Gbagede Iroyin

  • Home
  • Gbagede Iroyin

Gbagede Iroyin Gbagede Iroyin ni a gbekale lati mu awọn iroyin alailẹgbẹ tio se gbẹkẹle wa fun ọ, aw?

New Year, New Goals, Achieving ur set goals this year would require Consistency.Here is great opportunity that helpshttp...
22/01/2023

New Year, New Goals, Achieving ur set goals this year would require Consistency.Here is great opportunity that helps
http://bitly.ws/zbe6
IF U ARE ELIGIBLE U WILL BE REACHED

A Non-governmental Initiative that helps people live the good life in a fast changing economic landscape. We offer Lifestyle, Cash flow generation and Creating Millionaires.

Are u determined,  Passionate, Ambitious, Business minded and ready to get your plans and goals for 2023 achieved?Don't ...
20/01/2023

Are u determined, Passionate, Ambitious, Business minded and ready to get your plans and goals for 2023 achieved?

Don't wait any longer, kickstart ur year with the move and decision that will make ur long awaited ambition come to realization.

Kindly click on the link then u are good to go
https://docs.google.com/forms/d/e/1FAIpQLSchGPBxKopf2DHvb5DLh2y_D3A5V1akVGeovtyergsYNbQ9lg/viewform?usp=pp_url
IF U ARE ELIGIBLE U WILL BE REACHED

A Non-governmental Initiative that helps people live the good life in a fast changing economic landscape. We offer Lifestyle, Cash flow generation and Creating Millionaires.

*📡LARA AWON AKORI IROYIN FUN TONI📡*https://chat.whatsapp.com/DQVtZqXfLAl2waD3K8e2SOhttps://www.facebook.com/gbagedeiroyi...
21/11/2022

*📡LARA AWON AKORI IROYIN FUN TONI📡*

https://chat.whatsapp.com/DQVtZqXfLAl2waD3K8e2SO

https://www.facebook.com/gbagedeiroyin/

*Awọn gomina PDP marun-un faake kọri: A o ni i ṣiṣẹ fun Atiku o*

*Adeleke fọ̀rọ̀ ìdágbére ńlá ránṣẹ́ sí Oyetola tó ń kó ẹrù rẹ̀ kúrò nílé ìjọba Osun*

*Ikú ṣọṣẹ́! Ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga KWASU jáde láyé*

*Afurasi Obinrin Opo Kan tọju kokeeni sinu bata to n wọ lọ si Mẹka*

*Ẹ bá wa sọ̀rọ̀, ààyè ṣì wà fún ìjíròrò - Àwọn Gómìnà 'G5'*

*Awọn agbebọn to ji aafa at’ọmọ ẹ n’Ilọrin n beere fun ọgọrun-un kan miliọnu*

*Wọ́n yọ olórí ilé aṣòfin Ekiti láì pé ọ̀sẹ̀ kan tó dé ipò*

*Ọ̀tẹ̀ ni Ibadan ń ṣe, kìí ṣe òṣèlú, ló gbé Makinde wọlé gómìnà - Teslim Folarin*

*FIFA WORLD CUP: England ṣẹ̀ṣó ìyà 6-2 fún Iran ní ìfẹsẹ̀wọ́nsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ ní Qatar 2022*

*Ebenezer fibinu fọ agadagodo mọ’yawo ẹ lori, niyẹn gbabẹ ku l’Abẹokuta*

Fun awon iroyin ni ede Yoruba

Darapo mo wa lori

👇👇👇👇
WhatsApp: https://chat.whatsapp.com/DQVtZqXfLAl2waD3K8e2SO

Facebook: https://www.facebook.com/gbagedeiroyin/

WhatsApp Group Invite

*Ebenezer fibinu fọ agadagodo mọ’yawo ẹ lori, niyẹn gbabẹ ku l’Abẹokuta*Ibinu ko mọ p’olowo oun ko lẹsẹ nilẹ.  Beẹ lọrọ ...
21/11/2022

*Ebenezer fibinu fọ agadagodo mọ’yawo ẹ lori, niyẹn gbabẹ ku l’Abẹokuta*

Ibinu ko mọ p’olowo oun ko lẹsẹ nilẹ. Beẹ lọrọ ri fun baale ile ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Oluwaṣẹgun Ọmọtọṣọ Ebenezer, ti ti wa lahaamọ awọn ọlọpaa latari ẹsun pe o fibinu la agadagodo mọ iyawo rẹ, Olubukọla Ọmọtọṣọ, lori nigba ti wọn jọ n ṣe gbolohun asọ, obinrin ẹni ọdun mejilelogoji naa si gbabẹ ku patapata.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lawọn ọlọpaa lọọ fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran naa, nigba ti ẹgbọn oloogbe lọọ fẹjọ ẹ sun ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Kemta, l’Abẹokuta, ipinlẹ Ogun. O ni ọkọ aburo oun ti luyawo ẹ pa nibi ti wọn ti n ja lori ọrọ ti ko to nnkan.

Obinrin naa ni niṣe lọkọ yii la agadagodo nla ti wọn fi n ti geeti ile wọn mọ iyawo rẹ yii lori, ti ori naa si bẹjẹ, lobinrin naa ba mu’dii lọọlẹ.

O lawọn eeyan to wa nitosi ni wọn sare gbe e digbadigba lọ sileewosan ijọba, Federal Medical Centre (FMC), to wa lagbegbe Idi-Aba, l’Abẹokuta. Awọn dokita gbiyanju lati doola ẹmi ẹ, wọn fun un ni itọju pajawiri, ṣugbọn bi wọn ṣe n tọju ẹ lọwọ naa lo mi eemi ikẹyin.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe obinrin naa laju diẹ nigba to wa lọsibitu, wọn ni pẹlu irora naa lo dọgbọn fi ọrọ ranṣẹ sawọn mọlẹbi ẹ kan lori aago pe ọsibitu loun wa bayii o, oun atọkọ oun lawọn n ja to fi la agadagodo mọ oun lori, eyi lo si sọ oun dero ọsibitu, oun o ti i mọ’bi tọrọ naa le ja si o, ṣugbọn to ba fi ja siku, ki wọn mọ pe Ṣẹgun lo pa oun o, oun ni ki wọn beere iku oun lọwọ ẹ.

Kete to pari ifohunranṣẹ ti wọn n pe ni voice note ọhun, to si fi i ṣọwọ, ni wọn lo dakẹ.

Wọn ni bi baale ile ọran yii ṣe gbọ nipa ifohunranṣẹ ọhun nibi to ti n ronu irọ to maa fi bo iwa buruku to hu mọlẹ, o ri i pe aṣiri naa ko bo mọ, niṣe lo ba ẹsẹ rẹ sọrọ, o na papa bora.

Eyi lo mu kawọn ọlọpaa atawọn ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ si i wa a, wọn tọpinpin ibi to le sa pamọ si, iṣẹ gidi si ni DPO teṣan Kemta, SCP Adeniyi Adekunle, atawọn ẹmẹwa rẹ ṣe ki olobo kan too ta wọn pe jagunlabi

*FIFA World Cup**England ṣẹ̀ṣó ìyà 6-2 fún Iran ní ìfẹsẹ̀wọ́nsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ ní Qatar 2022*
21/11/2022

*FIFA World Cup*

*England ṣẹ̀ṣó ìyà 6-2 fún Iran ní ìfẹsẹ̀wọ́nsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ ní Qatar 2022*

*Ọ̀tẹ̀ ni Ibadan ń ṣe, kìí ṣe òṣèlú, ló gbé Makinde wọlé gómìnà - Teslim Folarin*Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣel...
21/11/2022

*Ọ̀tẹ̀ ni Ibadan ń ṣe, kìí ṣe òṣèlú, ló gbé Makinde wọlé gómìnà - Teslim Folarin*

Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo, Oloye Teslim Folarin ni iwọle gomina Seyi Makinde gẹgẹ bii gomina ko ṣeyin bii awọn oloṣelu kan ṣe fọwọsowọpọ lati ṣe ọtẹ gomina ana to ti di oloogbe, Abiola Ajimobi, eyi ti wọn ni awọn fẹ fi fi iya jẹ ẹ.

Folarin ṣalaye awọn ọrọ yii nigba to kopa ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ BBC News Yoruba lori opo ibanidọrẹ Facebook lọsan oni.

O ni awọn oloṣelu kan lo gbimọ pọ pe ki awọn sisẹ pọ pẹlu ọtẹ lati gbe Makinde wọlẹ nitori pe oun lo gba asia ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun naa.

“Ọtẹ ni Ibadan n ṣe, kii ṣe oṣelu, ọtẹ lo gbe Makinde wọle Gomina ipinlẹ Oyo.

“Ifọwọsowọpọ awọn oloṣelu kan lo gbe Makinde wọlẹ nitori wọn ni awọn ko fẹ Ajimobi mọ, ko ki n ṣe pe Makinde ni riri to pọ to bẹ lati ṣe oṣelu.

Makinde n kọ oṣelu lọwọ lo di gomina nitori ibẹẹrẹ oṣelu ni ki awọn eeyan mọ eeyan. Ko mọ bi wọn ṣeṣe pẹlu awọn eeyan to wa ni ẹsẹkuku ati pẹlu awọn alakọwe.

“Ọkan lara awọn fasiti to daraju ni mo lọ, fasiti ilẹ Ibadan ati Havard niluu London sugbọn nigba ti mo pada de, Baba Adedibu ni to ba ṣe oṣelu, o ni lati gbe gbogbo iyẹn si ẹgbẹ kan.

“Makinde o mọ bi wọn ṣe ba awọn eeyan sọrọ ni ẹsẹkuku ati igberiko.

Folarin ni ti a ba wo itan ipinlẹ Oyo, gbogbo awọn to ti jẹ gomina ni wọn bẹrẹ lati ibi kan ki wọn to di gomina ṣugbọn oun ni igbagbọ pe oye Makinde ko kun to.

“Baba Lam jẹ aṣofin, ki wọn to jẹ gomina, Ladoja jẹ sẹnẹtọ, ko to di gomina, Akala jẹ alaga ijọba ibilẹ ati igbakẹji gomina ko to di gomina, Ajimobi naa ṣe sẹnẹtọ ko to di gomina.

“Gbogbo wọn mọ bi wọn ṣe ṣe kini yii ki wọn to di gomina ṣugbọn ti Ọlọrun ba ṣe fẹ ṣe nkan rẹ ni yoo ṣe.”

*Lẹyin ọsẹ kan ti wọn yan an sipo, awọn aṣofin Ekiti yọ olori wọn*Laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn aṣofin bii mẹtad...
21/11/2022

*Lẹyin ọsẹ kan ti wọn yan an sipo, awọn aṣofin Ekiti yọ olori wọn*

Laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn aṣofin bii mẹtadinlogun, ninu awọn mẹẹẹdọgbọn ti wọn wa nile naa, yọ olori ileegbimọ ọhun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lọsẹ to kọja, Gboyega Aribiṣogun, ti wọn si yan Olubunmi Adeluga gẹgẹ bii olori wọn tuntun.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja ni wọn yan Abisogun to jẹ ọmọ bibi ilu Ijẹsa Iṣu Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle, to n ṣoju ẹkun kin-in-ni, ijọba ibilẹ Ikọle, lakooko ijokoo ile naa to waye ni gbọngan ile aṣofin wọn. Ọnarebu Tajudeen Akingbolu to wa lati ẹkun kin-in-ni ijọba ibilẹ Ariwa Ekiti, lo mu aba lati yan aṣofin naa wa, nigba ti Ọnarebu Adegoke Olajide to n ṣoju ẹkun ijọba ibilẹ Ẹfọn, kin in lẹyin. Bakan naa ni Ọnarebu Bọde Adeoye, to n ṣoju ẹkun keji ijọba ibilẹ Iwọ Oorun ipinlẹ Ekiti yan Arabinrin Olubunmi Adelugba, ti Ọnarebu Ojo Matins toun n ṣoju ijọba ibilẹ Ijero gbe e lẹyin.

Eyi lo fa a tawọn aṣofin naa fi dibo, Aribisọgan ni ibo mẹẹẹdogun, to fi fẹyin Adelugba balẹ.

Ṣugbọn l’Ọjọruu, Wẹside, iyẹn ọjọ keji ti iyansipo naa ṣẹlẹ ni wọn ni awọn kan ti wọn jẹ omọlẹyin gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Dokita Kayọde Fayẹmi, ti o si jẹ pe Adelugba ni wọn n ṣatilẹyin fun ya wọn ile-igbimọ naa, ni wọn ba bẹrẹ wahala, wọn ni awọn tọọgi oloṣelu kan fẹẹ dana sun apa kan ile naa nibi tọrọ ọhun le de.

Awọn agbofinro ni wọn tete lọ sibẹ ti wọn si gbakoso gbogbo agbegbe naa, ni wọn ba ti ile naa pa. Eyi ni ko fi ṣee ṣe fun awọn aṣofin naa lati jokoo, ti onikaluku awọn oṣiṣẹ si gba ile wọn lọ. Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, nigba ti awọn aṣofin naa tun pade, ti wọn si yọ Aribisọgan, ti wọn fi Adeugba rọpo rẹ.

Ṣugbọn aṣofin ti wọn yọ nipo naa naka abuku si Dokita Fayẹmi to ṣẹṣẹ kuro nipo gomina, o ni ọkunrin yii lo wa lẹyin bi wọn ṣe yọ oun nipo.

Ko ti i sẹni to mo boya yiyan ti wọn yan Adelugba yii yoo fopin si wahala ile naa.

Tẹ o ba gbagbe, iyansipo yii waye lẹyin iku olori wọn tẹlẹ, Họnọrebu Funminiyi Afuyẹ to ku lọjọ kọkanlelogun, oṣu

*Awọn agbebọn to ji aafa at’ọmọ ẹ n’Ilọrin n beere fun ọgọrun-un kan miliọnu*Awọn agbebọn to ji Aafa Sọfiu, ọmọ rẹ ati ẹ...
21/11/2022

*Awọn agbebọn to ji aafa at’ọmọ ẹ n’Ilọrin n beere fun ọgọrun-un kan miliọnu*

Awọn agbebọn to ji Aafa Sọfiu, ọmọ rẹ ati ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Aliyu, gbe lagbegbe Oko-Olowo, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara ti n beere fun ọgọrun-un kan miliọnu Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, ni awọn agbebọn naa ji awọn mẹtẹẹta gbe lọ nileegbe wọn lopopona Jẹbba, Oko-Olowo, niluu Ilọrin, lẹyin ti wọn yọ irin oju ferese ni wọn raaye wọle, ti wọn si tun fi ọta ibọn da ọgbẹ sara ọmọ Aafa Sọfiu kan ti orukọ rẹ n jẹ Fasasi.

Baba aafa ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si, Imam Amolegbe, ti agbegbe Dada, Okelele, Ilorin, sọ fun awọn oniroyin pe awọn ajinigbe naa ro pe Fasasi ti ku nigba ti wọn yinbọn mọ ọn ni wọn ṣe fi i silẹ, sugbọn awọn mọlẹbi ti gbe e lọ si ileewosan aladaani kan, nibi to ti n gba itọju bayii.

O fi kun un pe wọn ti bẹ awọn ajinigbe naa ki wọn gba miliọnu mẹwaa Naira, bo tilẹ jẹ pe ko si owo ọhun nilẹ bayii. O rọ ijọba Kwara atawọn ẹlẹyinju aanu ki wọn dide iranlọwọ, ki wọn le tu eeyan wọn yii silẹ lahaamọ awọn ajinigbe.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi meji lori iṣẹẹ ọhun, ati pe awọn ti n sa gbogbo ipa lati doola awọn aafa naa.

*Ẹ bá wa sọ̀rọ̀, ààyè ṣì wà fún ìjíròrò - Àwọn Gómìnà 'G5'*Awọn gomina marun un lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn pe ara wọ...
21/11/2022

*Ẹ bá wa sọ̀rọ̀, ààyè ṣì wà fún ìjíròrò - Àwọn Gómìnà 'G5'*

Awọn gomina marun un lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn pe ara wọn ni G5 sẹpade pọ pẹlu awọn igun ẹgbẹ oṣelu ọhun ni ipinlẹ Eko ṣaaju eto idibo ti yoo waye lọdun 2023.

Ipada alatilẹkunmọriṣe naa lo waye ni ile igbakeji alaga ẹgbẹ tẹlẹ, Oloye Bode George, ti wọn si kede pe awọn ti ni orukọ tuntun fun ajọse awọn gomina naa, eyi ti wọn pe ni ‘Integrity Group’.

Bakan naa ni awọn gomina ọhun ṣalaye pe aye si wa fun ijiroro ti yoo fi opin si gbogbo rogbodiyan to n waye lọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu naa.

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Plateau, Jonah Jang ba awọn akọroyin sọrọ pe igun ẹgbẹ yii ti fi aye silẹ fun ijiroro ti yoo fi opin si rogbodiyan inu ẹgbẹ naa.

“A wa ti a wa ni ipade yii ti ṣetan lati duro lori esi ipade wa ni Port Harcourt. A tun wa sọ lẹẹkan sii pe aye wa fun ijiroro to mu alaafia wa ninu ẹgbẹ oṣelu wa.”

*Afurasi Obinrin Opo Kan tọju kokeeni sinu bata to n wọ lọ si Mẹka*Ọwọ ṣinkun ajọ to n gbogun ti iwa gbigbe oogun oloro ...
21/11/2022

*Afurasi Obinrin Opo Kan tọju kokeeni sinu bata to n wọ lọ si Mẹka*

Ọwọ ṣinkun ajọ to n gbogun ti iwa gbigbe oogun oloro nilẹ wa, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti tẹ obinrin opo ẹni ọdun mẹrindinlọgọta (56) kan, Kẹhinde Sidika Ajiṣegiri, lasiko ti obinrin ọlọmọ mẹrin naa n gbiyanju lati gbe egboogi oloro ti wọn n pe ni kokeeni to to iwọn irinwo giraamu (400 grammes) lati Eko lọ siluu Mẹka, lorilẹ-ede Saudi Arabia, lọhun-un.

Ni papakọ-ofurufu Murtala Mohammed, to wa n’Ikẹja, niluu Eko, ni wọn ti mu obinrin yii, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Inu bata rọba dudu to wọ s’ẹsẹ ni wọn fura si pe o gbe oogun oloro naa si, nigba ti ẹrọ to n ṣayẹwo awọn ero to fẹẹ wọ baaluu bẹrẹ si i han gan-an-ranran, eyi to tumọ si pe ẹni naa lẹbọ lẹru. Wọn yẹ gbogbo ara abilekọ yii atẹru rẹ wo, wọn ko ri nnkan kan, ni wọn ba ko bata ẹ sori ẹrọ naa, ibẹ laṣiiri ti tu.

Lẹyin ti wọn da obinrin naa duro, wọn la bata ẹsẹ ẹ mejeeji to wọ si meji, ibẹ ni wọn ti ri lailọọnu meji pelebe to pọn egboogi oloro ọhun si ko too ṣẹṣẹ waa ko o saarin awọn bata naa, o si lẹ ẹ pa mẹrẹnmẹrẹn pada bii pe ọwọ ko kan bata yẹn ri.

Ninu fidio atawọn fọto kan ti Alukoro ajọ NDLEA, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, fi lede lori iṣẹlẹ yii ni wọn ti ṣafihan bi akara iwa ọdaran yii ṣe tu sepo, tọwọ si ba a. Ṣe ẹni to ba mọ nnkan i fi pamọ gbọdọ ranti ẹni ti mọ nnkan i wa dori okodoro.

Afurasi ọdaran to pe ara ẹ ni oniṣowo yii sọ pe aṣọ ati bata agbalagba ati tọmọde loun n ta ninu ọja Idumọta, l’Ekoo, ati pe ọja loun fẹ lọọ ra lorilẹ-ede Saudi toun n lọ, oun si tun fẹẹ de Mẹka, lati ṣe isin mimọ f’Ọlọrun.

Wọn niwadii ṣi n tẹsiwaju, ati pe laipẹ ni wọn yoo foju afurasi naa ati egboogi to lẹ mọ bata ọhun bale-ẹjọ, ko le lọọ fimu kata ofin.

Olori ajọ NDLEA, Mohammed Buba Marwa, ti gbe oṣuba sadankata fawọn ọmọ abẹ ẹ fun iṣẹ takuntakun ati ilakaka wọn lati fopin si iwa gbigbe egboogi oloro nilẹ yii.

*Ikú ṣọṣẹ́! Ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga KWASU jáde láyé*Ọga agba ile ẹkọ giga Fasiti ti ipinlẹ Kwara (KWASU), Ọjọgbọn Musta...
21/11/2022

*Ikú ṣọṣẹ́! Ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga KWASU jáde láyé*

Ọga agba ile ẹkọ giga Fasiti ti ipinlẹ Kwara (KWASU), Ọjọgbọn Mustapha Akanbi ti dagbere faye.

Ọkan lara awọn alakoso ile ẹkọ naa, Arabinrin Kikelomo Salle lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku.

Atẹjade naa ṣafihan pe lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ ni Ọjọgbọn Akanbi fi aye silẹ.

“A rọ gbogbo eniyan lati ranti idile oloogbe ati Fasiti to fi silẹ ninu adura lasiko yii”.

Salle sọ pe wọn yoo ṣagbejade gbogbo bi eto isinku yoo ṣe lọ.

*Ta ni Ọjọgbọn Mustapha Akanbi?*

A bi oloogbe Ọjọgbọn Mustapha Akanbi si idile Adajọ agba Muhammed Mustapha Adebayo Ajao Akanbi ati Alhaja Munfaatu Aduke Akanbi.

Ile Magaji Kemberi, Awodi lagbegbe Gambari ni Ilorin lo ti wa. Akanbi kawe akọbẹrẹ ati girama kaakiri awọn ipinlẹ Naijria bii Kano, Porthacourt, Ibadan ati Imo.

Fasiti Obafemi Awolowo ni Akanbi ti kawe gboye ninu imọ ofin lọdun 1993.
Ọpọlọ afikun iwe ati oye ni Mustapha Akanbi ti gba to si ṣiṣẹ kaakiri fasiti t**i to fi gba ipo Ọga agba Fasiti ipinlẹ Ilorin, KWASU nibi to wa t**i ti ọlọjọ fi de.

*Adeleke fọ̀rọ̀ ìdágbére ńlá ránṣẹ́ sí Oyetola tó ń kó ẹrù rẹ̀ kúrò nílé ìjọba Osun*Gomina tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan n...
21/11/2022

*Adeleke fọ̀rọ̀ ìdágbére ńlá ránṣẹ́ sí Oyetola tó ń kó ẹrù rẹ̀ kúrò nílé ìjọba Osun*

Gomina tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti rọ Gomina to ti fẹ kogba wọle, Gboyega Oyetola pe ko gba kamu pe o ti lulẹ ninu eto idibo gomina to waye ni oṣu Keje, pe ko si simi ariwo ni p**a.

Agbẹnusọ Adeleke, Olawale Rasheed ninu atẹjade to fi ransẹ si Oyetola lẹyin to kede pe oun yoo gba ẹtọ oun, ni pe ko si ẹtọ kankan to fẹ gba lọwọ Adeleke nitori gbogbo ọna ni o fi fi idi rẹ janlẹ ninu eto idibo gomina to waye nipinlẹ Osun.

O ni erongba buburu ni Oyetola ni si awọn eeyan ipinlẹ Osun latari bi o ṣe n fi irọ ati ailotọ ṣe ijọba rẹ.

Adeleke ni kete ti Oyetola ri pe oun ti lulẹ ni o ti bẹrẹ si ni maa ṣe owo ipinlẹ naa basubasu sugbọn ti ile ẹjọ si ti tu ọpọlọpọ irọ ti Oyetola pa fun awọn eeyan.

O mọ pe o ti n lọ, o wa bẹrẹ si ni maa ṣe owo ilu basubasu, o n dẹ pakute fun eeyan ipinlẹ Osun ni.

“O le gun akaso lati maa tan awọn alatilẹyin rẹ ti ẹ jọ ṣe ijọba basubasu

“Nnkan ti a ni lati ba iwọ ati awọn ẹmẹwa rẹ sọ ree. Ọsẹ yii loku fun ẹ ninu ile ijọba. Ko gbogbo nnkan too ba fẹ.

“Sugbọn a fẹ koo mọ pe gbogbo awọn too yan, ti ẹ jọ sisẹ pọ lati ṣe owo ilu basubasu ni yoo fi oju ba ofin.”

*Awọn gomina PDP marun-un faake kọri: A o ni i ṣiṣẹ fun Atiku o*Ẹkọ o ti i ṣoju mimu ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic ...
21/11/2022

*Awọn gomina PDP marun-un faake kọri: A o ni i ṣiṣẹ fun Atiku o*

Ẹkọ o ti i ṣoju mimu ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, paapaa laarin awọn agbaagba ẹgbẹ naa loke, pẹlu bawọn gomina marun-un tinu n bi, atawọn alatilẹyin wọn ko ṣe ti i yi ipinnu wọn pada t**i di ba a ṣe n sọ yii lori bi ọn ṣe ni aọn ko ni i ṣatilẹyin fun oludije wọn, Alaaji Atiku Abubakar lasiko ibo ọdun to n bọ. Arọni o wale, onikoyi o sinmi ogun, lọrọ naa da laarin wọn, bẹẹ si lọkan awọn ọmọ ẹgbẹ ko balẹ, tori wọn ni airinpọ lo n jẹ ọmọ ejo niya.

Nibi ipade pataki kan to waye laarin awọn gomina ipinlẹ maraarun ọhun ti wọn n jẹ (G-5) ti wọn ya ara wọn sọtọ pe awọn ko ni i ba Atiku ṣe, ti ko ba yọ alaga ẹgbẹ naa, Iyorchia Ayu, ko si fi ẹlomi-in to wa lati iha Guusu orileede yii rọpo rẹ, gẹgẹ bii adehun ti wọn jọ ṣe, lọrọ yii ti jẹ yọ.

Awọn gomina ọhun ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ti ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ti ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, Gomina ipinlẹ Enugu, Ifeanyi Ugwuanyi ati Gomina ipinlẹ Abia, Victor Ikpeazu.

Lara awọn mi-in ti wọn fara mọ ipinnu awọn gomina marun-un yii ti wọn si pesẹ sipade naa ni gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹri, Oluṣẹgun Mimiko, ti Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, ti Cross-River nigba kan, Donald Duke atawọn eekan eekan ẹgbẹ PDP lati iha Guusu lọhun-un.

Igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ naa tẹlẹ, Oloye Ọlabọde George lo gba wọn lalejo, otẹẹli Southern Sun, iyẹn Ikoyi Hotel atijọ, nipade naa ti n waye.

Lopin ipade, wọn ko mu atẹjade kankan jade, amọ Mimiko ati Wike to ba awọn ọmọ ẹgbẹ PDP sọrọ sọ pe awọn maa ṣiṣẹ fun gbogbo awọn oludije ẹgbẹ naa, bẹrẹ latori gomina, sẹnetọ atawọn ipo yooku latoke delẹ, ṣugbọn ko mẹnu ba oludije funpo aarẹ, tabi Atiku.
Ọrọ yii ko tẹ ọpọ awọn ero to pẹjọ naa lọrun rara, ọpọ wọn lo si fi aidunnu wọn han si iṣẹlẹ naa.

*Awa jagunjagun ibilẹ le daabo bo ilu wa ju awọn agbofinro ijọba lọ-Ọmọlubi*Nitori eto aabo to mẹhẹ lorileede yii, paapa...
20/11/2022

*Awa jagunjagun ibilẹ le daabo bo ilu wa ju awọn agbofinro ijọba lọ-Ọmọlubi*

Nitori eto aabo to mẹhẹ lorileede yii, paapaa, nitori laasigbo ti ẹya ajeji n da silẹ, ti wọn n ji awọn ọmọ Yoruba gbe, ti wọn si n pa wọn nipakupa nilẹ baba wọn, awọn ẹya Itsekiri, nipinlẹ Delta, lawọn ti ṣetan lati ran iran Yoruba lọwọ.

Olori ikọ ọmọ-ogun ibilẹ ẹya Itsekiri, Oloye Ọmọlubi Newuwum lo fidi igbesẹ yii mulẹ nibi ipade apero eto aabo kan ti gbogbo agbarijọ awọn eleto aabo ibilẹ nilẹ Yoruba ṣe ninu gnọngan nla ileetura Kakanfo Inn, n’Ibadan, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla yii.

Gẹgẹ bi Oloye Ọmọlubi ṣe sọ, ‘Gbogbo wa la mọ pe awọn Fulani ati ilana ti a n gba ṣeto ijọba lorileede yii lo n dena ilọsiwaju ilẹ Yoruba, idi ree ta a ṣe gbọdọ para pọ lati sa ipa wa lati gba ara wa silẹ lọwọ awọn ọta wa.

O daa bi wọn ṣe da Amotekun silẹ nilẹ Yoruba. Awa naa da iru ẹ kan silẹ lọdọ wa ta a pe ni Agbokomasaa. Awa ta a jẹ jagunjagun ibilẹ le daabo bo ilu wa ju agbofinro ijọba apapọ lọ nitori awọn yẹn ko mọ agboole, aarin ilu ati inu igbo wa to wa”.

Apapọ awọn to kopa ninu apero nla ọhun to ẹgbẹrun meji (2,000) niye. Ninu ninu wọn la ti ri oriṣiiriṣii ikọ eleto aabo ibilẹ Yoruba bii O.P.C., Agbẹkọya, fijilate, ẹgbẹ awọn ọdẹ ibilẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Nigba to n ṣalaye idi ti wọn ṣe pejọ bẹẹ, Ọmọwe Victor Taiwo, ẹni to ṣagbatẹru ipade ọhun, ṣalaye pe nnkan mẹta lo jẹ iṣoro ẹya Yoruba, aisi eto aabo, iṣọkan ati ominira, ati pe bi ko ba si iṣọkan ati aabo, niṣe lawọn ọta yoo maa fiya jẹ ẹya Yoruba, wọn ko si ni i le ni ominira lati bọ ninu iya naa laelae.

Ninu ipade alagbara ọhun ni wọn ti gbe igbimọ majẹẹ-o-bajẹ kan kalẹ lati maa dari awọn agbofinro ibilẹ Yoruba ti wọn ko jọ wọnyi pẹlu itọju ati ipese ohun eelo ti wọn yoo maa fi koju awọn afẹmiṣofo ati oniruuru awọn ọdaran gbogbo.

Ninu igbimọ ọhun, eyi to ko gbogbo ẹka igbesi aye ọmọniyan sinu, la ti ri Oṣilẹ ti Oke-Ọna nipinlẹ Ogun, Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo, gẹgẹ bii olori igbimọ fun ọrọ awọn lọbalọba; Ọmọwe Bayọ Orire gẹgẹ b

*Awọn gomina ẹgbẹ PDP marun-un (G-5) wọle ipade l’Ekoo*Ba a ṣe n kọ iroyin yii, ipade pataki kan n lọ lọwọ laarin awọn g...
20/11/2022

*Awọn gomina ẹgbẹ PDP marun-un (G-5) wọle ipade l’Ekoo*

Ba a ṣe n kọ iroyin yii, ipade pataki kan n lọ lọwọ laarin awọn gomina ipinlẹ marun-un kan lati inu ẹgbẹ PDP ti wọn n jẹ (G-5) ti wọn ya ara wọn sọtọ pe awọn ko ni i ba oludije sipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar, ṣe ti ko ba yọ alaga ẹgbẹ naa, Iyourchi Ayu, ko si fi ẹlomi-in to wa lati iha Guusu si i gẹgẹ bii adehun ti wọn jọ ṣe.

Awọn gomina ọhun ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ti ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, Gomina ipinlẹ Enugu, Ifeanyi Ugwuanyi ati Gomina ipinlẹ Abia, Victor Ikpeazu. Awọn eeyan wọnyi ni wọn ti n yẹra fun ipolongo ibo oludije wọn funpo aarẹ wọn, ti wọn ni awọn ko ni i ni nnkan kan an ba a ṣe nitori ko tẹle adehun ti awọn jọ ṣe pe ti oludije funpo aarẹ ba ti wa lati Ariwa, lati Guusu ni alaga yoo ti wa, bẹẹ ni Ayu ṣeleri pe bi ọrọ ba ri bẹẹ, oun yoo fi ipo oun silẹ. Ṣugbọn ti ọkunrin naa kọ lati ṣe bẹẹ.

Otẹẹli Southern Sun, iyẹn (Ikoyi Hotel), atijọ ni ipade naa ti n waye.

Awọn gomina maraarun yii atawọn agbaagba ẹgbẹ mi-in ni wọn peju sibi ipade to ṣi n lọ lọwọ naa, nibi ti wọn ti fẹẹ fi ipinnu wọn han lori eto idibo ọdun to n bọ ati igbesẹ to ṣee ṣe ki wọn gbe lori rẹ.

*Adigunjale kọ lẹta si wọn laduugbo Ologunẹrun, n’Ibadan, wọn lawọn yoo ba wọn lalejo nipari oṣu yii*Inu ibẹrubojo ni aw...
20/11/2022

*Adigunjale kọ lẹta si wọn laduugbo Ologunẹrun, n’Ibadan, wọn lawọn yoo ba wọn lalejo nipari oṣu yii*

Inu ibẹrubojo ni awọn eeyan adugbo Ifẹlagba, Adetokun, Ologun Ẹru, to wa ni Idi-Ọsan, nijọba ibilẹ Iddo, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ wa bayii.

ko sẹni to le sun oorun asun-diju ninu wọn. Ohun to fa aisun ojiji yii ni bi awọn adigunjalẹ ṣe kọ lẹta si wọn pe awọn n bọ waa ba wọn lalejo o, ki wọn maa reti awọn nipari oṣu Kọkanla yii.

Awọn eeyan adugbo naa ni wọn sọ eyi di mimọ fun awọn oniroyin. Ninu lẹta naa, eyi ti awọn adigunjale naa lẹ kaakiri awọn ile to wa ni adugbo ọhun ni wọn ti kọ ọ pe ki awọn eeyan adugbo yii maa mura awọn silẹ o, nitori awọn n bọ waa digun ja wọn lole nipari oṣu Kọkanla yii. Wọn fi kun un pe ki wọn ma wulẹ daamu ara wọn pe awọn n gbọkan le awọn ọdẹ adugbo yii o. Wọn ni awọn maa kapa awọn ọdẹ yii, ti awọn si maa ṣe wọn bi ọṣẹ ṣe n ṣe oju nitori awọn ni wọn ti n di awọn lọwọ lati ṣe iṣẹ ibi ti awọn fẹẹ ṣe ni adugbo naa latọjọ yii.

Latigba ti awọn eeyan agbegbe naa ti ri awọn iwe ti wọn le kaakiri yii ni wọn ti wa ninu ibẹru, aya wọn n ja gidigidi, ọkan wọn ko si balẹ.

Ọkan ninu awọn agbaagba agbegbe naa to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe awọn ti n gbe igbesẹ lori ohun ti wọn kọ naa, ṣugbọn awọn ko fẹẹ sọ igbesẹ ti awọn n gbe jade nitori ọrọ to ni i ṣe pẹlu eto aabo ni.

*Ọkùnrin kan ṣekúpa ìyá ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn tí ìyá ká níbi tó ti ń ba àbúrò ìyàwó rẹ̀ sún*Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ ọkunr...
20/11/2022

*Ọkùnrin kan ṣekúpa ìyá ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn tí ìyá ká níbi tó ti ń ba àbúrò ìyàwó rẹ̀ sún*

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ ọkunrin kan, ẹni ọdun mejidinlogoji fun ẹsun pe o ṣekupa iya iyawo rẹ ati ẹlomiran to ri igba to ṣe isẹ ibi naa ni agbegbe Akodo nipinlẹ Eko.

Ọkunrin ọhun ni iya iyawo rẹ ri nibi to ti n ba aburo iyawo rẹ, ọmọ ọdun mẹrinla sun, eyi lo sokunfa idi to gba ẹmi obinrin naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lo kede isẹlẹ naa lori opo ayelujara rẹ, Twitter ni Ọjọ Satide.

Gẹgẹ bii Hundeyin ṣe salaye, o ni kete ti ọkunrin naa ri pe Iya iyawo ọhun ti ri oun nibi to ti n ba aburo iyawo rẹ ni ibalopọ lo gbemi rẹ, to si tun pa ẹlomiiran to ri nigba to ṣekupa iya iyawo rẹ.

“Ni agbegbe kan ni Akodo, ọkunrin kan, ẹni ọdun mejidinlogoji ṣekupa iya iyawo rẹ, to si tun ṣekupa ẹlomiiran to ri nigba to ṣe isẹ ọhun.

“O ti wa ni ahamọ wa bayii. Iwadi ti fihan pe o gbe igbesẹ naa lẹyin to ri pe iya iyawo ti ri oun nibi to ti n ba aburo iyawo, ẹni ọdun mẹrinla sun.

“Ẹjọ naa ni a ti gbe lọ ileeṣẹ ọlọpaa to n risi iwa ọdaran lati tẹsiwaju ninu iwadii.”

*Mo mo daju, èmi ni mo borí ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Osun – Oyetola*Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola, ti fi ogun re gbari...
20/11/2022

*Mo mo daju, èmi ni mo borí ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Osun – Oyetola*

Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola, ti fi ogun re gbari pe oun yoo gba ẹtọ oun lọwọ gomina tuntun, Ademola Adeleke, nile ẹjọ.

Oyetola sọ eleyi nigba darapọ mọ awọn araalu nibi ayẹyẹ Iragbiji ni ijọba ibilẹ Boripe, o ni o da oun loju pe oun bori eto idibo gomina to waye ninu oṣu keje ọdun yii.

O tẹsiwaju pe oun yoo tun pada wa ba awọn eeyan ijọba ibilẹ Boripe ṣe ajọyọ gẹgẹ bii gomina lọdun to n bọ.

“Ni agbara Ọlọrun, Insha Allah, ma tun wa bayin ṣe ajọyọ yii lọdun to n bọ gẹgẹ bii gomina.

“O da mi loju, ko si aniani pe ma gba ẹtọ mi lọwọ wọn.”

Ajọ eleto idibo nilẹ wa kede esi idibo gomina nipinlẹ Osun to waye lọjọ Satide, ọjọ Kẹrindinlogun osu Keje ọdun 2022.

Ajọ INEC ni Sẹnatọ Ademola Adeleke tii se oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP lo bori idibo ọhun.

Adeleke lo ni apapọ ibo 403,371 eyi to mu ko fi ẹyin gomina to wa lori aleefa janlẹ, eyiun Adegboyega Oyetola.

*People are the most important resource in the world* 💪💪💪💪 *The power of the people is much stronger than the people in ...
25/07/2022

*People are the most important resource in the world* 💪💪💪💪
*The power of the people is much stronger than the people in power*
✊✊✊✊✊✊✊
_As people of this great Nation, it's important we understand our power and how to use it effectively to build our Nation_

Join us on this platform for enlightenment on *POWER OF THE PEOPLE*
https://chat.whatsapp.com/IldRz3OuIN77p0hz7mhGPr

WhatsApp Group Invite

03/07/2022
𝙸𝙽 𝚀𝚄𝙴𝚂𝚃 𝙵𝙾𝚁 𝙴𝙶𝙰𝙻𝙸𝚃𝙰𝚁𝙸𝙰𝙽 𝚂𝙾𝙲𝙸𝙴𝚃𝚈 𝚃𝙷𝙴𝚁𝙴 𝙰𝚁𝙴 𝙽𝙴𝙴𝙳𝚂 𝙵𝙾𝚁 𝙰 𝙿𝙾𝙻𝙸𝚃𝙸𝙲𝙰𝙻 𝚂𝚃𝚁𝚄𝙲𝚃𝚄𝚁𝙴 𝚃𝙷𝙰𝚃 𝚆𝙸𝙻𝙻 𝙰𝙻𝙻𝙾𝚆 𝚆𝙴𝙻𝙻 𝚁𝙴𝙰𝚂𝙾𝙽𝙸𝙽𝙶 𝙿𝙴𝙾𝙿𝙻𝙴 𝚃𝙾 𝙾𝙿𝙴𝚁...
22/05/2022

𝙸𝙽 𝚀𝚄𝙴𝚂𝚃 𝙵𝙾𝚁 𝙴𝙶𝙰𝙻𝙸𝚃𝙰𝚁𝙸𝙰𝙽 𝚂𝙾𝙲𝙸𝙴𝚃𝚈 𝚃𝙷𝙴𝚁𝙴 𝙰𝚁𝙴 𝙽𝙴𝙴𝙳𝚂 𝙵𝙾𝚁 𝙰 𝙿𝙾𝙻𝙸𝚃𝙸𝙲𝙰𝙻 𝚂𝚃𝚁𝚄𝙲𝚃𝚄𝚁𝙴 𝚃𝙷𝙰𝚃 𝚆𝙸𝙻𝙻 𝙰𝙻𝙻𝙾𝚆 𝚆𝙴𝙻𝙻 𝚁𝙴𝙰𝚂𝙾𝙽𝙸𝙽𝙶 𝙿𝙴𝙾𝙿𝙻𝙴 𝚃𝙾 𝙾𝙿𝙴𝚁𝙰𝚃𝙴 𝙸𝙽 𝙾𝚁𝙳𝙴𝚁 𝚃𝙾 𝙱𝚁𝙸𝙽𝙶 𝚃𝙾𝙶𝙴𝚃𝙷𝙴𝚁 𝙽𝙴𝚆 𝙸𝙳𝙴𝙰𝚂 𝚆𝙸𝚃𝙷 𝙰𝙸𝙼 𝙰𝙽𝙳 𝙾𝙱𝙹𝙴𝙲𝚃𝙸𝚅𝙴𝚂 𝚃𝙾 𝙻𝙸𝙱𝙴𝚁𝙰𝚃𝙴 𝙿𝙴𝙾𝙿𝙻𝙴 𝙸𝙽 𝙰 𝙿𝙰𝚁𝚃𝙸𝙲𝚄𝙻𝙰𝚁 𝚂𝙾𝙲𝙸𝙴𝚃𝚈.

𝙸 𝙻𝙴𝙺𝙰𝙽 𝙰𝙳𝙸𝚂𝙰 𝙿𝚁𝙴𝚂𝙴𝙽𝚃 𝚃𝙾 𝚈𝙾𝚄 𝙰𝙵𝚁𝙸𝙲𝙰 𝙰𝙲𝚃𝙸𝙾𝙽 𝙲𝙾𝙽𝙶𝚁𝙴𝚂𝚂 (𝙰𝙰𝙲) 𝙰𝚂 𝙰 𝙿𝙰𝚁𝚃𝚈 𝚃𝙷𝙰𝚃 𝙰𝙻𝙻𝙾𝚆𝚂 𝚈𝙾𝚄𝙽𝙶 𝙰𝙽𝙳 𝚅𝙸𝙱𝚁𝙰𝙽𝚃 𝙱𝙻𝙰𝙲𝙺 𝚁𝙰𝙲𝙴 𝚃𝙾 𝙵𝚁𝙴𝙴 𝙵𝚁𝙾𝙼 𝙲𝙴𝙽𝚃𝚄𝚁𝚈 𝙳𝙴𝙿𝚁𝙴𝚂𝚂𝙸𝙾𝙽 𝙰𝙽𝙳 𝙴𝚅𝙴𝚁𝚈 𝙺𝙸𝙽𝙳 𝙾𝙵 𝙾𝙿𝙿𝚁𝙴𝚂𝚂𝙸𝙾𝙽.

𝙰𝙰𝙲 𝙰𝚂 𝙰𝙽 𝙸𝙳𝙴𝙾𝙻𝙾𝙶𝙸𝙲𝙰𝙻 𝚁𝙴𝚅𝙾𝙻𝚄𝚃𝙸𝙾𝙽𝙰𝚁𝙸𝙴𝚂 𝙿𝙾𝙻𝙸𝚃𝙸𝙲𝙰𝙻 𝙿𝙰𝚁𝚃𝚈 𝚆𝙰𝚂 𝙲𝚁𝙴𝙰𝚃𝙴𝙳 𝚃𝙾 𝙱𝚁𝙸𝙽𝙶 𝙰𝙱𝙾𝚄𝚃 𝚂𝙾𝙻𝚄𝚃𝙸𝙾𝙽 𝚃𝙾 𝙾𝚄𝚁 𝙲𝙾𝙽𝚃𝙸𝙽𝙴𝙽𝚃 𝙿𝙾𝙻𝙸𝚃𝙸𝙲𝙰𝙻 𝚂𝚈𝚂𝚃𝙴𝙼 𝙿𝚁𝙾𝙱𝙻𝙴𝙼𝚂.

𝚈𝙾𝚄 𝙲𝙰𝙽 𝙱𝙴𝙲𝙾𝙼𝙴 𝙰 𝙸𝙽 𝙽𝙸𝙶𝙴𝚁𝙸𝙰 𝙼𝙴𝙼𝙱𝙴𝚁 𝙱𝚈 𝚁𝙴𝙶𝙸𝚂𝚃𝙴𝚁 𝙾𝙽𝙻𝙸𝙽𝙴.
http://aacparty.org/volunteer

𝙷𝙴𝚁𝙴 𝙸𝚂 𝚆𝙷𝙰𝚃𝚂𝙰𝙿𝙿 𝙻𝙸𝙽𝙺 𝙵𝙾𝚁 𝙾𝚈𝙾 𝚂𝚃𝙰𝚃𝙴 𝙶𝚁𝙾𝚄𝙿.

https://chat.whatsapp.com/JCjmWoABHtX4uwuLeRdeMM

𝙰𝙻𝚂𝙾 𝚈𝙾𝚄 𝙲𝙰𝙽 𝙹𝙾𝙸𝙽 𝙸𝙱𝙰𝙳𝙰𝙽 𝙽𝙾𝚁𝚃𝙷𝚆𝙴𝚂𝚃 𝚆𝙷𝙰𝚃𝚂𝙰𝙿𝙿 𝙶𝚁𝙾𝚄𝙿.
https://chat.whatsapp.com/IhZygyPA64SH1j40kB142v

_*AAC, Take It Back! Action!!*_

Knowing the truth is one thing. Doing something about it is another… Our campaign will only be as strong as our volunteers – folks from around the state who are willing to lend their time and energy to strengthening  our state and our nation. Take the first step in your community by signing up ...

*Kemi Afolabi: N kò mọ ohunkohun nípa ayédèrú ojú òpó Facebook tó ń bèèrè ìrànwọ̀ lórúkọ mi*https://chat.whatsapp.com/DQ...
15/03/2022

*Kemi Afolabi: N kò mọ ohunkohun nípa ayédèrú ojú òpó Facebook tó ń bèèrè ìrànwọ̀ lórúkọ mi*

https://chat.whatsapp.com/DQVtZqXfLAl2waD3K8e2SO

Ogun awitẹlẹ kii pa arọ, eyiun arọ to ba gbọn, bẹẹ si ni ta ba n sunkun, a maa riran.

Eyi lo mu ki gbajugbaja osere tiata nni, Kemi Afolabi figbe sita pe ki awọn ololufẹ oun sọra gidi, ki wn maa baa ko sọwọ awọn onijibiti lori ayelujara.

Kemi Afolabi lo kede lọjọ Ẹti to kọja pe aisan Lupus n ba oun finra eyi to n ro oun ninu egungun ara, ti awọn dokita si ti kede pe o ni oun ko ni ju ọdun mẹrin lati lo loke eepẹ.

Osere tiata naa fikun pe owo to to miliọnu kan naira ni oun n na lojumọ lati ra oogun ati se ayẹwo lori aisan naa, ti oun si ti ta lara dukia oun.

Idi si ree ti ọpọ awọn akẹẹ gbẹ rẹ lagbo tiata atawọn ololufẹ rẹ se n rọjo ẹbun ati adura le lori, lati seto iranwọ fun lori itọju ara rẹ.

Amọ nibayii, Kemi Afolabi ti wa kede pe oun kẹẹfin awọn ọbayejẹ ẹda kan, ti wọn n beere iranwọ ni orukọ oun lori ayelujara lai jẹ pe oun mọ nipa rẹ.

Ninu ikede to gbe soju opo Instagram rẹ, osere tiata naa gbe aworan ohun ti awọn onijibiti naa gbe soju opo Facebook ni orukọ rẹ sita.

Ninu aworan naa ni wọn gbe aworan kemi Afolabi si, ti wọn si kọ orukọ rẹ soju opo Facebook tuntun ti wọn si ni orukọ rẹ naa, ti wọn pe ni Kemi Afolabi Adedipe.

Iwadii fihan pe ilu Eko ni awọn onijibiti naa ni awọn wa, ti wọn si fi nọmba kan soju opo naa fun awọn eeyan to ba fẹ pe wọn.

Kemi Afolabi ni ọrọ to sọ labẹ aworan naa ni "O ti de etigbọ mi pe awọn ọbayejẹ kan n lo anfaani ipo ti mo wa lati lo orukọ ati aworan mi loju opo Facebook.

Awọn onijibiti naa si se eleyi lai jẹ pe mo mọ nipa rẹ tabi gba asẹ lọwọ mi lati se bẹẹ.

Oju opo Facebook mi tootọ ni Kemi Afolabi/Afolabi Kemi, kii si se Kemi Afolabi Adedipe.

Mo wa n rọ ẹyin ololufẹ mi lati mase naani awọn iroyin to ba n jade loju opo awọn onijibiti naa.

Ẹ ri daju pe awọn eeyan ko ko sọwọ awọn gbajuẹ yii nidi iwa jibiti ti wọn n hu."

*Kemi Afolabi: N kò mọ ohunkohun nípa ayédèrú ojú òpó Facebook tó ń bèèrè ìrànwọ̀ lórúkọ mi*https://chat.whatsapp.com/DQ...
15/03/2022

*Kemi Afolabi: N kò mọ ohunkohun nípa ayédèrú ojú òpó Facebook tó ń bèèrè ìrànwọ̀ lórúkọ mi*

https://chat.whatsapp.com/DQVtZqXfLAl2waD3K8e2SO

Ogun awitẹlẹ kii pa arọ, eyiun arọ to ba gbọn, bẹẹ si ni ta ba n sunkun, a maa riran.

Eyi lo mu ki gbajugbaja osere tiata nni, Kemi Afolabi figbe sita pe ki awọn ololufẹ oun sọra gidi, ki wn maa baa ko sọwọ awọn onijibiti lori ayelujara.

Kemi Afolabi lo kede lọjọ Ẹti to kọja pe aisan Lupus n ba oun finra eyi to n ro oun ninu egungun ara, ti awọn dokita si ti kede pe o ni oun ko ni ju ọdun mẹrin lati lo loke eepẹ.

Osere tiata naa fikun pe owo to to miliọnu kan naira ni oun n na lojumọ lati ra oogun ati se ayẹwo lori aisan naa, ti oun si ti ta lara dukia oun.

Idi si ree ti ọpọ awọn akẹẹ gbẹ rẹ lagbo tiata atawọn ololufẹ rẹ se n rọjo ẹbun ati adura le lori, lati seto iranwọ fun lori itọju ara rẹ.

Amọ nibayii, Kemi Afolabi ti wa kede pe oun kẹẹfin awọn ọbayejẹ ẹda kan, ti wọn n beere iranwọ ni orukọ oun lori ayelujara lai jẹ pe oun mọ nipa rẹ.

Ninu ikede to gbe soju opo Instagram rẹ, osere tiata naa gbe aworan ohun ti awọn onijibiti naa gbe soju opo Facebook ni orukọ rẹ sita.

Ninu aworan naa ni wọn gbe aworan kemi Afolabi si, ti wọn si kọ orukọ rẹ soju opo Facebook tuntun ti wọn si ni orukọ rẹ naa, ti wọn pe ni Kemi Afolabi Adedipe.

Iwadii fihan pe ilu Eko ni awọn onijibiti naa ni awọn wa, ti wọn si fi nọmba kan soju opo naa fun awọn eeyan to ba fẹ pe wọn.

Kemi Afolabi ni ọrọ to sọ labẹ aworan naa ni "O ti de etigbọ mi pe awọn ọbayejẹ kan n lo anfaani ipo ti mo wa lati lo orukọ ati aworan mi loju opo Facebook.

Awọn onijibiti naa si se eleyi lai jẹ pe mo mọ nipa rẹ tabi gba asẹ lọwọ mi lati se bẹẹ.

Oju opo Facebook mi tootọ ni Kemi Afolabi/Afolabi Kemi, kii si se Kemi Afolabi Adedipe.

Mo wa n rọ ẹyin ololufẹ mi lati mase naani awọn iroyin to ba n jade loju opo awọn onijibiti naa.

Ẹ ri daju pe awọn eeyan ko ko sọwọ awọn gbajuẹ yii nidi iwa jibiti ti wọn n hu."

WhatsApp Group Invite

*adájọ́ ko gba ki won gba béèlì kyari*Ọrọ fẹ jọ bi ere tiata diẹ loni nileẹjọ giga to wa nilu Abuja nibi ti igbẹjọ ọga ọ...
14/03/2022

*adájọ́ ko gba ki won gba béèlì kyari*

Ọrọ fẹ jọ bi ere tiata diẹ loni nileẹjọ giga to wa nilu Abuja nibi ti igbẹjọ ọga ọlọpaa Naijriia Abba Kyari ti n waye.

Eyi ko si se lẹyin bi iyawo rẹ se daku lẹyin ti wọn pari igbẹjọ lonii ti se ọjọ Aje.

Se ni awọn eeyan rọgba yi obinrin naa ka lati doola ẹmi rẹ, ti wọn si gbe kuro nile ẹjọ.

Asọ dudu ni iyawo Kyari wọ wa sile ẹjọ, to si fẹ lọ di ọkọ rẹ mu, ki o to sadede bẹrẹ si ni mi hẹlẹhẹlẹ.

Ka to wi, ka to fọ, obinrin naa ti daku gbọnran-gandan amọ awọn mọlẹbi to ba BBC sọrọ sọ pe aisan semi-semi (Asthm) lo ni.

Eyi jẹ ọkan lara nkan to sẹlẹ nla to waye nile ẹjọ lonii sugbọn adajọ ti sun igbẹjọ ẹsun kiko oogun oloro ti wọn fi kan Abba Kyari sọjọ mii.

Ni bayii ọjọ Kejidinlọgbọn osu yi ni wọn yoo tẹsiwaju igbẹjọ lori gbigba beeli Abba Kyari ati awọn ọlọpaa mẹrin miran ti wọn jijọ fẹsun kan wọn.

Lọjọ Kẹjọ osu Kẹta ni Kyari ati awọn ọlọpaa mẹ́rin sọ fun adajọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Ẹsun yii nise pẹlu oogun oloro co***ne kilo mẹtadinlogun le diẹ ti wọn ni wọn fẹ ta ati pe wọn gbọna ẹburu yọ ninu oogun oloro co***ne naa, eyi to le diẹ ni ogun kilogiramu.

Adajọ Emeka Nwite lẹyin to gbọ atotonu agbẹjọro Mahmoud Magaji sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Kyari jẹ eleyi ti wọn le gba oniduro rẹ.

Agbẹjọro Kyari yii tun sọ pe Kyari nilo asiko pẹlu agbẹjọro rẹ ki wọn ba fi le gbaradi daada de igbẹjo.

O ni ti Kyari ba si wa lọdọ ajọ NDLEA ko ni le se eleyi bo ti se yẹ.

Agbẹjọro naa fikun pe NDLEA ko ti fun laaye lati le sinmi daada ati lati sayẹwo ẹjọ to wa lọrun rẹ.

O ni wọn n tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ ni bayii.

Agbẹjọro NDLEA Joseph Sunday gba ile ẹjọ nimọran ki wọn ma se jẹ ki wọn gba beeli Kyari.

Awijare rẹ to fi ẹsẹ ofin gbe lẹyin ni pe, Kyari le na papa bora bi wọn ba fi le gba oniduro rẹ.

NDLEA tun sọ pe jijẹ ọga ọlọpaa ikọ ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa tun jẹ anfaani fun Kyari lati sa kuro ni Naijiria, ti ko si ni yọju sile ẹjọ bi wọn ba fi le gba beeli rẹ.

Ajọ NDLEA sọ pe ọrọ naa bẹrẹ lọjọ kọkanlelogun osu Kini nigba ti Kyari pe

Address


Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Gbagede Iroyin posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to Gbagede Iroyin:

Shortcuts

  • Address
  • Telephone
  • Alerts
  • Contact The Business
  • Claim ownership or report listing
  • Want your business to be the top-listed Media Company?

Share