04/04/2024
*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KẸRÌN OṢÙ KẸRÌN ỌDÚN 2024*
1. *ÀWỌN MỌ̀LẸ́BÍ ADARÍ IKỌ̀ TÓ Ń BÉÈRÈ FÚN ÌDÁSÍLẸ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ BIAFRA (IPOB) MAZI NNAMDI KANU TI RAWỌ́ Ẹ̀BẸ̀ SÍ ÀWỌN GÓMÌNÀ TÍ Ó WÀ NÍ ẸKÙN GÚÚSÙ ÌLÀ OÒRÙN LÁTI TÈTÈ BÁ WỌN WÁ ǸKAN ṢE SÍ BÍ KÁNU YÓÒ ṢE GBA ÌTÚSÍLẸ̀ NÍ ÀKÀTÀ ÀWỌN ELÉTÒ ÀÀBÒ ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TÓ WÀ*
2. *GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ KÁNÒ, ÀLHÁJÌ ABBA KABIR YUSUF TI KÌLỌ̀ PÉ ẸNIKẸ́NI, TÀBÍ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ ALÁÀBÒ TÓ BÁ GBÉ OÚNJẸ ÌRÀNWỌ́ TÍ ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ KÁNÒ FUN ÀWỌN ÈNÌYÀN GBA IBÒMÍRÀN LỌ Á LO GBOGBO ỌJỌ́ AYÉ Ẹ̀ TÓ KÙ LỌ́GBÀ Ẹ̀WỌ̀N*
3. *ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, ÀWỌN FIJILANTÉ, ÀJỌ SO SAFE, IKỌ̀ ÀMỌ̀TẸ́KÙN TI SỌ PÉ ÀWỌN TI BẸ̀RẸ̀ SI NÍ ṢE ÌWÁDÌÍ LÓRÍ ỌLỌ́KADÀ ÀTI ÈRÒ Ẹ̀ KAN TÍ ÀWỌN AJÍNIGBÉ JÍ GBÉ BẸ́Ẹ̀ SÌ NI WỌ́N ṢE ÌLÉRÍ PÉ ỌWỌ́ MÁA TÓ TẸ ÀWỌN AJÍNIGBÉ YÌÍ*
4. *ÀÀRẸ ẸGBẸ́ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ (NLC) TẸ́LẸ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, ÀLÍ CIROMA TI JÁDE LÁYÉ*
5. *GÓMÌNÀ ABDULRAHMAN ABDULRASAQ BÁ ÀWỌN ARÁ Ọ̀FFÀ KẸ́DÙN LÓRÍ ỌJÀ OWÓDÉ TÓ JÓNÁ*
6. *Ọ̀GÁ ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN TI KÌLỌ̀ FÚN ÀWỌN ỌLỌ́MỌGE TÓ Ń ṢIṢẸ́ AṢẸ́WÓ PÉ KÍ WỌ́N ṢỌ́RA KÍ WỌ́N MÁ BA FI WỌ́N ṢE ÈTÙTÙ ỌLÀ*
7. *ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ KWARA TI ṢÈLÉRÍ PÉ GBOGBO ÀGBÈGBÈ TÓ WÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KWARA NI YÓÒ JẸ ÌGBÁDÙN OMI Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDÉ LÁSÌKÒ YÌÍ*
8. *ỌYÁWOYÈ DI OLÙBÁDÁMỌ̀RÀN PÀTÀKÌ LÓRÍ ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KWARA*
9. *ỌWỌ́ ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ DÍDÈNÀ ÌWÀ ÌBÀJẸ́ ÀTI ṢÍṢE OWÓ ÌLÚ KÚMỌKÙMỌ (EFCC) TI TẸ ÀWỌN ALUJÌBÌTÌ ORÍ Ẹ̀RỌ̀ AYÉLUJÁRA (YAHOO) MẸ́RÌNLÉLÁÀDỌ́RIN NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN*
10. *ỌWỌ́ ÀJỌ ÀMỌ̀TẸ́KÙN TẸ BABALỌLÁ TÓ FI ÒRÙKA ÌGBÀDÍ JÍ ÌYÁÁLÉ ILÉ GBÉ NÍ ÒṢOGBO*
*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ (GLAMOURLADY)*
*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN)*