ṢE OOOO.

13/12/2024

ỌJÀ PÀYÀMỌ́RA...

ÌDÁMỌ̀ ẸRANKOA kúu ìsinmi tí óún kàn 'lẹ̀kùn.Ẹ bá wa sọ ọ̀rọ̀ Yorùbá nípa ẹyẹ yíì o.
13/12/2024

ÌDÁMỌ̀ ẸRANKO

A kúu ìsinmi tí óún kàn 'lẹ̀kùn.

Ẹ bá wa sọ ọ̀rọ̀ Yorùbá nípa ẹyẹ yíì o.

ÌDÁNILẸ́KỌ̀Ọ́ : ÌBEJÌ ALÁPAPỌ̀Àwọn ọmọ méjì tí ọlẹ̀( embryo) wọn lẹ̀ pọ̀ ni a mọ̀ sí siamese twins. Láti inú oyún ni wọn...
13/12/2024

ÌDÁNILẸ́KỌ̀Ọ́ : ÌBEJÌ ALÁPAPỌ̀
Àwọn ọmọ méjì tí ọlẹ̀( embryo) wọn lẹ̀ pọ̀ ni a mọ̀ sí siamese twins. Láti inú oyún ni wọn ti lẹ̀ pàpọ̀, oyún wọn kìí tọ́jọ́ tàbí kí ọmọ náà kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí wọn bí i tán.

Àwọn ìbejì yìí le è lẹ̀pọ̀ láti ibi àyà, orí, ìdí tàbí ìsàlẹ̀ inú. Ẹ̀yà ara kan ṣoṣo ni àwọn ìbejì yìí máa n pín. Wọ́n le è pín ọpọlọ ( brain) ìfun( intestine) kíndìnrín (kidney) tàbí ẹ̀dọ̀( liver) kan ṣoṣo.

Ronald àti Donald Galyon ni àwọn ìbejì alápapọ̀ tó pẹ́ láyé jù, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti bí wọn lọ́dún 1951-2020. Nnkan ọmọkùnrin kan náà ni wọ́n gbé wáyé.

Njẹ́ Ẹ tílẹ̀ mọ̀ pé wọ́n le è yè? Bẹ́ẹ̀ni ooo, bí ibi tí wọ́n ti lẹ̀pọ̀ kò bá la ẹ̀mí lọ, àwọn dọ́kítà oníṣègùn òyìnbó le è yà wọ́n, èyí kìí ṣe iṣẹ́ ayé oooo.

Díẹ̀ lára àkíyèsí oyún ìbejì alápapọ̀ ;
a. Ikùn aláboyún tó tóbi jù
b. à pọ̀jù òòyì ojú, èébì, àyà rírìn, inú rírun àti àwọn àìlera aláboyún mìíràn
d. a le è tètè ṣàkíyèsí rẹ̀ níbi àwòrán ọmọ inú ẹni ( Scan).
Òṣùbà👊👊👊👊 fún àwọn ilé ìwòsàn bí i UCH, OAU, OOU tí wọn n ṣiṣẹ́ takuntakun ìpínyà àwọn ìbejì alápapọ̀ náà ni àṣeyè.
#ẹ̀yàyorùbá ̣

Address

Thanes Villa, Seven Sister's Road, Finsbury Park
London
N77PH

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Eya Yoruba posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to Eya Yoruba:

Videos

Share