Yèyégbàgede Àṣà Tv

Yèyégbàgede Àṣà  Tv On Air Personalty
(2)

AZ:5310/OGS/PRO/VOL.7/250                29/03/2024OGUN POLICE COMMAND PRESS RELEASE.ARREST OF A 2 MAN ONE CHANCE ROBBER...
29/03/2024

AZ:5310/OGS/PRO/VOL.7/250 29/03/2024

OGUN POLICE COMMAND PRESS RELEASE.

ARREST OF A 2 MAN ONE CHANCE ROBBERY GANG ALONG LAGOS-ABEOKUTA EXPRESSWAY.

A Four man gang of one chance robbery were given a hot chase by the Sango Ota police operatives and 2 amongst them were arrested.

This was done following a report by a victim on the 23rd of March, 2024.

The victim boarded a Toyota Corolla taxi at Ijako market, going to Itori, with four men who surreptitiously posed as a fellow passenger in the said taxi.

While on the way, the said men robbed the victim of her valuables, by forcefully dispossessing her of her smart phone valued at Eighty five thousand naira ( #85,000), money realized from POS machine sale ,worth one hundred and twenty three thousand naira ( #123,000), and a separate cash sum of one hundred and five thousand naira ( #105,000) and subsequently pushed her out of the car and fled.

Acting on the report, the DPO Sango Ota Division gave his surveillance team a matching order to be on a look out, and unravel the perpetrators of the crime.

Policemen from Sango Division intensified their efforts , and other two fleeing suspects were apprehended on the 28th March, 2024 when a team of surveillance policemen were on a routine patrol around the same route in Itori, having gotten details of their Toyota Corolla operational car, on sighting the policemen, the suspects abandoned their vehicle and ran into different directions, the crack police operatives gave them a hot chase and they succeeded in arresting the duo of Aliu Oyetola 'm', aged 35yrs and Seyi Afolabi 'm' age 40yrs.

A Toyota Corolla vehicle with Reg.No GGE 659 FR, blue colour was recovered.

The two suspects arrested have made confessional statements and are cooperating with the police by giving useful information that will lead to the arrest of other fleeing felons.

The Commissioner of Police, CP Abiodun Alamutu has ordered that the suspects be transferred to the Anti robbery department of the State Criminal Investigation Department for discreet investigation and for diligent prosecution.

SP OMOLOLA ODUTOLA, anipr.
POLICE PUBLIC RELATIONS OFFICER, OGUN STATE POLICE COMMAND HEADQUARTERS ELEWERAN ABEOKUTA.

29/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KỌKÀNDÍNLỌ́GBỌ̀N OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ILÉ ÌFOWÓPAMỌ́ ÀGBÀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI KÉDE ÌLÀNÀ Ọ̀TUN FÚN GBOGBO ÀWỌN ILÉ ÌFOWÓPAMỌ́ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ PÉ WỌ́N GBỌ́DỌ̀ MÚ ÀFÍKÚN BÁ OWÓ ÌDÓKOWÒ WỌN*

2. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI Ń FOJÚ SỌ́NÀ LÁTI RÍ TÍRÍLÍỌ́NÙ MÁRÙN-ÚN NÁÍRÀ LÓRÍ ÀFIKÚN OWÓ ORÍ (VAT) LỌ́DUN 2024*

3. *LÓRÍ Ẹ̀SÙN ṢÍṢE ÀFÍKÚN OWÓ ÌṢÚNÁ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, AṢÒFIN ÀGBÀ NINGIN TI BẸ̀RẸ̀ SI NÍ DÚNKOKÒ LÁTI GBÉ ÌGBÉSẸ́ ÒFIN TAKO ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN ÀGBÀ BÍ WỌN Ò BÁ TÈTÈ DÁ ÒUN PADÀ BỌ̀ SÍPÒ*

4. *OLÓRÍ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢOJÚṢÒFIN TAJUDEEN ABASS TI SỌ PÉ KÍ WỌ́N GBÉ ÒṢÙBÀ RÀBÀǸDẸ̀ FÚN ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ TORÍ PÉ Ó MỌ ÈTÒ NÍPA MÍMÚ ÌTẸ̀SÍWÁJÚ BÁ ÈTÒ ÌJỌBA ÀTI ÒṢÈLÚ*

5. *ÀWỌN ỌMỌ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢOJÚṢÒFIN TI BẸ̀RẸ̀ SI NÍ KÌLỌ̀ FÚN ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ ÈTÒ ÌPAWÓ WỌLÉ LÁPAPỌ̀ LÁTARÍ BÍ WỌ́N ṢE KỌ̀ LÁTI JẸ́ ÌPÈ WỌN*

6. *ÌYÀWÓ ALÁṢẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, AṢÒFIN OLÚRẸ̀MÍ TINÚBÚ TI GBÉ BÍLÍỌ́NÙ KAN NÁÍRÀ KALẸ̀ LÁTI FI GBÓGUN TI IKỌ́ IFE LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

7. *ALÁṢẸ TẸ́LẸ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, AJAGUNFẸ̀YÌNTÌ MÙHÁMMÁDÙ BÙHÁRÍ TI BÁ ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ YỌ̀ AYỌ̀ ỌJỌ́ ÌBÍ ỌDÚN KEJÌLÉLÁÀDỌ́RIN TÓ Ń PÉ LÓKÈ EÈPẸ̀*

8. *LÓRÍ PỌ̀PỌ̀ṢÌNṢÌN ỌDÚN ÀJÍǸDE, Ọ̀GÁ ÀGBÀ ỌLỌ́PÀÁ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI PÀṢẸ KÍ ÈTÒ ÀÀBÒ ALÁYÌPÓ Ó BẸ̀RẸ̀ SÍ NÍ FI ẸSẸ̀ MÚLẸ̀ LÁWỌN PÁPÁKỌ̀ ÒFURUFÚ, OJÚ ỌKỌ̀ IRIN, ÌBÙDÓKỌ́ GBOGBO ÀTI ÀWỌN IBI TÓ ṢE GBÒÓGÌ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

9. *ILÉ ẸJỌ́ GÍGA TÓ WÀ LÓLÚ ÌLÚ WA ÀBÚJÁ TI FÌDÍ Ẹ̀ MÚLẸ̀ PÉ ALÁKÒÓSO FÚN ÈTÒ ÌDÁJỌ́ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TẸ́LẸ̀ TI WẸ̀ YÁN KÀNǸKÀN LÓRÍ Ẹ̀SÙN TÍ WỌ́N FI KÀN ÁN*

10. *ẸGBẸ́ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (NANS) TI Ń DÚNKOKÒ LÁTI FI Ẹ̀HỌ́NÚ HÀN LÁTARI BÍ OWÓ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ṢE WỌ́N GEGELE ÀTI BÍ WỌN Ò ṢE FÚN WỌN LÁWỌN OUN TÓ YẸ KÍ WỌ́N FÚN WỌN LÁWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ WỌN GBOGBO*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

28/03/2024

NIGERIANS, PLEASE HELP ME OUT, A SCHOOL USED MY DAUGHTER FOR RITUAL...Eleyi tun ga o . Ni Abeokuta Ogun state .
The Ogun State Ministry of Education need to look into this so that this girl will not die in vain.

Credit: Kasnaty

AN APOLOGY FROM ENIOLA AJAODear Esteemed Members of the PublicI write to you today with a heavy heart, filled with regre...
28/03/2024

AN APOLOGY FROM ENIOLA AJAO

Dear Esteemed Members of the Public
I write to you today with a heavy heart, filled with regret and remorse over the events that unfolded at my movie premiere, "AJAKAJU," on Sunday, 24th March, 2024. I address you all today, taking full responsibility and seeking your pardon with my deepest regrets for the distress and turmoil caused by the events surrounding the premiere of "AJAKAJU."
First, I want to extend my sincerest apologies to the Muslim community, especially during this sacred month of Ramadan. I acknowledge and respect the significance of this time, and it was never my intention to offend or upset anyone with the proceedings of our premiere. Please accept my sincerest apologies for any distress my actions may have caused during this sacred time.
To the women in our society, I want to express my profound apologies. As a woman myself, I understand the importance of upholding and honoring our gender with dignity and respect. I want to assure you that I hold the utmost reverence for womanhood, and I would never intentionally engage in any behavior that diminishes or disparages the role of women in our society.
I also extend my heartfelt apologies to Femi Adebayo and his wife for the undue backlash they faced as a result of the announcement made at our event. I deeply regret the insults and disrespect directed towards them, and I take full responsibility for any harm caused.
To Bobrisky, I offer my sincere apologies for putting you in a difficult position. The decision to award you was never meant to cause harm or controversy but was rather a misguided attempt to generate publicity for our movie. I am truly sorry for any distress this may have caused you.

In an effort to make amends and correct my mistakes, I have decided to honor Papaya Ex and Iyabo Ojo as the best-dressed females at the premiere. Each will receive a sum of N1,000,000(One Million Naira) as a token of my sincere apology and appreciation for their grace and elegance.
I want to emphasize that my primary goal in all of this was to promote my movie, which is set to hit cinemas on 29th March, 2024. While I may have made missteps.

28/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KEJÌDÍNLỌ́GBỌ̀N OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ, ÀWỌN Ọ̀TỌ̀KÙLÙ ÌLÚ, ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN, ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ PẸ̀LÚ ÀWỌN GÓMÌNÀ GBOGBO LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI BU ỌLÁ ÌKẸYÌN FÚN ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ MẸ́TÀDÍNLÓGÚN TÍ WỌ́N ṢUBÚ GBÉ Ẹ̀MÍ MÌ LÓJÚ ÌJÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA. BẸ́Ẹ̀ SÌ NI ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ PÀṢẸ PÉ KÍ WỌ́N ṢÀWÁRÍ ÀWỌN ẸNI IBI TÓ GBẸ̀MÍ WỌN LÁTI WÁ FI IMÚ KÁTA ÒFIN*

2. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI KÉDE ỌJỌ́ ẸTÌ ỌJỌ́ KỌKÀNDÍNLỌ́GBỌ̀N Ọ̀SẸ̀ YÌÍ ÀTI ỌJỌ́ AJÉ ỌJỌ́ KÍNNÍ OṢÙ KẸRÌN Ọ̀SẸ̀ TÓ Ń BỌ̀ GẸ́GẸ́ BÍ ỌJỌ́ ÌSINMI LẸ́NU IṢẸ́ FÚN ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ LÁTI LÈ FI ṢE PỌ̀PỌ̀ṢÌNṢÌN ÌSÀMÌ AYẸYẸ ỌJỌ́ ÀJÍǸDE JÉSÙ KRISTÌ OLÚWA*

3. *ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ TI ṢÈLÉRÍ PÉ ÌṢÀKÓSO ÒUN MÁA PÈSÈ Ẹ̀KỌ́ Ọ̀FẸ́ ÀTI ILÉ ÌGBÉ FÚN ÀWỌN ỌMỌ ÀTI ẸBÍ ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN MẸ́TÀDÍNLÓGÚN TÍ WỌ́N DÁ Ẹ̀MÍ WỌN LÉGBODÒ NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA*

4. *IGBÁKEJÌ ALÁṢẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, KASHIM SHETTIMA TI FI ÌDÁNILÓJÚ Ẹ̀ HÀN PÉ ÒUN MỌ̀ PÉ OWÓ NÁÍRÀ Ò TUN NÍ FẸ̀GBẸ́ WỌ́N ILẸ̀ LẸ́GBẸ̀ OWÓ ILẸ̀ ÒKÈRÈ*

5. *LÁÀRIN GBOGBO ÀTAKÒ TÓ Ń WÁYÉ LÁTỌWỌ́ ẸGBẸ́ ÒṢÌṢẸ́ NLC SÍ JULIUS ÀBURÈ, WỌ́N TÚN TI DÌBÒ YAN JULIUS ÀBURÈ GẸ́GẸ́ BÍ ALÁGA ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ LABOUR PARTY FÚN SÁÀ KEJÌ NÍNÚ ÌGBÌMỌ̀ ÀWỌN AṢOJÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ LABOUR PARTY*

6. *ILÉ IṢẸ́ TÓ Ń PÈSÈ EPO LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (NNPCL) TI SỌ PÉ IRỌ́ ŃLÁ NI ÌRÒYÌN TÓ Ń JÀ RÀN-ÌN RÀN-ÌN KIRI PÉ ÀWỌN MÁA MÚ OWÓ EPO WÁ SÍLẸ̀ JU BÓ ṢE WÀ LỌ*

7. *Ọ̀GÁ ỌLỌ́PÀÁ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, ABÍỌ́DÚN ALÁMÙTÚ TI SỌ̀RỌ̀ LÓRÚKỌ ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN PÉ ÀWỌN TI FI ÀYÈ SÍLẸ̀ LÁTI BẸ̀RẸ̀ ÌFOJÚ ÀÁNÚ WO ÀWỌN ỌMỌ ẸLẸ́GBẸ́ ÒKÙNKÙN TÍ WỌ́N BÁ FINNÚ FẸ́DỌ̀ FI ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN SÍLẸ̀ PÉ ÀWỌN Ò ṢE MỌ́ LÁTARI BÍ ÀWỌN ỌMỌ ẸLẸ́GBẸ́ ÒKÙNKÙN TÍ WỌ́N TÓ MÉJÌDÍNLÁÀDỌ́TA ṢE YÀNDA PÉ ÀWỌN Ò ṢE ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN MỌ́ NÍ AGBÈGBÈ ṢÀGÁMÙ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN*

8. *GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, ỌMỌBA DÀPỌ̀ ABÍỌ́DÚN TI SỌ PÉ ÌṢÀKÓSO ÒUN MÁA BẸ̀RẸ̀ ÈTÒ TÍTA ÌRẸSÌ FÚN GBOGBO ARÁ ÌLÚ JÁKÈJÁDÒ GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN NÍ ÌDAJÌ OWÓ LÁTI LÈ MÚ Ẹ̀DÍNKÙ BÁ GBOGBO ÌNIRA TÓ Ń BÁ ÀWỌN ÈNÌYÀN FÍNRA LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

9. *ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TÍ WỌN Ò NÍ ÀǸFÀÀNÍ LÁTI SO NỌ́MBÀ ÌBANISỌ̀RỌ̀ WỌN MỌ́ NỌ́MBÀ ÌDANIMỌ̀ TI RỌ ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ ÌKÀNSIRA ẸNI LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ PÉ KÍ WỌ́N DÁKUN DÁBỌ̀ BÁ ÀWỌN SÚN GBÈǸDÉKE ỌJỌ́ TÍ WỌ́N FÚN WỌN SÍWÁJÚ SI*

10. *ILÉ ẸJỌ́ TÓ WÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN TI DÁJỌ́ Ẹ̀WỌ̀N ỌDÚN MÉJE FÚN ADÉWÁLÉ ADÉNẸ́KÀN ẸNI ỌDÚN MÉJÌLÉLÓGÚN LÁTARÍ Ẹ̀SÙN ṢÍṢE ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN NÍ AGBÈGBÈ IFỌ̀*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

28/03/2024

FEMI ADEBAYỌ STOP BEEN A SHALLOW MINDED JỌỌ, DAYỌ AMUSA JEALOUS YOU ON WHAT? ANI NKAN TẸẸ ṢE KÒ DÁRA, OHUN TÍ KÒ DÁA O LÓRÚKO MÉJÌ NOW😏😏 BOBRISKY BEST FEMALE DRESSED FOR WHAT? Ẹ MA GBAMI LỌ́WỌ́ ÀWỌN YẸYẸBRITIES YÍ KĘ😏😏

27/03/2024

IS BOBRISKY A FEMALE? IF NO IS THE ANSWER, WHY WAS HE THE BEST FEMALE DRESSED? SOMETHING IS WRONG WITH YẸYẸBRITIES
😏😏😏😏😏😏😏

27/03/2024

I'M NOT EXPECTING MUCH FROM THIS YEYEBRITY AND FILM MAKERS, BECAUSE THEY'RE THE ONE DISTROYING OUR CULTURE EVERY DAY.

26/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN TÒNÍ ỌJỌ́ KẸRÌNDÍNLỌ́GBỌ̀N OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI RÁNṢẸ́ PÉ SHEIKH GÚMÍ KÓ WÁ SỌ TẸNU Ẹ̀ LÓRÍ ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ KAN TÓ SỌ́ NÍPA ÌJÍNIGBÉ TÓ WÁYÉ LÁPÁ ÀRÍWÁ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

2. *ADARÍ ẸGBẸ́ ỌMỌ ODÙDUWÀ NI, IBA GÀNÍ ADAMS ÀTI AJÌJÀGBARA FÚN ÌDÁSÍLẸ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ YORÙBÁ, OLÓYÈ SUNDAY ADÉYẸMỌ TÍ GBOGBO ÈNÌYÀN MỌ̀ SÍ SUNDAY ÌGBÒHO GBÉNÁ WOJÚ ARA WỌN*

3. *LÁTARI BÍ GBOGBO ǸKAN ṢE LE KOKO LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁSÌKÒ YÌÍ, MỌ́ṢÁLÁṢÍ ŃLÁ KAN NÍ ÌPÍNLẸ̀ JÌGÁWÁ TI PÍN ÀPÒ ÌRẸSÌ TÓ TÓ ẸGBẸ̀RÚN LỌ́NÀ ỌGBỌ̀N FÚN ÀWỌN ÈNÌYÀN NÍ ÌPÍNLẸ̀ NÁÀ*

4. *ÌGBÌMỌ̀ ÌṢÀKÓSO ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI BỌWỌ́ LÚ OWÓ TÓ TÓ TÍRÍLÍỌ́NÙ KAN NÁÍRÀ ÀTI Ọ̀Ọ́DÚNRÚN (1.3trln) FÚN ÀKÀNṢE ÀWỌN OJÚ Ọ̀NÀ TÓ TÓ MÉJÌLÉLỌ́GBỌ̀N JÁKÈJÁDÒ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

5. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI KÀN SÍ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ (INTERPOL) ÀTI ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ LÁTI BÁ WỌN ṢÀWÁRÍ ỌKÙNRIN KAN TÓ SÁLỌ PẸ̀LÚ ÀWỌN KAN NÍ IBI TÍ WỌ́N FI PAMỌ́ SÍ LÓRÍ Ẹ̀SÙN JÌBÌTÌ ORÍ Ẹ̀RỌ AYÉLUJÁRA ÀTI MÍ MÁA ṢE PÀṢÍPÀRỌ̀ OWÓ LỌ́NÀ ÀÌTỌ́*

6. *Ọ̀KAN PÀTÀKÌ LÁRA ÀWỌN AKỌ̀RÒYÌN NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, JÁMÍÙ FỌLÁRÌN TI KỌ̀WÉ RÁNṢẸ́ SÍ ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ TÓ WÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN LÁTARI BÍ ÀWỌN AJAGUNGBALẸ̀ ṢE Ń DÚNKOKÒ MỌ́ Ẹ̀MÍ Ẹ̀*

7. *ALÁKÒÓSO FÚN ÈTÒ ÌRÒYÌN ÀTI ÌLANILỌ́YẸ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ MÙHÁMMÁDÙ IDRIS TI SỌ PÉ ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ Ò SAN OWÓ KANKAN LÁTI GBA ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ TÍ WỌ́N JÍ GBÉ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ PADÀ*

8. *ILÉ ẸJỌ́ TÓ WÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ANAMBRA TI RÁN ỌKÙNRIN KAN LẸ́WỌ̀N ỌDÚN MẸ́WÀÁ LÓRÍ Ẹ̀SÙN PÉ Ó FI IPÁ BÁ ỌMỌBÌNRIN ỌDÚN MẸ́SÀN-ÁN KAN NÍ ÀJỌ́ṢEPỌ̀*

9. *IKỌ̀ ÀMỌ̀TẸ́KÙN TI RỌ́WỌ́ TÓ Ọ̀GBẸNI AWAKỌ̀ AKÉRÒ KAN TÓ JÍ ỌMỌBÌNRIN ỌMỌ ỌDÚN MẸ́Ẹ̀DÓGÚN KAN GBÉ SÁLỌ NÍ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀ṢUN*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

Thanks for being a top engager and making it on to my weekly engagement list! 🎉 Hairat Oluwatoyin, Mariam Harbimbolar Du...
26/03/2024

Thanks for being a top engager and making it on to my weekly engagement list! 🎉 Hairat Oluwatoyin, Mariam Harbimbolar Duroorike, Awi Kehinde Aina

25/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KẸẸ̀DỌ́GBỌ̀N OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ TI TỌ́LẸ̀ LÁ FI ỌLỌ́RUN ṢẸ̀RÍ PÉ ÒUN MÁA ṢE ÀTÌLẸYÌN FÚN ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ SAFERS CORP LÁTARI BÍ WỌ́N ṢE GBA ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ LÀ*

2. *LÓRÍ AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌSINMI Ọ̀PẸ TÓ WÁYÉ LÁNÀÁ, ẸGBẸ́ ÀWỌN ỌMỌLẸ́YÌN KRÍSTÌ TI RỌ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁTI FI ÀÀYÈ GBA ÌṢỌ̀KAN ÀTI ÀLÀÁFÍÀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

3. *ÀWỌN AṢÁJÚ ẸGBẸ́ ÀWỌN ỌMỌLẸ́YÌN KRÍSTÌ TI GBÓṢÙBÀ RÀBÀǸDẸ̀ FÚN GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, ỌMỌBA DÀPỌ̀ ABÍỌ́DÚN LÓRÍ BÍ ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN ṢE PÈSÈ OUN ÌRÀNWỌ́ FÚN ÀWỌN ONÍGBÀGBỌ́ LÁWỌN ILÉ ÌJỌSÌN GBOGBO TÓ WÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN*

4. *LÓRÍ ÌJÍNIGBÉ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ÀTI ÀWỌN OLÙKỌ́ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ, ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI Ń GBÈRÒ LÁTI GBA ÀWỌN ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ ELÉTÒ ÀÀBÒ SÍ ÀWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́*

5. *GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ TI FI ÌDÍ Ẹ̀ MÚLẸ̀ PÉ OLÙKỌ́ KAN NÍNÚ ÀWỌN OLÙKỌ́ TÍ WỌ́N JÍ GBÉ PẸ̀LÚ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ TI PÀDÁNÙ Ẹ̀MÍ Ẹ̀ NÍ ÀKÀTÀ ÀWỌN AJÍNIGBÉ*

6. *ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ TI WỌ́GI LÉ AYẸYẸ PỌ̀PỌ̀ṢÌNṢÌN ỌJỌ́ ÌBÍ Ẹ̀ LÁTI LÈ DÈNÀ ÌNÁKÚNÀ ÒUN ÀNÁDÀNÀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

7. *Ọ̀KAN NÍNÚ ÀWỌN OPÓ TÍ ỌKỌ Ẹ̀ PẸ̀LÚ ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN TÍ WỌ́N DÁ Ẹ̀MÍ Ẹ̀ LÉGBODÒ NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA TI KÉ GBÀJARÈ SÍTA, Ó SÌ TI TỌ́LẸ̀ LÁ FI ỌLỌ́RUN ṢẸ̀RÍ PÉ ÒUN Ò NÍ GBA ỌMỌ ÒUN KANKAN LÁÀYÈ LÁTI ṢIṢẸ́ OLÓGUN*

8. *ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ÀWỌN TI ṢE TÁN LÁTI DÁ ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ SÍLẸ̀*

9. *ÀWỌN ONÍMỌ̀ ÌṢÈGÙN NÍPA OUN Ọ̀SÌN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI SỌ̀RỌ̀ ÌKÌLỌ̀ SÍTA FÚN ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ PÉ KÍ WỌ́N ṢỌ́RA GIDI GAN LÓRÍ ÀTI MÁA JẸ ÀWỌN ẸRAN TÍ KÒ BÁ ARA RẸ́*

10. *ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ÀTI ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI ṢE TÁN LÁTI MÁA LẸ ORÚKỌ ÀTI ÀWÒRÁN ÀWỌN TÍ WỌ́N BÁ TI KÉDE PÉ WỌ́N Ń WÁ SÍ ÀWỌN PÁPÁKỌ̀ ÒFURUFÚ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ GLAMOURLADY*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

Congratulations and happy birthday sir long life in sound health and plenty wealth lasẹ Èdùmàrè 🙏🙏🙏Fans join me to celeb...
24/03/2024

Congratulations and happy birthday sir long life in sound health and plenty wealth lasẹ Èdùmàrè 🙏🙏🙏
Fans join me to celebrate Alhaji Chief Dr Sefiu Àlàó Adekunle ọmọ oko tó gbó kirakira

Clear road for March born, boss and my partner on ayekooto on Sweet 107.1 FM  Abẹ́òkúta, ijẹmọ akomoyin ara ìtake ọmọ on...
24/03/2024

Clear road for March born, boss and my partner on ayekooto on Sweet 107.1 FM Abẹ́òkúta, ijẹmọ akomoyin ara ìtake ọmọ onilẹ n'ilu Ẹ̀gbá, Ode Aperan Happy birthday sir long life in sound health and plenty wealth lasẹ Èdùmàrè 🙏

24/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KẸRÌNLÉLÓGÚN OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ALÁKÒÓSO TÓ Ń ṢÀKÓSO ILÉ IṢẸ́ TÓ Ń RÍ SÍ ÈTÒ ÌLERA LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, Ọ̀MỌ̀WÉ MUHAMMAD ALLI TI TỌWỌ́ BỌ ÌWÉ ÀDÉHÙN ALÁSỌYÉPỌ̀ KAN PẸ̀LÚ ÀJỌ N.S.I.A LÁTI LỌ RA ÀWỌN OUN ÈLÒ KAN FÚN ÌTỌ́JÚ ÀTI ÀYẸ̀WÒ ÀÌSÀN JẸJẸRẸ LÁWỌN ILÉ ÌWÒSÀN ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ MẸ́FẸ̀Ẹ̀FÀ TÓ WÀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

2. *AṢÒFIN ÀGBÀ KAN TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ WÀ NÍ IPELE ÀTÚNBÍ ÈTÒ ỌRỌ̀ AJÉ LÁBẸ́ ÌṢÀKOSO ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ*

3. *ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI ṢEKÚ PA ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ TÍ WỌ́N JẸ́ IKỌ̀ ISWAP MÁRÙN-ÚN NÍ APÁ ÀRÍWÁ ÌLÀ ÒÒRÙN ORÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ, WỌ́N SÌ DÓÒLÀ Ẹ̀MÍ ÀWỌN OBÌNRIN TÍ WỌ́N JẸ́ MÉJÌDÍNLỌ́GỌ́RIN ÀTI ÀWỌN ỌMỌ KÉKERÉ*

4. *ÀJỌ NDLEA TI KÌLỌ̀ FÚN ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ PÉ KÍ WỌ́N ṢỌ́RA FÚN ÀWỌN ONÍJÌBÌTÌ TÍ WỌ́N Ń PERA WỌN NÍ ÒṢÌṢẸ́ ÀJỌ NDLEA*

5. *ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ ÈTÒ ÌDÁNWÒ ÌGBANIWỌLÉ SÍ ÀWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍGA ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ(JAMB) TI SỌ́ DI MÍMỌ̀ ÀWỌN TI SÚN PÉ ÈTÒ ÌFORÚKỌ SÍLẸ̀ FÚN ÈTÒ ÌGBANIWỌLÉ TÀÀRÀ (DIRECT ENTRY) SÍWÁJÚ SI FÚN Ọ̀SẸ̀ MÉJÌ*

6. *ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI NAWỌ́ GÁN ÀWỌN ÈNÌYÀN TÍ WỌ́N ÌGBÌMỌ̀ PỌ̀ LÁTI LỌ KỌLU ILÉ ÌJỌSÌN ÌJỌ ÀGÙDÀ KAN NÍ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ*

7. *ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ÀWỌN ỌJÀ TÍ WỌ́N ṢÍ SÍLẸ̀ LÁTI MÁA TA 'OÚNJẸ ÈKÓ' MÁA DI ṢÍṢÍ PADÀ LÓNÌÍ ỌJỌ́ ÀÌKÚ*

8. *ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ LABOUR PARTY NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI PÀṢẸ FÚN ALÁGA ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ NÁÀ, JULIUS ABURE LÁTI KỌ̀WÉ FI IPÒ SÍLẸ̀ LÓNÍ WÀRÀǸṢESÀ*

9. *GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́, ONÍMỌ̀ Ẹ̀RỌ ṢÈYÍ MÁKINDÉ TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ÌBAṢEPỌ̀ TÓ DÁNMỌ́RÁN LÁÀÁRÍN ÀWỌN ẸLẸ́SÌN ÀTI ÀWỌN ÈNÌYÀN ÌPÍNLẸ̀ NÁÀ LÓ MÚ ÀWỌN ÀṢEYỌRÍ ỌLỌ́KAN-Ò-JỌ̀KAN BÁ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́*

10. *ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒǸDÓ TI ṢE ÀYẸ̀WÒ FÍNNÍFÍNNÍ FÚN ÀWỌN TÓ Ń GBÈRÒ ÀTI DÍJEDUPÒ FÚN IPÒ GÓMÌNÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒǸDÓ*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

23/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KẸTÀLÉLÓGÚN OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ TI KÍ YÈYÉ OLÚFÚNKẸ́ DANIEL TÍÍ ṢE AYA GÓMÌNÀ TẸ́LẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, TÍ Ó TÚN JẸ́ ASOFIN ÀGBÀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ Ọ̀TUNBA JUSTUS OLÚGBÉNGA DANIEL KÚ ORÍIRE ỌGỌ́TA ỌDÚN TÓ Ń PÉ LÓÓKẸ̀ EÈPẸ̀*

2. *Ọ̀KAN NÍNÚ ÀWỌN ÌGBÌMỌ̀ TÍ WỌ́N Ń GBÉ ÌGBÉSẸ̀ NÍPA ÀFIKÚN OWÓ OṢÙ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ TO KÉRÉ JÙ LỌ TI SỌ PÉ Ó ṢEÉ ṢE KÍ ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ KÉDE ÀFIKÚN OWÓ OṢÙ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ TÓ KÉRÉ JÙLỌ NÍ ÀYÁJỌ́ ỌJỌ́ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÓṢÙ KARÙN-ÚN*

3. *ALÁṢẸ TẸ́LẸ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, OLÓYÈ OLÚṢẸ́GUN ỌBÁSANJỌ́ TI RỌ ÀWỌN GÓMÌNÀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁTI TẸ̀LÉ ÌLÀNÀ GÓMÌNÀ ALEX OTTI BÍ Ó ṢE ṢE ÀTÚNṢE NÍPA YÍYỌ ORÚKỌ ÀWỌN GÓMÌNÀ TÓ TÍ ṢE ÌJỌBA TẸ́LẸ̀ ÀTI ÀWỌN IGBÁKEJÌ WỌN KÚRÒ NÍNÚ ÀWỌN TÍ YÍÒ MÁA GBA OWÓ ÌFẸ̀YÌNTÌ NÍ ÌPÍNLẸ̀ RẸ̀*

4. *ALÁGA FÚN ÀJỌ ELÉTÒ ÌDÌBÒ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (INEC), Ọ̀JỌ̀GBỌ́N MAHMOOD YÀKÚBÙ TI RỌ ÀWỌN IKỌ̀ ELÉTÒ ÀÀBÒ LÁTI FI ÌWÀ ỌMỌLÚWÀBÍ ṢIṢẸ́ TAKUNTAKUN NÍBI ÈTÒ ÌDÌBÒ TÓ MÁA WÁYÉ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒǸDÓ ÀTI ÌPÍNLẸ̀ EDÓ*

5. *ẸGBẸ́ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (NLC) ÀTI ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ LABOUR PARTY TI YỌ JULIUS ABURE KÚRÒ LÓRÍ IPÒ GẸ́GẸ́ BÍ ALÁGA ẸGBẸ́ NÁÀ*

6. *ÌYÀWÓ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ, ÌBÍJỌKẸ́ SANWÓ OLÚ TI RÓ ÀWỌN ÈNÌYÀN TÓ TÓ Ọ̀TÀLÉLỌ́Ọ̀DÚNRÚN Ó DÍN MẸ́WÀÁ LÁGBÁRA NÍPA FÍFÚN WỌN NÍ IRINṢẸ́ ỌWỌ́ ÀTI OWÓ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ*

7. *ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN TI ṢE ÀWÁRÍ IBÙDÓ KAN TÍ WỌ́N Ń KÓ ÀWỌN ÈNÌYÀN TÍ WỌ́N Ń KÓ ÀWỌN ÀJÒJÌ SÍ LÁTI ORÍLẸ̀ ÈDÈ TOGO, CAMEROON, NIGER LỌ́NÀ TÍ Ò BÁ ÒFIN MU NÍ ÌLÚ ỌBÁDÁ OKO NÍ ABẸ́ÒKÚTA ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN*

8. *ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ TI RỌ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁTI MÁA RA ÀWỌN ǸKAN TÍ À Ń PÈSÈ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ DÍPÒ ÀWỌN OUN TÍ WỌ́N Ń PÈSÈ NÍ ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ KÍ OWÓ NÁÍRÀ WA LÈ NÍYE LÓRÍ SI*

9. *ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ OJÚ PÓPÓ TI SỌ PÉ ÀWỌN MÁA BẸ̀RẸ̀ SI NÍ GBẸ́SẸ̀ LÉ GBOGBO ỌKỌ̀ TÓ BÁ Ń KÓ ÈNÌYÀN MỌ́ ẸRÚ LÁWỌN OJÚ PÓPÓ TÓ WÀ NÍ TÌBÚTÒRO ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

10. *GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ NASSARAWA TI PÀṢẸ KÍ WỌ́N ṢE ÌWÁDÌÍ NÍ Ọ̀RÍNKÍNNIWÍN LÓRÍ IKÚ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ OBÌNRIN MÉJÌ TÍ WỌ́N TẸ̀ MỌ́LẸ̀ PA LÁSÌKÒ TÍ WỌ́N Ń PÍN OÚNJẸ FÚN ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ ÌPÍNLẸ̀ NASSARAWA*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

22/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KEJÌLÉLÓGÚN OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ LÁÌPẸ́ LÁÌJÌNNÀ, ÀWỌN MÁA BẸ̀RẸ̀ SI NÍ KÓ ÀWỌN AKỌ́ṢẸ́MỌṢẸ́ AJÓRINMỌ́RIN (WELDER) ÀTI ÀWỌN TÍ WỌ́N MỌ́ NÍPA SÍSO IRIN KAN MỌ́ ÈKEJÌ LỌ SÍ ÀWỌN ORÍLẸ̀ ÈDÈ ADÚLÁWỌ̀ MÌÍRAN ÀTI ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ LÁTI LỌ ṢIṢẸ́*

2. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI SỌ PÉ OUN GBOGBO TÍ ÀWỌN BÁ NÍ LÀWỌN MÁ FI GBÓGUN TI ÌYÀ ÀTI ÌṢẸ́ TÓ Ń JẸ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

3. *ALÁKÒÓSO KAN TI SỌ̀RỌ̀ PÉ BÍLÍỌ́NÙ KAN NI JÁLÁ EPO TÍ WỌ́N Ń KÓ WỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LỌ́NÀ ÀÌTỌ́*

4. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TI ṢE ÌFILỌ́LẸ̀ ÀWỌN IKỌ̀ ELÉTÒ ÀÀBÒ TUNTUN TÍ YÓÒ MÁA DÁ ÀÀBÒ BO ÀWỌN ÌBÙDÓ ÌWAKÙSÀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

5. *LÁTARI BÍ ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ ṢE Ń ṢORO BÍ AGBỌ́N LÁWỌN AGBÈGBÈ KAN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ, ÀTI BÍ ÀWỌN KAN ṢE Ń ṢÀTÌLẸYÌN FÚN WỌN, ÀWỌN ỌMỌ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN ÀGBÀ TI SỌ̀RỌ̀ PÉ ÀWỌN TI ṢE ÀTÚNṢE SÍ ÒFIN KAN TÓ MÁA RÀN WỌ́N LỌ́WỌ́ LÁTI MÁA GBÓGUN TI ÌWÀ Ọ̀DARÀN*

6. *ÌGBÌMỌ̀ ÀWỌN AṢÒFIN ÀGBÀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI RỌ ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ LÁTI WÁ OJÚTÙÚ SÍ ÌṢÒRO ÌJÍNIGBÉ TÓ TI GBÌNÀYÁ NÍ TÌBÚTÒRO ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

7. *ÌGBÌMỌ̀ ÀWỌN GÓMÌNÀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI FÌDÍ Ẹ̀ MÚLẸ̀ PÉ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ NI WỌ́N MÁA YANJÚ GBOGBO ÌṢÒRO ÈTÒ ÀÀBÒ TÓ Ń DẸ̀GBẸ́ WỌ̀GBẸ́ LỌ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

8. *Ọ̀GÁ ÀGBÀ ILÉ IṢẸ́ ALÁÀBÒ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI SỌ PÉ LÁÌPẸ́ LÁÌJÌNNÀ WỌN Á BẸ̀RẸ̀ SI NÍ MÁA LO ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN LÁTI MÁA DÁ ÀÀBÒ BO ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ WỌN GBOGBO LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ*

9. *Ọ̀GÁ ÀGBÀ ÀJỌ TÓ Ń MÓJÚ TÓ Ọ̀RỌ̀ ÀWỌN PÁPÁKỌ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI FÌDÍ Ẹ̀ MÚLẸ̀ PÉ ÀWỌN OUN ÈÈLÒ ÀTI ÀWỌN ÈBÚTÉ TÍ ỌJỌ́ TI LỌ LÓRÍ WỌN NÍ TÌBÚTÒRO ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÓ Ń ṢE ÀKÓBÁ FÚN ÀWỌN IṢẸ́ ÀKÀNṢE TÓ YẸ KÍ WỌ́N ṢE SÍ ÀWỌN ÈBÚTÉ NÁÀ*

10. *ALÁṢẸ TẸ́LẸ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, GOODLUCK EBELE JONATHAN TI LÉWÁJÚ ÀWỌN ÀGBÀÀGBÀ LÁTI APÁ ÌWỌ̀ OÒRÙN ILẸ̀ ADÚLÁWỌ̀ LÁTI LỌ MÓJÚ TÓ ÌDÌBÒ TÓ WÁYÉ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NAMIBIA*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

21/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KỌKÀNLÉLÓGÚN OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ALÁṢẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, BỌ́LÁ AHMED TINÚBÚ TI RABỌ́ Ẹ̀BẸ̀ SÍ ÀWỌN ỌMỌ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢOFIN ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁTI DẸ́KUN ÀTI MÁA PÉ ÀWỌN ALÁKÒÓSO TÍ WỌ́N YÀN SIṢẸ́ NÍ GBOGBO ÌGBÀ, KÍ WỌ́N GBÀ WỌ́N LÁÀYÈ LÁTI ṢIṢẸ́ WỌ́N DÓJÚ ÀÀMÌ*

2. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI Ń GBÉ ÌGBÉSẸ̀ LÁTI WÁ WỌ̀RỌ̀KỌ̀ FI ṢE ÀDÁ LÓRÍ ÌPÈNIJÀ ÈTÒ ÌṢÚNÁ TÓ Ń KOJÚ Ẹ̀KA OUN ÀMÚṢAGBÁRA ÌYẸN INÁ MỌ̀NÀ MỌ́NÁ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

3. *ÀWỌN ỌMỌ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI BU ỌWỌ́ LU ÀBÁ KAN TÓ NÍ ṢE PẸ̀LÚ OWÓ YÍYÁ FÚN ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́*

4. *ẸGBẸ́ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (NLC) TÍ YABO OLÚ ILÉ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ LABOUR PARTY TÓ WÀ NÍ ÌLÚ ÀBÚJÁ, WỌ́N SÌ Ń BÉÈRÈ FÚN ÌYỌNÍPÒ ALÁGA ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ LABOUR PARTY ÌYẸN JULIUS ABURE LÓRÍ Ẹ̀SÙN PÉ Ó FẸ́ GBÉ ÌPÀDÉ KAN KALẸ̀ LÁÌSÍ ÌMỌ̀ ÀWỌN ALẸ́NULỌ́RỌ̀ ÀWỌN ẸGBẸ́ NÁÀ NÍBẸ̀*

5. *ALÁBÒÓJÚTÓ FÚN Ọ̀RỌ̀ ÀṢÀ ÀTI OUN ÌGBAFẸ́ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, HON ṢẸ̀SAN FÁGBAYÌ TI SỌ PÉ ÈDÈ ÀYEDÈ TÓ WÁ LÁÀRÍN ILÉ IṢẸ́ TÓ Ń RÍ SÍ Ọ̀RỌ̀ ÀṢÀ ÀTI ÀWỌN OUN ÌGBÁFẸ́ PẸ̀LÚ ÀWỌN ELÉRÉ ORÍ ÌTÀGÉ (ANTP) LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ OWÓ SÍSAN NÍ GBỌ̀NGÁN ÀṢÀ JUNE 12 NÍ ÌLÚ ABẸ́ÒKÚTA TI JẸ RODÒ LỌ MO MI*

6. *GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ DELTA, SHERIFF OBOREVWORI TI SỌ PÉ ÒUN NI ÌGBÀGBỌ́ TÍ KÒ YINGIN NÍNÚ ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁTI ṢE ÀWÁRÍ ÀWỌN TÍ WỌ́N ṢEKÚ PA ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ KAN NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA*

7. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI BẸ̀RẸ̀ ÌPÍNFÚNNI MẸ́TÍRÍKÌ TỌ́Ọ́NÙ OÚNJẸ ÒNÍHÓRÓ TÓ TÓ ẸGBẸ̀RÚN LỌ́NÀ MÉJÌLÉLÓGÓJÌ LÁTI MÚ Ẹ̀DÍNKÙ BÁ EBI Ọ̀JÀJÀ FỌWỌ́ MẸ́KẸ́ TÁWỌN ÈNÌYÀN Ń FOJÚ WINNÁ RẸ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

8. *ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ DÍDẸ́RAN ÌTÀNKÁLẸ̀ ÀÀRÙN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI FI LÉDE PÉ ÀÀRÙN ÌBA Ọ̀RẸ̀RẸ̀ LASSA (LASSA FEVER) TÚN TI GBÌNÀYÁ LÁWỌN ÌPÍNLẸ̀ KAN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

9. *ẸGBẸ́ ÀWỌN ÀKÀNDÁ ÈNÌYÀN NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN TI KỌ̀WÉ RÁŃṢẸ́ SÍ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, ỌMỌBA DÀPỌ̀ ABÍỌ́DÚN LÁTI BU ỌWỌ́ LU ÀBÀ TÓ NÍ ṢE PẸ̀LÚ ÌGBANISÍṢẸ́ ÀWỌN ÀKÀNDÁ ÈNÌYÀN*

10. *ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI RỌ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ PÉ KÍ WỌ́N MÁ RO GBOGBO ÌPÈNIJÀ TÍ À Ń KOJÚ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ṢÙGBỌ́N KÍ WỌ́N MÁA WÀ NÍ INÚ DÍDÙN NÍ ÌGBÀ GBOGBO*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

20/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ OGÚNJỌ́ OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ALÁṢẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, BỌ́LÁ AHMED TINÚBÚ TI BÈÈRÈ FÚN ÌBÚWỌ́LÙ ÀWỌN ỌMỌ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢOJÚṢÒFIN LÁTI BU ỌWỌ́ LU OWÓ OṢÙ TUNTUN ÀTI ÌSÀPÒRÓ FÚN ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ Ẹ̀KA ÈTÒ ÌDÁJỌ́*

2. *LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀YÁWÓ TÓ TÓ BÍLÍỌ́NÙ MẸ́WÀÁ NÁÍRÀ LÁSÌKÒ ÌṢÈJỌBA ALÁṢẸ ÀNÁ, AJAGUNFẸ̀YÌNTÌ MÙHÁMMÁDÙ BÙHÁRÍ, ÀWỌN ÌGBÌMỌ̀ FÌDÍẸ́ NÍLÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢOJÚṢÒFIN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI RÁŃṢẸ́ PE OLÓRÍ ILÉ ÌFOWÓPAMỌ́ ILẸ̀ WA ỌLÁYẸMÍ CARDOSSO LÁTI WÁ ṢÀLÀYÉ ÀWỌN ǸKAN TÓ MỌ̀ NÍPA Ẹ̀*

3. *IGBÁKEJÌ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, ONÍMỌ̀ Ẹ̀RỌ NỌ́ÌMỌ́T SÀLÀKỌ́ OYÈDÉLÉ TI RỌ ÀWỌN AKỌ̀RÒYÌN LÁTI MÁA KỌ ÌRÒYÌN NÍ ÌLÀNÀ AKỌ́ṢẸ́MỌṢẸ́*

4. *GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ DELTA, SHERIFF OBOREVWORI TI ṢE ÌPÀDÉ PAPỌ̀ PẸ̀LÚ ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ LÁTARI ÌṢEKÚPANI NÍ ÌPANÍKÚPA TÍ ÀWỌN KAN PA ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN ILẸ̀ WA*

5. *IKỌ̀ ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI DÓÒLÀ Ẹ̀MÍ ÀWỌN MẸ́RÌNDÍNLÓGÚN TÍ ÀWỌN AJÍNIGBÉ GBÉ SÁ LỌ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ*

6. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ÀWỌN TI ṢÀWÁRÍ ÀWỌN MẸ́Ẹ̀Ẹ́DÓGÚN KAN TÍ WỌ́N Ń ṢE AGBÁTẸRÙ ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ*

7. *ADARÍ IKỌ̀ ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ OJÚPOPO LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI KÌLỌ̀ FÚN ÀWỌN AWAKỌ̀ TÓ Ń KÓ ẸRÙ PÉ KÍ WỌ́N DẸ́KUN ÀTI MÁA KÓ ÀWỌN ÈNÌYÀN PẸ̀LÚ ẸRÙ WỌN*

8. *ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI RÁWỌ́ TÓ ÀWỌN AFURASÍ MẸ́TA KAN TÍ WỌ́N LỌ́WỌ́ NÍNÚ ÌṢEKÚ PANI NÍ ÌPAKÚPA ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA*

9. *AJÌJÀGBARA TÍ Ó TÚN JẸ́ ADARÍ IKỌ̀ TÓ Ń BÉÈRÈ FÚN ÌDÁSÍLẸ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ BIAFRA (IPOB), NNAMDI KANU TI SỌ PÉ ÒUN LÈ DẸ́KUN GBOGBO ÀÌSÍ ÈTÒ ÀÀBÒ LÁPÁ GÚÚSÙ ÌLÀ ÒÒRÙN ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁÀRÍN ÌṢẸJÚ MÉJÌ BÍ WỌ́N BÁ FI ÒUN SÍLẸ̀ LÁHÀMỌ́*

10. *ỌKÙNRIN ỌMỌ Ọ̀DỌ̀ KAN ṢEKÚ PA Ọ̀GÁ Ẹ̀ OBÌNRIN LẸ́YÌN ỌJỌ́ MÉJE TÍ Ó GBA IṢẸ́ ỌMỌ Ọ̀DỌ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

19/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KỌKÀNDÍNLÓGÚN OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ GBÉ ÀSÍÁ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC) LÉ ADÍJEDUPÒ GÓMÌNÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ EDÓ ÀTI IGBÁKEJÌ Ẹ̀ LỌ́WỌ́*

2. *AJÀFẸ́TỌ̀ ỌMỌ ÈNÌYÀN TÍ Ó TÚN JẸ́ AKỌ́ṢẸ́MỌṢẸ́ ÀGBÀ Ọ̀JẸ̀ AGBẸJỌ́RÒ NÌ, FẸ́MI FÁLÀNÀ BẸNU ÀTẸ́ LU BÍ WỌ́N ṢE JÁ OKÙN Ẹ̀MÍ ÀWỌN IKỌ̀ ỌMỌ OGUN MẸ́RÌNDÍNLÓGÚN LÁSÌKÒ TÍ WỌ́N WÀ LÓJÚ IṢẸ́ ÀTI DÓÒLÁ Ẹ̀MÍ ÀWỌN ÈNÌYÀN NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA*

3. *ÌGBÌMỌ̀ TÓ WÀ FÚN Ọ̀RỌ̀ ÌNÁWÓ NÍ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN ÀGBÀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI SỌ PÉ KÒ SÍ ÀÀYÈ FÚN ṢÍṢE ÒJÓRÓ, MÍMÚ Ọ̀KAN MỌ́KAN TÀBÍ LÍ LẸ̀DÍ ÀPÒ PỌ̀ HÙWÀ ÌBÀJẸ́ NÍNÚ ÀBÁ ÈTÒ ÌṢÚNÁ TÍ WỌ́N GBÉ KALẸ̀ LỌ́DÚN YÌÍ GẸ́GẸ́ BÍ ÀWỌN KAN TI Ń GBE PÒYÌ ẸNU*

4. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TI Ń GBÈRÒ ÀTI YÁ OWÓ TÙÙLÙ TUULU BÍLÍỌ́NÙ KAN DOLLAR NÍ ILÉ ÌFOWÓPAMỌ́ ÀGBÁYÉ LÁTI LÈ FI ṢE ÌTỌ́JÚ ÀWỌN TÍ WỌ́N WÀ NÍ ÌBÙDÓ OGÚNLÉNDÉ ÀTI LÁTI MÚ ÌDÀGBÀSÓKÈ BÁ Ẹ̀KA ÈTÒ Ọ̀GBÌN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

5. *AYA GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÌTÌ PÍN ÀPÒ ÌRẸ́SÌ ÀTI OWÓ FÚN ÀWỌN OBÌNRIN TÍ WỌ́N TÓ Ẹ̀Ẹ́DẸ́GBẸ̀TA NÍ ÌPÍNLẸ̀ NÁÀ*

6. *ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÌTÌ TI DÀNÁ SUN SAARE ILẸ̀ TÓ TÓ OGÚN TÍ ÀWỌN KAN GBIN IGBÓ SÍ NÍ ÌPÍNLẸ̀ NÁÀ*

7. *ÀWỌN ILÉ ÌTAJÀ BÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN KAN NÍNÚ ỌJÀ CENTRAL MARKET NÍ ÌPÍNLẸ̀ ṢÓKÓTÓ NI INÁ ỌMỌ Ọ̀RARA ṢORO BÍ AGBỌ́N NÍNÚ WỌN*

8. *ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ KỌLU ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ, WỌ́N SÌ TÚN JÍ ÀWỌN ÈNÌYÀN TÍ WỌ́N TÓ MẸ́TÀDÍNLÁÀDỌ́RÙN-ÚN MÍRÀN SÁ WỌGBÓ LỌ*

9. *Ọ̀GÁ ÀGBÀ LẸ́KA ÈTÒ ÀÀBÒ ILÉ IṢẸ́ OLÓGUN ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, Ọ̀GAGUN CHRISTOPHER MÚSÁ TI ṢE ÌPÀDÉ PAPỌ̀ PẸ̀LÚ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ LÓRÍ ÌKỌLÙ TÓ WÁYÉ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ, Ó SÌ ṢÈLÉRÍ PÉ ILÉ IṢẸ́ OLÓGUN ÀTI ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ TÓ KÚ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ MÁA ṢÀWÁRÍ GBOGBO ÀWỌN TÍ ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ JÍ GBÉ, ÀWỌN Á SÌ KÓ WỌN PADÀ WÁ SÍ ÌPÍNLẸ̀ NÁÀ*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

Thanks for being a top engager and making it on to my weekly engagement list! 🎉 Gbolagade Obisesan, Mariam Harbimbolar D...
18/03/2024

Thanks for being a top engager and making it on to my weekly engagement list! 🎉 Gbolagade Obisesan, Mariam Harbimbolar Duroorike, Hairat Oluwatoyin

18/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KEJÌDÍNLÓGÚN OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ALÁṢẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, BỌ́LÁ AHMED TINÚBÚ TI SỌ PÉ KÍ ÀGBÁRÍJỌPỌ̀ ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ Ó PARAPỌ̀ ṢÀWÁRÍ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ TÍ WỌ́N ṢEKÚ PA ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA KÍ WỌ́N SÌ WÁ FINMÚ KÁTA ÒFIN*

2. *ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ PÍPÈSÈ NỌ́MBÀ ÌDÁNIMỌ̀ FÚN ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (NIMC) TI FI ỌKÀN ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ BALẸ̀ PÉ OGUNLỌ́GỌ̀ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ NI WỌ́N MÁA RÍ NỌ́ḾBÀ ÌDÁNIMỌ̀ WỌN GBÀ*

3. *ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ BORNU TI BẸ̀RẸ̀ SI NÍ PÍN OÚNJẸ FÚN ÀWỌN MỌ̀LẸ́BÍ TÍ WỌ́N TÓ ẸGBẸ̀RÚN MÉJÌLÉLÁÀDỌ́TA ÀTI Ẹ̀Ẹ́DẸ́GBẸ̀TA NÍ ÌPÍNLẸ̀ NÁÀ*

4. *ẸGBẸ́ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ ÀTI OLÙKỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍGA ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI SỌ PÉ ÀWỌN NÁÀ MÁA ṢE ÀTÌLẸYÌN FÚN ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ ÀGBÀ (SSANU ÀTI NASU) BÍ WỌ́N ṢE MÁA BẸ̀RẸ̀ ÌFẸ̀HỌ́NÚHÀN ONÍKÌLỌ̀ WỌN*

5. *ÀWỌN OLÙGBÉ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI GBÓṢÙBÀ RÀBÀǸDẸ̀ FÚN GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ, BABÁJÍDÉ SANWÓ OLÚ LÓRÍ BÍ Ó ṢE GBÉ ÈTÒ OÚNJẸ KAN KALẸ̀ TÍ WỌ́N PÈ NÍ 'OÚNJẸ ÈKÓ' TÍ ÀWỌN ÈNÌYÀN ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ Á MÁA RÀ LÓWÓ TÍ Ò GANI LÁRA*

6. *GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀ṢUN, ADÉMỌ́LÁ ADÉLÉKÈ TI DIGBÁ DAGBỌ̀N Ẹ̀ KÚRÒ NÍNÚ ILÉ Ẹ̀ NÍ ÌLÚ ẸDẸ LÁTI LỌ MÁA GBÉ NÍ ILÉ ÌJỌBA TÓ WÀ NÍ ÌLÚ ÒṢOGBO LẸ́YÌN ỌDÚN KAN TÓ GUN ORÍ ÀLÉÉFÀ*

7. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI ṢÈLÉRÍ PÉ ÀWỌN MÁA WÁ ǸKAN ṢE SÍ ÈTÒ Ọ̀RỌ̀ AJÉ ORÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ TÍ KÒ ṢẸNU IRE LÁSÌKÒ YÌÍ*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

17/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KẸTÀDÍNLÓGÚN OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ALÁṢẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, BỌ́LÁ AHMED TINÚBÚ TI SỌ PÉ ÌṢÈJỌBA ÒUN TI BẸ̀RẸ̀ ÀTI MÁA TARI ÀWỌN ǸKAN ÈLÒ SÍ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁTI MÚ KÍ ǸKAN Ó ṢẸNU IRE FÚN ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

2. *LÁTARI BÍ ǸKAN ṢE LE KOKO BÍ OJÚ ẸJA LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁSÌKÒ YÌÍ, ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI BẸ̀RẸ̀ SI NÍ PÍN ÀWỌN ǸKAN ÌTURA FÚN ÀWỌN TÍ ǸKAN Ò ṢẸNU IRE FÚN NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ*

3. *ÀLÚFÁÀ TÚNDÉ BÁKÀRÈ TI ÌJỌ CITADEL GLOBAL TI SỌ PÉ ÀJỌ EFCC ÀTI ICPC NÌKAN Ò LE GBÓGUN TI ÌWÀ ÀJẸBÁNU LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

4. *ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI SỌ PÉ FÍFÚN ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ALÁKỌ̀BẸ̀RẸ̀ NÍ OÚNJẸ Ọ̀FẸ́ LÁWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ ALÁKỌ̀BẸ̀RẸ̀ NÍ TÌBÚ TÒRO ORÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ MÁA TÚN GBÉRA SỌ PADÀ LÁÌPẸ́ LÁÌJÌNNÀ*

5. *IKỌ̀ AṢÍWÁJÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) TI SỌ PÉ JÍJÍ TÍ WỌ́N JÍ ALÁGA ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) GBÉ JẸ́ ÌKÙNNÀ ÌṢÈJỌBA ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC)*

6. *ỌWỌ́ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ TI TẸ AFURASÍ AJÍNIGBÉ KAN PẸ̀LÚ ÀWỌN OUN ÌJÀ OGUN NÍ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ*

7. *ÀWỌN AJÍNIGBÉ TI JÍ AKỌ̀RÒYÌN KAN GBÉ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ*

8. *ÀWỌN ADARÍ MIYETTI ALLAH TI NÍ BÍ ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ BÁ KỌ̀ LÁTI WÁ OJÚTÙÚ SÍ ÈTÒ ÀÀBÒ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, ÀWỌN Ò NÍ MÁA TA ẸRAN MÀÁLÙ SÍ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ MỌ́*

9. *AGBẸJỌ́RÒ TÍ Ó TÚN JẸ́ AJÀFẸ́TỌ̀ ỌMỌNIYAN NÌ, DÈJÌ ADÉYANJÚ TI BẸNU ÀTẸ́ LU BÍ WỌ́N ṢE ṢEKÚ PA ÀWỌN ỌMỌ OGUN ILẸ̀ WA NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA*

10. *ÀWỌN AJÍNIGBÉ TI JÍ AKỌ̀RÒYÌN KAN GBÉ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

15/03/2024

*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KẸẸ̀DÓGÚN OṢÙ KẸ́TA ỌDÚN 2024*

1. *ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ TI KỌ̀WÉ RÁNṢẸ́ SÍ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN LÁTI BÉÈRÈ FÚN ÀGBẸ́YẸ̀WÒ OWÓ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ TÓ KÉRÉ JÙ LỌ*

2. *ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ KWARA TI KÓ ÀWỌN ATỌRỌ BÁRÀ TÍ WỌ́N TÓ MẸ́RÌNDÍNLÁÀDỌ́TA KÚRÒ NÍ ÌLÚ ÌLỌRIN*

3. *ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ KOGÍ TI TỌRỌ ÀFORÍJÌN LÁTARI ÈNÌYÀN KAN TÍ WỌ́N ṢÈṢÌ YÌNBỌN FÚN LÁSÌKÒ TÓ FẸ́ LỌ GBA ÈNÌYÀN Ẹ̀ KAN LÀ LỌ́WỌ́ ÀWỌN AJÍNIGBÉ*

4. *ALÁKÒÓSO FÚN OLÚ ÌLÚ WA ÀBÚJÁ NYESOM WIKE TI SỌ̀RỌ̀ JÁDE PÉ ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) ṢÌ NI ÒUN, FÚN ÌDÍ ÈYÍ KÍ ÀWỌN ÈNÌYÀN YÉ GBÉ ÌRÒYÌN ẸLẸ́JẸ̀ KIRI MỌ́*

5. *ÀKỌ̀WÉ ÈTÒ ÌPOLONGO TÍ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP), DÉBỌ̀ OLÓGÚNÀGBÀ TI SỌ̀RỌ̀ JÁDE PÉ KÍ OLÓRÍ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, GODSWILL AKPABIO Ó LỌ KỌ̀WÉ FI IPÒ SÍLẸ̀ NÍTORÍ Ọ̀RỌ̀ ÀFIKÚN ÈTÒ ÌṢÚNÁ TÍ ABDULNINGIN ṢE*

6. *Ọ̀GÁ ÀGBÀ ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KÁNÒ TI GBÉ ÒSÙBÀ RÀBÀǸDẸ̀ FÚN ARÁKÙNRIN KAN TÓ Ń ṢIṢẸ́ MÍ MÁA FÚN ÀWỌN ÈNÌYÀN LÓWÓ MÁA GBA OWÓ PADÀ (POS) LÁTARI PÉ Ó DÁ MÍLÍỌ́NÙ MẸ́WÀÁ NÁÍRÀ TÍ ONÍBÀÁRÀ RẸ̀ ṢÈSÌ FI SÍNÚ ÀPÒ ÀSÙNWỌ̀N RẸ̀ PADÀ FÚN ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ*

7. *OLÓRÍ ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ AṢỌ́BODÈ TÍ PÀṢẸ FÚN ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ AṢỌ́BODÈ LÁTI PADÀ LỌ MÁA ṢIṢẸ́ WỌN NÍ ẸNUBODÈ ORÍLẸ̀ ÈDÈ OLÓMÌNIRA NIGER SÍ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*

8. *ẸGBẸ́ ÀWỌN ỌLỌ́KỌ̀ ÈRÒ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (NURTW) TI KÉ GBÀJARÈ SÍTA PÉ KÍ ÀWỌN TÍ WỌ́N NÍ JỌ̀BỌ̀JỌ́BỌ̀ LÁPÁ MÁA DÁṢÀ MO KÍỌKÍỌ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ Ó JỌ̀WỌ́ BÁ WỌN BÁ DÁSÍ GBOGBO LỌGBỌLỌGBỌ TÓ Ń ṢẸLẸ̀ NÍNÚ ẸGBẸ́ NÁÀ*

9. *LÁTARI ÀÌSÍ ÈTÒ ÀÀBÒ TÓ GÍRÍÌKÌ LÁPÁ ÀRÍWÁ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, OLÙBÁDÁMỌ̀RÀN PÀTÀKÌ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ ÀÀBÒ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ NUHU RIBADU TI ṢE ÌPÀDÉ PAPỌ̀ PẸ̀LÚ ÀWỌN GÓMÌNÀ TÓ WÀ LÁPÁ ÀRÍWÁ ORÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ*

10. *OLÚBÀDÀN TI ÌLÚ ÌBÀDÀN, ỌBA LÉKAN BALÓGUN TI LỌ BÁ ÀWỌN BABA ŃLÁ WỌN NÍ ẸNI ỌDÚN MỌ́KÀNLÉLỌ́GỌ́RIN*

*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ*

*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YÈYÉ GBÀGEDE ÀṢÀ (YGA)*

Address

177 Aládé Street Sapon Abeokuta
Abeokuta

Opening Hours

Monday 09:00 - 17:00
Tuesday 09:00 - 17:00
Wednesday 09:00 - 17:00
Thursday 09:00 - 17:00
Friday 09:00 - 17:00
Saturday 09:00 - 17:00
Sunday 09:00 - 17:00

Telephone

+2348039722703

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Yèyégbàgede Àṣà Tv posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to Yèyégbàgede Àṣà Tv:

Videos

Share


Other Broadcasting & media production in Abeokuta

Show All