Iroyin Agege

Iroyin Agege Contact information, map and directions, contact form, opening hours, services, ratings, photos, videos and announcements from Iroyin Agege, News & Media Website, .

Okanjua!Iyaleele Onigbẹgbẹ lọrun loun ko fẹ iṣe abẹ ọfẹ mo*O ni ki wọn k'owo iṣẹ abẹ naa tounỌrọ buruku buruku ni awọn e...
21/11/2023

Okanjua!Iyaleele Onigbẹgbẹ lọrun loun ko fẹ iṣe abẹ ọfẹ mo
*O ni ki wọn k'owo iṣẹ abẹ naa toun

Ọrọ buruku buruku ni awọn eeyan ilu n sọ si ọmọbinrin kan to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ọsun ti awọn ileeṣẹ ẹlẹyinju aanu kan fẹẹ ṣeranwọ fun lati ṣiṣe abẹ ọfẹ fun, ki o le bọ lọwọ gbẹgbẹ nla to sọ mọ ọn lọrun, ẹni to taku wọnle nile iwosan wi pe, owo loun fẹ dipo iṣẹ abẹ naa.

Ẹgbẹrun lọna Ọọdunrun niy lowo ti awọn ileeṣẹ naa ri ko jọ fun arabinrin ọhun ṣugbọn nigba ti o yẹ ki iṣẹ abẹ naa bẹrẹ ni iyaleele sọ pe, ki wọn fi gbẹgbẹ ọhun silẹ soun lọrun sibẹ, ki wọn si kowo le oun lọwọ.

Arabinrin ti wọn pe orukọ rẹ ni Fọlakẹmi to wa lati ijọba ibilẹ Ẹdẹ, ẹni to ti n jẹrora ọlọjọ pipẹ lori arun gbẹgbẹ naa ni o ti n beere fun iranlọwọ lọna iṣẹgun oyinbo lori gbẹgbẹ to wa lọrun rẹ ṣugbọn nigba ti awọn akọsẹmọsẹ Dokita kan pinnu lati ṣiṣe abẹ ọfẹ fun un, nigba naa lo sọ pe, oun ko ṣe mọ ṣugbọn ki wọn o ko owo ti wọn ri gba jọ lorukọ oun fun un.

Awọn ajọ abani gbẹru ẹni nibi to ti wuwo julọ naa bẹẹ arabinrin Fọlakẹmi lati yi ero ati ipinnu rẹ pada ṣugbọn o ni dandan ni ki wọn ko ẹgbẹrun lọna Ọọdunrun foun koun le maa lọ sile oun.

Lootọ, wọn fun lowo rẹ, toun naa si pada si abule rẹ niluu Ẹdẹ.

Eemo! Lẹyin ọdun Mọkanlelogun niluu Amẹrika*Baba yii ba'rarẹ labẹ biriji l'Ekoo lairotẹlẹBaba agbalagba ọkunrin ti ẹ n w...
21/11/2023

Eemo! Lẹyin ọdun Mọkanlelogun niluu Amẹrika
*Baba yii ba'rarẹ labẹ biriji l'Ekoo lairotẹlẹ

Baba agbalagba ọkunrin ti ẹ n wo aworan rẹ yii la gbọ wi pe o sa dede ba ara rẹ labẹ afara biriji Oṣodi niluu Eko lẹyin ọdun Mọkanlelogun to ti filuu Amẹrika ṣe ibugbe.

Baba ti a forukọ bo laṣiri yii tu pẹẹpẹẹrẹ ọrọ bi igbesi aye rẹ ṣe dojuru nile iṣẹ agbohun s'afẹfẹ kan niluu Ibadan pe, akẹẹkọ gboye ninu imọ eto isuna ati onimọ nioa ile ifowopamo si loun ṣe niluu London fun ọdun mesan-an gbako lẹyin ti oun wa lọ fi ibugbe oun siluu Amẹrika.

Arakunrin naa sọ pe, wahala to deba oun bẹrẹ nigba toun la ala wi pe oun n fo bi ẹyẹ loju ọrun.

O ni ninu ala ọhun, to da oun pada s'orilẹ-ede Naijiria, o ni bi oun ṣe n fo bi ẹyẹ loju ọrun ni wọn ki oun kaabọ si agbegbe ẹkun Afirika nipato, orilẹ-ede Naijiria.

O ni igba toun ji saye, abẹ biriji Oṣodi niluu Eko loun laju si. O ni oun ko ranti igba toun lọ si papakọ ofurufu wọn niluu Amẹrika lọ wọ ọkọ balua to gbe oun wa Naijiria lẹyin ala ti oun ti n fo loju ọrun toun la.

Ọdun mọkanlelogun ni baba naa loun fi gbe niluu Amẹrika ki ọwọ aye to ba a, to si da a pada s'orilẹ-ede lairotẹlẹ.

𝗛𝗢𝗪 𝗬𝗢𝗥𝗨𝗕𝗔 𝗣𝗘𝗢𝗣𝗟𝗘 & 𝗜𝗡𝗚𝗘𝗡𝗨𝗜𝗧𝗬 𝗖𝗥𝗘𝗔𝗧𝗘𝗗 𝗡𝗢𝗟𝗟𝗬𝗪𝗢𝗢𝗗.The media is currently abuzz with a statement credited to Aisha Lawal wh...
29/08/2023

𝗛𝗢𝗪 𝗬𝗢𝗥𝗨𝗕𝗔 𝗣𝗘𝗢𝗣𝗟𝗘 & 𝗜𝗡𝗚𝗘𝗡𝗨𝗜𝗧𝗬 𝗖𝗥𝗘𝗔𝗧𝗘𝗗 𝗡𝗢𝗟𝗟𝗬𝗪𝗢𝗢𝗗.
The media is currently abuzz with a statement credited to Aisha Lawal which is that the Yoruba people Created and Pioneered the Nigerian movie industry popularly known as "Nollywood". Is it true that the Yoruba people created Nollywood? Let's take a look at what the facts say.

'Nollywood' as we know it today, wasn't always called that. The Nigerian movie scene started with "The Golden age Era" which was the time period between 1950s to late 80s when theatre, stage plays and performance troupes that were mobile dominated the scene. According to the facts, productions from Western Nigeria were the major force propelling the acting industry in this time period. The earliest and most famous Nigerian thespians of then were largely Yoruba people including people like; Moses Olaiya, Jab Adu (Joseph Biodun Babajide), Isola Ogunsola, Ladi Ladebo, Sanya Dosumu and Hubert Ogunde who transitioned into the big screen. It is no mistake that Hubert Ògúndé is regarded as the father of theatre and performace arts in Nigeria.

Latola Films, which started the production of motion pictures since 1962, has often been noted as the earliest Nigerian indigenous film production company in Nigeria. Television broadcasting in Nigeria began in 1959 spear headed by the Western Nigeria Television (WNTV) Ibadan, which made it a point to broadcast the theatre and productions of the early pioneers into the homes of the denizens of Western Nigeria.

Before then a few films such as Kongi's harvest by Francis Oladele, a film based on a work of the same name by Wole Soyinka was released in 1970s. Ola Balogun's post-civil War film, Amadi (1975) was one of the first notable Nigerian historical films on celluloid. Balogun subsequently directed Ajani Ogun in 1976, a film which grew to become very popular, and is widely regarded as the first "commercial" Nigerian film, due to its success. This movie had Adeyemi Afolayan, father of current trailblazers Kunle Afolayan (producer of Anikulapo) as its main star.
Other popular films released in this era include: Bull Frog in the Sun (1974), Dinner with the Devil (1975); directed by the duo Sanya Dosunmu and Wole Amele, Ogunde's Aiye (1979), Jaiyesimi (1980), Cry Freedom (1981). These were all before Achebe's things fall apart was adapted to television in 1987.

Another very successful television adaptation was the adaptation of D.O. Fagunwa's 1949's novel, Igbo Olodumare. The television series of the same title witnessed a tremendous success, especially in South western states, where it was reported that the show constantly left streets deserted during its broadcast on Sunday evenings.

In terms of revenue generation, After several moderately successful films, productions like Papa Ajasco (1984) by Wale Adenuga became one of the first Nigerian mega grossers, reportedly grossing about ₦61,000 (₦88.64 million in 2023) in three days. A year later, Mosebolatan (1985) by Moses Olaiya also grossed ₦107,000 (₦183 million in today's money) within five days and officially became Nigerias first Blockbuster.

Later on in the late 1980's the Golden age began to come to an end due to many reasons but most importantly due to the in crease in the onership of private television sets at home.
The industry moved on to the production of home videos, an era which was termed "The video film era". Again the Yoruba people led and pioneered the industry. Firstly, by 1984, television programming in the western region, which was the major area the cinemas served had improved tremendously and more television stations were established in the region as well, leading to a significant decline in cinema culture and embrace of private television viewing.

Jimi Odumosu's Evil Encounter, a 1983 horror film released directly on television, was the first production to be a pointer to how lucrative making film directly on video can be. The film was extensively promoted before being aired on the television, and as a result, had streets flooded the following morning with video copies of the recorded broadcast. Since Evil Encounter, it became common in Nigerian cities to see video copies of recorded television programmes traded on the streets. This was the method that was adopted by producers and distributors from Eastern Nigeria who came into the movie scene later on, often with copyright violations and piracy issues but with major success in proliferation of views.

The first film produced directly on video in Nigeria is 1988's Soso Meji, produced by Ade Ajiboye. Subsequently, Alade Aromire produced Ekun (1989) on video. These are the pioneers and fathers of Nigerian Home Videos or VHS. The era became entrenched in the 90's with the proliferation of VHS video players in homes. This was the time when movie production from Eastern Nigeria became a major force in Nollywood. Kenneth Nnebue's Living in Bo***ge (1992) was released in this era and many of the popular stars of igbo extraction made their names in this period too.

Now, the Nigerian movie industry or 'Nollywood' is moving to its newest and most modern phase. An Era that has been termed "New Nollywood". New Nolywood is characterized by a major shift in the method of film production, from the video format/VCD discs, which came about during the video boom, back to the original cinema method the industry started out with, which constituted the films produced in the Golden Era of Nigerian cinema, and which also dominates in most countries around the globe with an organized movie industries.

This method is once again led by the Yoruba people. This is evident in the fact that the vast majority of the highest earning/grossing Nigerian movies of recent times have been largely dominated by producers of Southwestern origin like; Funke Akindele Niyi Akinmolayan, Kemi Adetiba, Kayode Kasum and others. Such movies as: Battle on Buka street to Omo ghetto, Wedding party, King of thieves, Ijakumo, King of boys Etc.

The second facet of this new era which has come with the proliferation of internet services of good quality is the- On demand streaming services and payTV sector which has seen Yoruba speaking movie productions like Anikulapo and Jagun Jagun reach record heights, becoming some of the most watched Non-English movies in the entire world on these Internet streaming platforms.

So... Yes, Aisha Oladunni Lawal is very much correct when she said Yorubas created Nollywood. And what she said is verifiable by both historical and empirical data. The only issue is some people who do not like hearing the truth and who enjoy obfuscating historical facts. Ire o.
Credit to (Copied from): The Yoruba Nation CH on X.

Igbimo Ipolongo APC Agege Ati Orile-Agege Sewode Ilaniloye Fawon Oludije Won l'AgegeAwon omo igbimo ipolongo egbe oselu ...
14/01/2023

Igbimo Ipolongo APC Agege Ati Orile-Agege Sewode Ilaniloye Fawon Oludije Won l'Agege

Awon omo igbimo ipolongo egbe oselu Onitesiwaju "All Progress Congress" (APC) ti apapo Agege ati Orile-Agege ti Onorebu Isiaka Alabaja eni to je oludari igbimo ipolongo Agege ati Onorebu Fatai Ajibola to je oludari igbimo ipolongo ti Orile-Agege ko awon omo igbimo eyin won jade lojo Eti Furaide ana lati sewode onimoto tito-telerawon lowoowo lati se ilaniloye lori gbigba kaadi idibo awon araalu to je igbese akoko ki ojo idibo to wole de.

Ninu iwode ipolongo onimoto tito-telerawon lowoowo yii ni awon omo igbimo naa tun ti n ba awon araalu soro lati dibo fun awon oludije ninu egbe APC. Ibo Aare orile-ede yii fun Asiwaju Bola Ahmed Tinub, ibo gomina ipinle Eko fun Babajide Olusola Sanwo-wo, ibo ekun iwo oorun Seneto fun Ojogbon obinrin Idiat Adebule, ibo ile-igbimo asofin l'Abuja lati soju Agege fun Onimo Isegun Wale Ahmed, ibo asoju ile igbimo asofin ipinle Eko Agege 01 fun Abenugan Mudasiru Ajayi Obasa ati ibo ile igbimo asofin ipinle Eko Agege 02 fun Onorebu Jubreel Abdulkareem.

Ofiisi
Abenugan ile igbimo asofin ipinle Eko, iyen Onorebu Mudasiru Ajayi Obasa to wa ni Agege ni ipolongo naa ti bere, ti won si gbe e kiri gbogbo aarin ilu Agege ati Orile-Agege.

Orisiirisii awon nnkan bii aworan awon oludije ni won gbe lowo ti won fi se ipolongo fun awon oludije won, ti won si tun n fun awon eeyan ni iwe ilewo pelebe lati da awon eeyan ti won yoo dibo won fun mo lojo idibo naa.

Olukede:

Eka Iroyin Igbimo Ipolongo Egbe APC Agege ati Orile-Agege

13/01/2023
Apapo Omo Igbimo Ipolongo Idibo Agege Ati Orile-Agege Yoo Bere Ipolongo Lola FuraideApapo omo igbimo ipolongo idibo fun ...
12/01/2023

Apapo Omo Igbimo Ipolongo Idibo Agege Ati Orile-Agege Yoo Bere Ipolongo Lola Furaide

Apapo omo igbimo ipolongo idibo fun ijoba ibile Agege ati ijoba idagbasoke Orile-Agege Eko ti kede wi pe, ipolongo idibo fun awon oludije ti egbe Onitesiwaju won, iyen "All Progressives Congress" (APC) l'Agege ati Orile-Agege yoo se ipolongo onimoto tito-lowoowo kaakiri awon asayan agbegbe kan l'Agege ati ayika re fun odindi wakati meta gbako lola ojo Eti Furaide yii.

Ogbeni Remi Bello to je akowe igbimo ipolongo idibo fun ijoba ibile Agege lo fi bi ilana eto naa yoo se waye to awon oniroyin leti.

Agogo mejo aaro ni ipolongo idibo naa yoo bere ni ofiisi abenugan ile igbimo asofin Eko, iyen Olola julo Onorebu Mudashiru Ajayi Obasa, ti ipolongo ohun yoo si pari ni dede aago mokanla owuro lojo kan naa.

Idi pataki ti awon omo igbimo ipolongo idibo yii se fee lati lo moto fun ikede ipolongo won ko ju pe, won ko fe di igboke-gbodo eto oro aje awon araalu lowo ni won se fee fi tito-lowoowo pelu moto se ipolongo won.

Olukede.

Igbimo iponlogo egbe APC l'Agege ati Orile-Agege

Iroyin Ayo! Ayeye ajoyo 'Agege day' wole deLana ode oni ni awon omo igbimo to n se agbateru aseyori ayeye ajoyo ilu 'Age...
07/12/2022

Iroyin Ayo! Ayeye ajoyo 'Agege day' wole de

Lana ode oni ni awon omo igbimo to n se agbateru aseyori ayeye ajoyo ilu 'Agege day' ko awon oniroyin ilu Eko jo sinu ogba Kansu ijoba ibile Agege lati bawon soro lori awon ilana ati eto bi ose ayeye ajoyo ilu Agege naa yoo ti lo.

Onorebu Afolabi Ayantayo to je Olugbani-nimoran fun gomina ipinle Eko, iyen Babajide Olusola Sanwo-wo to je alaga awon omo igbimo naa dupe gidigan lowo awon oniroyin to wa nijokoo pelu awon eeyan pataki to wa nibe.

Leyin ti Onorebu Afolabi so itan bi ilu Agege se bere ati ibi to de bayii pelu idagbasoke to ba Agege nipase okan pataki to je omo Agege, iyen Abenugan ninu ile igbimo asofin ipinle Eko, iyen Onorebu Mudashiru Ajayi Obasa ati iranlowo gomina ipinle Eko, Babajide Olusola Sanwo-wo to ti mu ayipada nla ba Agege.

Agba oloselu naa so pe, pataki nnkan to mu kawon fe se ayeye ajoyo ilu Agege naa ko ju mimu ife, isokan ati lati je kawon eeyan ilu naa mo nipa itan ilu Agege olojo pipe ati ewa re.

Onorebu Ayantayo wa so pe, adura ni ilana esin Musulumi ododo yoo waye ninu Mosalasi Morikaasi nibi ti eto ayeye ajoyo ilu Agege naa yoo ti bere ni ojo Eti Furaide, Kerindonlogun osu Kejila yii, ti adura nilana awon omo Elesin Igbagbo yoo waye ninu ijo St. Saviour's African Church to wa ni opopona Old Abeokuta Motor Road niluu Agege ni ojo Isinmi Aiku Sande, Kokandinlogun osu Kejila yii.

Eto ikowojo milionu lona Eedegbeta naira (N500,000,000) fun owo iranlowo eto eko l'Agege ni yoo je asekagba gbogbo ayeye naa. Olorin ti yoo forin da awon eeyan laraya ni Oluaye Fuji, Wasiu Ayinde Marshal ni ojo Kejilelogun, osu Kejila yii ninu papa igba boolu ni Agege.

Bee ni, awon idije lorisirisi wa nile fun awon to ba fee kopa, e le kan si awon omo igbimo eto ayeye ajoyo ilu Agege naa ninu ogba Kansu ijoba ibile Agege fun ekunrere alaye.

IROYIN AGEGE

Oni l'ọjọ ibi abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, iyẹn Ọnọrebu Mudashiru Ajayi Obasa. Apibatide sa lati ile iṣẹ ÌRÒYÌ...
11/11/2022

Oni l'ọjọ ibi abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, iyẹn Ọnọrebu Mudashiru Ajayi Obasa. Apibatide sa lati ile iṣẹ ÌRÒYÌN AGÉGE.

Ọna abawọle to wọ agọ ọlọpaa Ẹlẹrẹ ree ni biriiji Pensiniima Agege niyi lẹyin arọda ojo ọsan yii.
09/11/2022

Ọna abawọle to wọ agọ ọlọpaa Ẹlẹrẹ ree ni biriiji Pensiniima Agege niyi lẹyin arọda ojo ọsan yii.

Isọ oru agbaayanu ọlọjọ mẹta t'Ijọ 'PRAYER LIFE SOLUTION MINISTRY' yoo waye lọsẹ yiiIsọ oru ọlọjọ mẹta ti ijọ Prayers li...
08/11/2022

Isọ oru agbaayanu ọlọjọ mẹta t'Ijọ 'PRAYER LIFE SOLUTION MINISTRY' yoo waye lọsẹ yii

Isọ oru ọlọjọ mẹta ti ijọ Prayers life solution ministry ti wọn maa n ṣe losoosu yoo tun waye lọsẹ yii bẹrẹ ni Ọjọruu Wẹside ọjọ Kẹsan-an di ọjọ Kẹtala Ẹti Furaide oṣu Kọkanla ọdun yii.

Gbogbo ọsẹ keji osoosu ni eto adura pataki yii maa n waye nibi ti Ọlọrun Wolii Samuel Oyinloye ti maa n ṣiṣẹ idande, itusile, ti awọn oniruuru alaisan ti maa n ri iwosan gba.

E darapọ mọ isọ oru ti oṣu yii ti yoo bẹrẹ ni Ọjọruu Wẹside ọsẹ yii. Ẹ wa gba ibukun yin pada eyi ti awọn ọta yin ti gba lọwọ yin lọjọ pipẹ.

Akori isọ oru ti oṣu yii ni wọn pe ni 'Divine Restoration' (IDAPADA LAT'ỌRUN).

Awọn gbajugbaja olorin ẹmi naa wa ti yoo dari awọn eeyan lati pe ẹmi Ọlọrun Sọkalẹ ninu isọ oru naa nipasẹ ẹbun orin wọn.

Gbogbo eeyan ni wọn pe sinu adura pataki yii, e tete maa bọ fun itusilẹ ti'yin lati ọdọ Jesu Kristi.

Ijọ naa wa ni ojule 54, Capitol road, car wash bus stop, Agege Lagos.

Lẹyin t'ẹgbẹ agbabọọlu Aston Villa pakuta si gaari Manchester*Niwọn ba tun gbe omi ewuro fun won lati mu un
06/11/2022

Lẹyin t'ẹgbẹ agbabọọlu Aston Villa pakuta si gaari Manchester

*Niwọn ba tun gbe omi ewuro fun won lati mu un

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal f'omi iya wẹ fun Chelsea lọsan-an Sande*Lawọn alatilẹyin Chelsea ba n wo rakọrakọ bi egbere ti wọ...
06/11/2022

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal f'omi iya wẹ fun Chelsea lọsan-an Sande

*Lawọn alatilẹyin Chelsea ba n wo rakọrakọ bi egbere ti wọn ji ẹni rẹ gbe sa lọ

Oriire nla! Won fami eye pataki da J. S. Babatunde, Alaga ijoba ibile idagbasoke Orile-Agege lolaNibi eto ipejopo pataki...
05/11/2022

Oriire nla! Won fami eye pataki da J. S. Babatunde, Alaga ijoba ibile idagbasoke Orile-Agege lola

Nibi eto ipejopo pataki ti awon odo ile Adulawo Afirika, ti won pe ni "Africa Youth Day Conference" ni won ti fami eye omo ile Adulawo Afirika to yege julo, iyen "African Achievers Award" da alaga J.S Babatunde lola pe, oun lo tayo julo laarin awon alaga ijoba ibile to wa ni ekun iwo-oorun Naijiria fun nipa riro awon odo lagbara, to si n mu idagbasoke bawon ni ijoba ibile idagbasoke re l'Orile-Agege l'Ekoo.

Nigba ti alaga naa yoo soro lori ami eye naa, o so pe, oore-ofe nla loun ri gba fun ami eye yii bi won foun, to si loun mo-on loore lodo awon to gbe eto naa kale.

Alaga J.S. Babatunde so pe, bo tile je pe oun ki i se eni to feran lati maa polongo iru eye bayii, o so pe, ami eye ti won foun je abajade ise takuntakun ti oun se ati awon ise ironilagbara toun n se fun awon odo nijoba ibile idagbasoke Oríle-Agege oun.

J.S. so pe, oun gbe awon eto kan kale ni ijoba ibile idagbasoke Orile-Agege, ninu eyi ti awon odo ti kopa ninu awon ironilagbara gbigba owo ogorun-un naira losoosu, ti isejoba oun n fun awon eeyan ni woodu kaakiri ijobo ibile idagbasoke Oríle-Agege, ti oun si n sa gbogbo ipa ati igbiyanju oun lati fopin si aisise nipa boun se n da awon ohun amayederun sile kiri bayii ati ile ero igbalode ICT
sile ni gbogan ekoni to wa ni Powerline, ti igbese naa si ti n so eso rere.

Babatunde ti wa fi da awon eeyan ijoba ibile idagbasoke re loju pe, awoodu naa toun gba je koriya ti yoo je ki oun tun tesiwaju ninu ise ribiribi ti oun n se, o ni ko wa ni je awon odo nikan ni yoo je anfaani naa sugbon gbogbo eka yooku ni ijoba ibile idagbasoke Oríle-Agege.

Alaga J.S Babatunde yii, to tun je pasito wa dupe lowo igbakeji re, iyen Onorebu Kafilat Akanni-Pedro, o dupe lowo awon asofin ijoba ibile idagbasoke re, o dupe lowo awon omo igbimo amusese ati gbogbo awon alabaasisepo re fun ipa ti gbogbo won ko ninu aseyori toun se yii nitori o ni ise ijoba ibile idagbasoke Orile-Agege toun gba ami eye lori e, ki i se nnkan to see da'se laisi won.

Agbátẹrù ìròyìn! ̀_ẹgbẹ́_ọ̀dọ́_AgégeÀwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ìlú Agége ni wọ́n pe ètò pàtàkì kan tí yóò wáyé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ yìí...
04/11/2022

Agbátẹrù ìròyìn!

̀_ẹgbẹ́_ọ̀dọ́_Agége

Àwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ìlú Agége ni wọ́n pe ètò pàtàkì kan tí yóò wáyé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ yìí ní "Ìpéjọpọ̀ ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Agége fún àwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress".
Àwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ìlú Agége yìí sọ pé, àwọn gbé ètò pàtàkì yìí kalẹ̀, tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní "Ọbásá Youth Crusade" láti fi ṣàtìlẹyìn fún àwọn olùdíje tó ń jáde lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú "All Progressive Congress" iyẹn APC bíi Asíwájú Bọ́lá Ahmed Tinubu tó ń díje-dupò ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yìí lọ́dún 2023, gómínà Babájídwé Olúṣọlá Sanwó-olú to fẹ́ẹ́ dupò náà láti ṣe gómìnà sáà Kejì l'Ékòó, Olùdíje sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó ti Agége kìn-ín-ní (01) lọ́dún 2023, tó sì jẹ́ abẹnugan ìyẹn sípíkà nílé ìgbìmọ̀ náà lọ́wọ́ lásíkò yìí, Ọ́nọ́rébù Múdàṣírù Àjàyí Ọbásá, Olùdíje sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó ti Agége Kejì (02) lọ́dún 2023, ìyẹn alága ìjọba ìbílẹ̀ Agége nígbàkan rí, Ọnọrébù Jubreel Abdulkareem Ayọ̀déjì, Dókítà Délé Ahmed tó ń dupò ile ìgbìmọ̀ aṣojúsòfin kéreré ti ìjọba àpapọ̀ l'Ábujá àti àgbà olóṣèlú obìnrin, ìyẹn Dókítà Ídíyátù Olúrántí Adébulé tó ń dupò aṣojúsòfin àgbà, ìyẹn ipò Sẹ́nétọ̀ ẹkùn ìwọ̀-oòrùn ìpínlẹ̀ Èkó l'Ábujá.

Ọjọ́ Àbámẹ́ta Sátidé ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ yìí ni ètò náà yóò wáyé ní pápá ìseré bọ́ọ̀lù-ẹlẹ́sẹ̀ tó wà nílùú Agége ní dédé agogo mẹ́wàá òwúrọ̀ lètò ọ̀hún yóò bẹ̀rẹ̀.
Gbogbo ọ̀dọ́ ìlú Agége pátápátá ni wọ́n pè síbẹ̀.

Ibi tí iṣẹ́ dé dúró ní afárá bííjì Pen-cinema ní ìsọ̀kalẹ̀ sí apá Òkè-kòtò tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ń ṣe lọ́wọ́ l'Ágége rèé....
03/11/2022

Ibi tí iṣẹ́ dé dúró ní afárá bííjì Pen-cinema ní ìsọ̀kalẹ̀ sí apá Òkè-kòtò tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ń ṣe lọ́wọ́ l'Ágége rèé. Ẹ kí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó kúusẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́.

Ijọba Sanwo-Olu bẹrẹ iṣẹ atunṣe opopona Oke-koto l'AgegeỌjọ Aje Monde ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹwaa ọdun yii ...
27/10/2022

Ijọba Sanwo-Olu bẹrẹ iṣẹ atunṣe opopona Oke-koto l'Agege

Ọjọ Aje Monde ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹwaa ọdun yii ni ijọba ipinlẹ Eko ti gomina Babajide Olusọla Sanwo-Olu n dari rẹ lasiko yii bẹrẹ iṣẹ atunṣe oju ọna orita mẹrin Oke-koto niluu Agege.

Opopona orita mẹrin Oke-koto Agege yii lo ti n fun awọn awakọ ati awọn onrinsẹ mi-in ni ẹfọri bo ṣe jẹ pe, omi agbara maa n korajo soju ọna naa, to si maa n fa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ati idaduro ọlọpọ akoko.

Oju ọna yii ṣe pataki fun awọn araalu pẹlu bo se le jẹ ki irinajo awọn ero gbogbo to n bọ lati agbegbe Abule-Egba, Ọgba, Iju-Iṣaga, Iyana-Ipaja ati bẹẹ bẹẹ lọ to fẹẹ gba Agege lọ siluu Ikẹja ati Oṣodi ya kankan.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣe Iroyin Agege ti lọ ṣabewọ si Oke-koto naa, ti awọn ileeṣẹ ti wọn gbe kọntiraati iṣẹ atunṣe ọhun fun ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu.

Iroyin Agege n jẹ ki ẹ mọ bayii wi pe, oju ọna orita mẹrin Oke-koto kò ṣee gba lasiko yii nitori iṣẹ atunṣe to n lọ lọwọ nibẹ sugbọn awọn ọna mi-in wa ti awọn awakọ le pẹ ọna ya si lati maa ba tiwọn lọ.

Nigba ti ileeṣẹ wa kan si awọn asoju ijọba ipinlẹ Eko, wọn jẹ ko ye wa pe, iṣẹ atunṣe oju ọna naa ko ni gba akoko rara ti wọn yoo fi pari ẹ nitori o jẹ ọna gboogi ti kalọ-kabọ igbokegbodo mọto maa n rin nigbogbo igba.

23/10/2022

O ga o! E wo bi baba agbalagba se be s**o Osa l'Ekoo nitori gbese

Address


Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Iroyin Agege posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Videos

Shortcuts

  • Address
  • Alerts
  • Videos
  • Claim ownership or report listing
  • Want your business to be the top-listed Media Company?

Share