01/07/2024
*ASIRI IJINLE TI ỌLỌRUN, JAH 🔥 _SERIES 17* 🔥🔥🔥🔥🔥🔥
HALLELUYAH GBOGBO ILE, E KAARO A KU OJO ONI A SI KU ASE KU ODUN, LORUKO JESU ODUN YI YOO JE ODUN ISELOGO FUN WA LORUKO JESU..
OUN TI A MU WA FUN YIN LONI LO DA LORI ORUKO OLUWA TI AKOLE RE N JE JAH…
LARA AWON ORUKO TI ỌLỌRUN N JE TI KO SE FOWO RO SEHIN NINU OPO AWON ORUKO RE NI ORUKO TI A N PE NI JAH YI WA, (ASIRI ATI IWULO BIBELI) TI A BA TUN PE ORUKO YI NI YAH, KOSI ABURU NBE NITORI NINU AWON ALFABETI TI HEBERU BI IRU TI YORUBA TI A NI (A,B,D) NA NI A NI ALEPH, BETA, GIMEL, DALETH (A.b.c.d) LEDE HEBERU…
ṢUGBỌN NINU EDE HEBERU KOSI LETA J NINU ALFABETI WON GEGEBI KOSE SI LETA C,Q,Z NINU ALFABETI YORUBA ṢUGBỌN TI NBE NINU TI EDE GEESI TI NSE TI OYINBO TO GBAJUMO JAKEJADO AGBAYE…
ORUKO OLUWA TI A NPE NI JAH YI O JE ORUKO KAN TI A MU JADE WA LATINU ORUKO OLUWA EYI TI A MO SI JEHOFA (JEHOVAH) TABI YAHWEH, FUN APEERE HALLELUYAH, HALLELU(J)AH… FUN APEERE BAKAN NA, OLUFEMI, (OLU), OBA FEMI, (OBA), OLAOYE, (OLA), GELE BI MO SE YO GBOGBO AWON ORUKO TI MO FI SINU BRACKET WON YEN SOTO BEE NA NI, (ASIRI ATI IWULO BIBELI) ORUKO OLUWA JAH TI A MU JADE WA NINU OJULOWO ORUKO TI ỌLỌRUN OLODUMARE N JE LEDE AWON HEBERU, J/YAHWEH (YHWH) (JHWH).
ORUKO JEHOVAH YI JE ORUKO OLUWA TI A MU JADE WA LATINU EDE LATINI WA, A TUN LE PE NI ORUKO TI IGBA LODE (modern name) YAHWEH JE OJULOWO ORUKO OLUWA TI EDE HEBERU TO TI WA TIPE TIPE (ancient) ṢUGBỌN (ASIRI ATI IWULO BIBELI) OJULOWO ORUKO OLUWA GANGAN NI (YHWH) TI O JE LETA MERIN PERE TI A TUN NPE NI TETRAGRAMMATON TO TUNMO SI LETA MERIN TO JE OJULOWO ORUKO ỌLỌRUN, TI ỌLỌRUN PERA RE FUN MOSE, EDE MEJI LO JE EDE KAN GBOOGI TI O LAGBARA LORILE AYE EDE AKOKO NI EDE HEBERU TO TI ARAMAIKI WA ATI EDE LARUBAWA (Arabic languages)...
TOO, BI MO SE NSO LO, ORUKO YI JE ORUKO OLUWA TI O JE MIMO (Most Holiest on earth) GIDI GIDI TI A YA SOTO (consecrate/sanctify) (Asiri ati iwulo Bibeli) DEBI PE EKAN LODUN NI AWON RABBI TI A MO SI OLUKONI/ONIMO/AMOYE A MAA PE E SI AWON AKEKO WON LETI, NI AARIN KAN NIGBA AYE AWON SOOLU (LEHIN IKU KRISTI/ A.D) KI O TO DI POOLU APOSTELI, E MA GBAGBE PE POOLU TI FIGBA KAN RI JE OKAN LARA AWON AKEKO LODO AWON FARISI, O JE AKEKO TO NI IMO GIDI GIDI TORI O JE OKAN LARA AWON OMO JUU TI O DARA JULO LABE EKO AWON FARISI NIGBA NA, (Filipi 3:4–6; Galatia 1:13–14), LAYE IJOUN WON O KI N FE PE ORUKO OLUWA NI GBANGBA LETI AWON EYAN, (Asiri ati iwulo Bibeli) IBI TI ORUKO OLUWA TI A NPE NI ADONAI TI WOLE WA NIYI, KAKA KI WON PE ORUKO YHWH YI WON A KUKU PE NI ADONAI (OLUWA) LETI AWON ARA ILU NIGBA TI WON BA N SE IWAASU TI WON NIGBA NA FAWON EYAN GEGEBI OFIN MOSE TI WON GBE DANI TI WON SI N TELE..
HALLELUYAH, WON GBAGBO PE AWON ENIYAN LE BA ORUKO OLUWA JE, WON LE MU KI IDIBAJE (corrupt) O DE BA ORUKO NA TI O BA DI OUN TI TAJA TERAN KAN NPE, EYI NI IBERU TI WON NI FUN ORUKO OLUWA NIGBA NA LO MU KI WON FI ORUKO YI PAMO ATI WIPE ORUKO NA NIGBA NA JE ASE ATI AGBARA TO LEWU PUPO PUPO LATI MAA SO TABI PE FI GBADURA NIGBA NA, TORI KOSI OUN TI ENI TI O JE MIMO TABI TO YARA RE SI MIMO O FI SE TI KO NI JE BI INA PELU ORUKO ANGELI TI AWON KAN TUN NPE NI OOSA EGYPTI ALAGBARA NLA KAN TO FARA SIN TI OPO AWON EYAN KAN NPE LEHIN ADURA WON TI WON KOSI SAKIYESI TABI KOBI ARA SI, EYI TI ORUKO RE NJE (Amin, Amen, Amon, Amun, Ammon tabi Amoun-ra.) LORI ORO ISEMI KAN ENI TI ORUKO RE N JE AMIN, AMEEN, AMU RA YI ORO NBO LORI RE NI SERIES 20 TA O MAA FI KADI RE FUN WA LORI AFEFE, AWON TI WON BA NFE SERIES YI LATI APA KINNI T**I DE APA AADOTA NI KI WON O KAN SI MI LATI NI EDA (copy) TI WON LOWO FUN RIRA..
OPO NI KO TI E MO PE AMIN (Amen) TI OPO WA MA NSE LEHIN ADURA LORI LO NI ORISUN ATI ITAN TO BI ORUKO YI, (Asiri ati iwulo Bibeli) KILODE TO JE PE GBOGBO IBI TI A BA TI N DARUKO AMIN NINU BIBELI NISE LO MA N DABI IGBA TI A BA DARUKO ENIYAN, (It's more like a proper noun, Akin, why not akin, Amen instead of amen, why Amen/Amin, and not amen.?) HMMMMMN… ORO NBO NI SERIES 20 TI JESU BA FA BIBO RE SEHIN A O MAA TU PERE PEERE RE, SE LOOTO NI ABI O KAN JE SABABI (Coincidence) LASAN PELU ORUKO ORISA ILE EGYPTI YI? ORO NBO LORI RE NIJO IWAJU…
HALLELUYAH, BI MO TI SE N SO LO, ORUKO OLUWA YI, IWADI NJE KO YE WA PE AWON ONI PIDAN PIDAN ALALUPAIDA (magicians) NA NLO ORUKO YI DAADA LAYE IJOUN NIGBA NA, AWON ELEMI OSO (Sorcerer/wizards) NA A MAA LO, EYI NI AWON FARASI RI TI WON FI DEKUN ATI MAA LO ORUKO NA LAWUJO OPO AWON ENIYAN, (Asiri ati iwulo Bibeli), WON SI PA OPO AWON EYAN TI WON NLO ORUKO OLUWA NIGBA NA, KODA GBOGBO AWON ELESIN TI A MO SI GNOSTICS CHRISTIAN TA WON NA NI AWON IMO ASIRI IJINLE LORISIRISI AWON WONYI GANGAN NI ONIGBAGBO TI WON JE OMOLEHIN KRISTI TI WON NI IMO ASIRI IJINLE LOWO, IMO IKOKO NBE LOWO WON EYI TI AWON TO SI N TELE ILANA ESIN KRISTI NIGBAGBO PE AWON LAWON NI TI AWON SI JE ENI EMI JULO NITORI TI JESU FI KO WON SUGBON TI A O FI OPO RE KUN INU BIBELI RARA, (Asiri ati iwulo Bibeli), ṢUGBỌN TI A YO LATI LE MAA JE GABA ATI MAA SAKOSO LORI OPO AWON ENIYAN LAGBAYE, HMMMMMN….
BI MO SE NSO LO, PUPO NINU AWON TO JE OMOLEHIN KRISTI AWON MEJILA (12) ATI AWON TI A MO SI MEJI LE LAADORIN (72) TI WON O GBAJUMO BI AWON MEJILA TI N TELE JESU KRISTI ATI AWON TO N KAAKIRI PELU WON LAWON FARISI PA NIPAKUPA LEYI TI POOLU APOSTELI JE IRINSE WON NIGBA TO SI NJE SOOLU.. WON PA OPOLOPO AWON EYAN WONYI, WON SI N SO FUN AWON ENIYAN LAYE IGBA NA PE KI WON MA SE TELE ESIN TI WON NITORI ELEMI ESU NI WON, OUN TI WON WA FI BORI OPO AWON ONIGBAGBO LAYE IJOUN NI PE WON GBAGBO PELU IWOYE WON PE EKO ODI NI EKO TI JESU KRISTI FI LE LE LAYE IJO NA NITORI AKARA ATI OTI WAINI ELERIN DODO TI JESU NI KI WON O MAA MU KI WON O SI MAA JE NIRANTI OUN, (Matiu 26:26-29, Maaku 14:22&24, Luku 22:19&20, Johanu 6:53) ATI OPO ISE IYANU TI JESU OLUWA WA TI SE TI WON FI SO PE EMI ESU LO N LO (Matiu 12:24) EYI NI WON RI GBAMU TI WON SI NPE AWON OMOLEHIN JESU NI ELEMI OKUNKUN ATI ELEGBE IMULE (occultic circles) NITORI PE WON NI AKARA (Bread) DURO FUN ERAN ARA KRISTI TI WAINI SI DURO FUN EJE KRISTI, NKAN WONYI NI WON FI BORI WON TI KOSI SI OUN TI ENI TI O DABI GOMINA (prime minister) Felix (a.k.a Marcus Antonius Felix) LE SE SI LAYE IGBA NA, EYIN IGBA TI POOLU SE WA JE OKAN LARA AWON ENI TI O TI N PA NI PRAIM MINISITA ILE ROMU NIGBA NA OGBENI Felix (a.k.a Marcus Antonius Felix) SE WA TI POOLU MOLE SINU TUUBU, (Ise Awon Aposteli 24) LEHIN OREHIN RE NI FESTUS ENI TI O GBA IPO FELIX ANTONIUS WA MU POOLU LO PADE OBA ILE ROMU HERODU KEJI TI ORUKO RE NJE AGRIPPA. (ISE awon Aposteli 25)
OUNJE ALE OLUWA NI JIJE KOSI NINU ESIN ATI ILANA TI MOSE TI AWON FARISI ATI AWON SADUSI N TELE LAYE IGBA NA, GBOGBO AWON EYI ATI EKO ODI TI WON TI KO AWON AKEKO NI POOLU APOSTELI GEGEBI OKAN LARA AWON AKEKO TO NI ITARA PELU IMO LILE RE NI SOOLU GBE SORI NIGBA NA.. POOLU APOSTELI SI RE OUN NA NI AWON ASIRI ORUKO OLODUMARE LOWO DAADA NIGBA NA, INU RE LO TI LO ORUKO NA FI SISE AWON AMI ATI ISE IYANU, GELE (Handkerchief) ATI BANTE (Apron) TO FI WO OPO AWON OLOKUNRUN SAN NIGBA NA. …
BI MO SE NSO LO, LATINU ORUKO YHWH YI NI YAHWEH TI JADE WA NITORI WON FI FAWEELI (Vowel) KUN IGBA TO YA LAWON AARIN KAN NI OPO ODUN SEYIN O DI YAHOWA, IGBA TO YA NI AWON ELEDE LATINI SO DI JAHOWAH TO FI DI PE WON NPE NI JEHOVAH DONI OLONI, JHVH, (Latin, English), IHVH, (Greek), JHWH (English), YHVH (English, Latin), YHWH, (Original ancient name in Hebrew)…
KI WA NITUNMO ORUKO JAH YI FUNRA RE? KINI AWON ASIRI TO RO MO ORUKO YI, KINI A LE FI DA LARA.? KINI ORUKO AWON ANGELI IMOLE TI NBA ORUKO YI SISE..? E JE A PADE NINU NEXT SERIES, E SEUN FUN KIKA, KI ORE OFE OLUWA KI O WA PELU YIN ..…
©️ S.O.