01/10/2022
THE ORIKI OF OBA TIMI TIJANI OLADOKUN OYEWUSI
Oriki Agate
Omo agate logun
Erun yan n’be sese,
Omo erun yank are igbe,
Omo yin mi gbin kin,
Omo ogogo rumo-rumo
O ru mo laye o rumo lorun.
Omo olode okuta,
Omo a buoke die sogun,
Omo atikiji,
Omo jerin, je efan, je kiniun
Oje ikoko, ko pa bale ile leran,
Je borokinni iledi, oko oyinbo, asun kaka tok lorun.
Omo oto ti mu ogi tutu,
Omo ase t oun mu omi kikan,
Omo oloye iji meje, yoyo efa,
Yoyo nji, ti a ran lobi lakesan ile,
Ofi owo gbogbo feleni,
Afikun elenu nkan owo,
Olobi nso,
Oibi mo so mo, e bi iwo naa, lo ni eru re,
Omo a naa okan bo oyo
Oye kii pa igbeti, eni ti a bi si oye, ni oye paa
Ajagbe iji o mo oloye moyin
Ile iya re o mo oloye moyin ,
A ti ki iji,
Omo a gbele be bogun lowe.
Oriki Babanla
Tijani Oladokun Ajagbe Oyewusi
Omo Agbonran Gba ke n ja
Omo so’gbo di ile.
Omo so’gbe di igboro, omo o s’atan d’oja
Omo so inu igbe di igbejo, oda omo lekun a foju di
Omo arunse kuta kuta, ori ile si mosalasi, fila
Funfun, ewufunfun, sokoto funfun bi olosa nla.
Omo Lalemo, omo Eso ikoyi, omo dile dogun,
Omo osun lede la obinrin kaka, omo a pa eran kari ayaba
Omo Onikoyi, to gbo ogun ogun yo sese,
Agbonran ikotun oja n’fon, oja l’Ejigbo,
Ofi enu osa gbole aara,
Agbonran fi olojo se ikowo wole, ari so igbanu ni ibokun,
Okunrin gbonin gboin nigbo Aagba,
Okunrin kitikiti ni igbo Iragbiji,
Ol’ara ida g’oke osun
Omo Eso Ikoyi, oburin oburin fohun ogun yamu yamu
Sunre o Ajagbe omo Ikubolaje ti oda, Ede sile lasunara,
Asuara omo anile L’erin
Sunree, oo Ajagbe Oyewusi Agbonran II Ajagbe II